Thai Deer: Pátá awọtẹlẹ, rọba àti ìdọ̀tí kilo méje ṣekú pa Ìgalà

Oríṣun àwòrán, The Protected Area Regional office 13 (Phrae)
Igala kan ti wọn ri oku rẹ ni ọgba iko-ẹranko-si kan lariwa orile-ede Thailand ni awọn alaṣẹ ti ba idọti to to iwọn kilo meje ninu rẹ.
Lara awọn nkan ti o wa ninu idọti naa ni awọtẹlẹ ọkunrin, rọba, ọra iyẹfun kọfi ati okun wa lara ohun ti wọn ba ninu rẹ.
Oṣiṣẹ ọgba iko-ẹranko-si naa ni Khun Sathan ational Park sọ pe o ti pẹ ti Igala naa ti n jẹ rọba ike ki o to wa ṣokunfa iku rẹ.
Laipẹ yi ni ẹranko inu omi kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni ''dugong'' ti kọkọ ku lataari idiwọ ti rọba to jẹ n ṣe fun un ninu ikun rẹ.
Earlier this year, a baby dugong in Thailand died after eating plastic.
Ọwọ awọn to ju idọti silẹ la ba nibẹ:
Lọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu kọkanla, awọn oṣiṣẹ to n para inu ọgba naa ba oku igala naa ti ọjọ ori rẹ́ to ọdun mẹwaa nibi to ku si.
Ninu awọn nkan ti wọn ba ninu rẹ la ti ri ibọwọ onirọba ati tawẹli inura kekere kan.
Kriangsak Thanompun to jẹ oludari ọgba naa sọ fun BBC News Thai pe ''A ni igbagbọ pe o ti pẹ to ti n jẹ awọn nkan wọn yi ki o to ku''
O ṣalaye pe awọn ro pe awọn nnkan to jẹ lo di ifun rẹ ṣugbọn awọn yoo ṣe iwadii ẹkunrẹrẹ .

Oríṣun àwòrán, The Protected Area Regional office 13 (Phrae)
Loju opo ayeluja ni awọn eeyan ti n bẹnu atẹ awọn to n ju idọti silẹ ninu ọgba ọhun.
Eeyan kan sọ si oju opo Facebook pe''Bi ba lọ si ọgba yi,ti ẹ si ju idọti silẹ, ẹ ri wi pe ẹ ṣa nigba ti ba n kuro nibẹ.Ẹ ṣe oun to tọ''
Eeyan kan tilẹ sọ pe iṣẹ nla ni wọn yoo ṣe lati le j ki awọn eeyan ṣa idọti ti wọn ba ju silẹ.
Ẹlomiran naa sọ pe "Nkan ti o yẹ ki wọn maa kọ awọn eeyan lati kekere ni. Bi ko ba jẹ bẹẹ, bi wọn ba dagba tan, yoo nira ki wọn to le yi iwa pada''
Gẹgẹ bi ohun ti ọga ọgba naa sọ awọn yoo gbe ilana olopo mta kan kalẹ ti yoo mu ki awn eeyan ma ṣa idọti ati awọn nkan pantiri mi kuro nilẹ ninu ọgba naa.
Ilana wa naa yoo tun ṣe alakalẹ ọna lati maa ko idọti lọna to yẹ ati kikọ awọn eeyan lẹkọ nipa dida idọti sayika.
Orile-ede Thailand wa lara awọn orile-ede to n lo rọba pupọ.

Oríṣun àwòrán, The Protected Area Regional office 13 (Phrae)
Ajọ to n mojuto ayika ẹni, Greenpeace sọ pe o to biliọnu márùndínlọ́gọ́rin rọba ti awọn eeyan n ju silẹ lọdọọdun.
Minisita ayika ti sọ loṣu Kẹsan an pe awọn ontaja nilẹ Thailand yoo dẹkun lilo ọra lati maa fi ta nkan bẹrẹ lati oṣu Kini, ọdun 2020.
Watchiranot Thongtep ati Smitanan Yongstar ni wọn ṣafikun iroyin yii ka to gbe e wa si eti igbọ yin.














