Òjò àrọ̀rọ̀dá: Àrá sán pa màálù mẹ́tàlélógùn ní Ekiti

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kayefi, nkan ṣẹlẹ ni duniyan. ara nla kan to san lẹyin ojo arọrọda ni Abule Okeowa Eluju nipinlẹ Ekiti lo ti pa maalu mẹtalelogun ni Gaa wọn.
Eleyi si ti da ibẹru-bojo silẹ ni agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ ni ijọba ibilẹ Ijero.
Nigbati o n sọrọ iṣẹlẹ naa, darandaran Fulani to ni agbo maalu ọhun Abdulkadri Kadiri sọ pe ọrọ naa ko gba ibi kankan ye oun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọgbẹni Kadiri sọ pe eyi nigba akọkọ ti irufẹ iṣẹlẹ yii yoo ṣẹlẹ s'oun lati igba ti oun ti n ṣe ọsin maalu fun ọdun marundinlogoji.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O fi kun ọrọ rẹ sọ pe, oun lọ si agbo maalu oun lẹyin ti ojo ti rọ fun wakati mẹfa nibi ti oun ti ba oku maalu nilẹ rẹpẹtẹ.
''Ko si apa kankan lara wọn nigba ti mo yẹ wọn wo. Mo gbagbọ pe amuwa Ọlọrun ni eyi nitori mi o ṣẹ ẹnikankan, mi o dẹ ba ẹnikankan ja.''









