Fathia Williams ṣàlàyé àjọṣepọ̀ òun àti Saidi Balogun, bí wọ́n ṣe wọ àńkóò aṣọ lóde

Oríṣun àwòrán, Screenshot
O fẹrẹ ma si ayẹyẹ kan ti Fathia Williams, oṣere tiata Yoruba n ṣe ti ọkọ rẹ tẹlẹ, Saidi Balogun toun naa jẹ onitiata, ki i si nibẹ.
Ki i ṣe pe Saidi yoo wa nibẹ lasan, yoo tun maa ṣe bii pe iyawo ile rẹ ṣi ni Fathia ni, wọn yoo jọ maa ṣe kokaari eto gbogbo pọ bii lọkọ-laya.
Lọjọ Aiku to kọja ni Fathia Williams ṣe ikojade fiimu rẹ tuntun niluu Eko.
Gẹge bi iṣe rẹ, Saidi Balogun tun wa nibẹ, aṣọ kan naa, damaski alawọ waini, si ni oun ati Fathia jọ wọ pẹlu.
Wọn jọ de sibi eto naa nigba kan naa ni, wọn jọ ṣe gbogbo eto papọ, jo papọ, ya fọto papọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Fathia dúpẹ́ níta gbangba lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀

Oríṣun àwòrán, Fathia Williams/Facebook
Bi ikojade fiimu ọhun ṣe n lọ lowọ ni Fathia dupẹ lọwọ baba awọn ọmọ rẹ naa, fun pe o wa, o si tun duro tan ti oun.
Loju ọpọ eeyan to wa nibi ayẹyẹ naa ni Fathia ti fi ẹmi imoore nla han si Saidi tawọn eeyan tun mọ si Walata.
Ninu fiimu tuntun ọhun, Saidi Balogun naa kopa nibẹ.
Njẹ bi aarin awọn oṣere meji naa ṣe n gun loju aye yii le mu wọn pada bii lọkọ-laya?
Ọpọ eeyan lo ti n sọ ọ tipẹ, pe ko ba dara pupọ bi Saidi Balogun ati Fathia ba le fẹra wọn pada bii lọkọ-laya.
Awijare awọn eeyan yii ni pe ifẹ ṣi n foju han laaarin awọn mejeeji ni wọn fi le jọ maa ṣe bayii nita gbangba.
Bakan naa ni awọn mi-in sọ pe ẹni ti a bimọ fun ti kuro ni ale ẹni.
Wọn ni nigba ti Fathia ko lọkọ miran lati ọdun pipẹ to ti fi Saidi Balogun silẹ, to si jẹ pe baba ọmọ rẹ ni ọkunrin yii, ko sohun to ni ko ma pada fẹ ẹ.
Awọn mi-in n sọ pe ajoṣepọ to kun fun ibọwọ fun ara ẹni lo n waye laaarin wọn bayii, ti yoo si daa ti wọn ba le jẹ ko ni ọrọ ifẹ ninu.
Ṣugbọn lọpọ igba ti Fathia ba n ṣe iforọwerọ lori ọrọ oun ati Saidi, kedere lo maa n sọ ọ pe oun ṣi le ni ọkọ mi-in ti asiko ba to.
Ọjọ karun-un oṣu Keji ọdun ni wọn jọ bi Saidi Balogun ati Fathia Williams.
Ọjọ karun-un oṣu Keji ọdun 1967 ni wọn bi Saidi, nigba ti Fathia daye lọjọ karun-un, oṣu Keji ọdun 1969.
Ki lo fa ipinya wọn?
Ọdun 2000 ni awọn oṣere mejeeji yii fẹra won bii lọkọlaya, ija de ni nnkan bii 2006.
Koko ija naa bi wọn ṣe sọ nigba naa ni aigbọra ẹni ye, fifi ẹsun agbere kan ara ẹni atawọn nnkan mi-in to ni i ṣe pẹlu
ẹnikọọkan wọn.
Saidi Balogun lo jawe ikọsilẹ fun Fathia, o ni o ju ọdun kan lọ ti obinrin naa fi pa oun ti.
Wọn tu ajọṣepọ naa ka lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kin-in-ni ọdun 2014.
Ọpọ igbiyanju lo waye lọtun-un losi lati pari ija fun awọn oṣere mejeeji yii, lati ẹka ọtọọtọ, amọ wọn ko ri ija naa pari rara.
Àlàyé rèé lórí ìdí tí ẹnu ṣe ń kun Funke Akindele pé ó fojú pa Pasuma rẹ́ lóde àti bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé

Oríṣun àwòrán, Funke Akindele/ Facebook/ Wasiu Alabi Pasuma/Facebook.
Oju la n tẹ fun alejo ka too tẹ́ní ni Yoruba wi, ati pe o da a ka ri eeyan, ka ki wọn daadaa pẹlu ọyaya.
Bi ẹnikan ba fi oju pa ẹnikeji rẹ lasiko ti wọn n ki i tabi pọn-ọn le, tabi ti ọmọde foju pa agba rẹ lai ki i, abuku nla ni Yoruba ka a si .
Eyi lo tun mu ọrọ kan maa ja ranyin lori ayelujara bayii, nipa gbajumọ oṣere tiata, Funke Akindele.
Wọn ni Funke ri Sheu Fuji, iyẹn Alaaji Wasiu Alabi Pasuma, lode kan laipẹ yii, to si foju pa a rẹ lai ki i.
Ẹ o ranti pe laipẹ yii ni ẹnu kun Funke Akindele lori ọrọ ikini, nigba ti Toyin Abraham ti won jọ jẹ oṣere n ki i lode Iyabo Ojo, ṣugbọn ti Funke ko dahun.
Eyi ko ti i pẹ to ṣẹlẹ, ti ẹnikan torukọ rẹ n jẹ #UOladiti, tun gbe fidio kan soju opo X rẹ, to si kọ akọle sibẹ pe:
"Nigba ti Funke Akindele foju pa Pasuma rẹ nigboro. Eyi ko daa rara."
O fi ibi kan to han pe obinrin naa ko tasi Pasuma han.
Funke Akindele fesi
Ọpọ eeyan lo bẹrẹ si i sọ ero ọkan wọn lorii fidio naa ati ohun ti wọn ri.
Awọn kan sọrọ si Funke tawọn eeyan tun mọ si Jennifer, wọn ni ko rọra ṣe ko si yee jọ ara rẹ loju.
Lati ṣalaye ara rẹ, Funke Akindele sọ pe ko sohun to jọ pe oun kan Pasuma labuku, tabi pe oun foju pa a rẹ.
Akindele sọ pe iroyin aṣinilọna ti awọn ẹni ibi kọ ni.
Lọjọ Aiku ni Funke dahun soju opo X rẹ pe ko si ohun to jọ aibọwọ fun agba ninu ọrọ oun.
"Foju pa eeyan rẹ? O doodi. Ẹ sinmi aida, ẹ jọọ.
"Mo ri wọn, mo ki wọn, mo ba wọn jo.
"Ẹgbọn mi ni Pasuma. Ẹ jọọ, gbogbo yin ẹ ṣiwọ iwa ibi yii."
Bẹẹ ni Funke Akindele kọ ọ soju opo X rẹ.
Ohun ti fidio kekere ṣafihan ati ohun to ṣẹlẹ gan-an
Ninu fidio kekere to fa awuyewuye yii, wọn ṣafihan ibi ayẹyẹ kan ti Funke Akindele ti n ki oṣere tiata bii tiẹ, Fathia Balogun.
Pasuma jokoo ni ẹgbẹ kan nibẹ, o n wo foonu rẹ.
Ṣugbọn fidio yii ko fi ibi ti Funke ti ki Pasuma han, kaka bẹẹ, akọle ti wọn kọ si I ni pe o dọgbọn foju pa akọrin Fuji naa rẹ.
Ṣugbọn ninu fidio keji to gun daadaa, a ri Funke Akindele to n ki Alaaji Pasuma pẹlu ọyaya, to sunmọ akọrin naa pẹkipẹki, to si n rẹrin-in.
Koda, wọn jọ sọrọ ninu fidio naa daadaa, ki Akindele too lọ ki awọn alejo mi-in to tun wa nibẹ.
Eyi lo fi han pe awọn to fẹ da rúgúdù silẹ lo ge abala to wu wọn, ti wọn si kọ ohun ti wọn fẹ si i.
Ta ni Funke Akindele ti ẹnu n kun?
Ọjọ ikẹrinlelogun oṣu kẹjọ ọdun 1977 ni wọn bi Funke Akindele ni idile Akindele, baba rẹ jẹ adari ile iwe girama ti iya rẹ si jẹ dokita.
Oṣere ni, olukọtan ni, o tun jẹ olootu to ṣe wi pe bi awọn eniyan ṣe bẹrẹ si ni mọ ọ jẹ ara ọtọ paapaa pẹlu ere rẹ to fi gba orukọ, Jennifer.
Ohun ti a fi lee pe e ni oniroyin ni wi pe iṣẹ to fi bẹrẹ ẹkọ kika ni ibẹrẹ ile iwe giga rẹ̀ ni imọ nipa iṣẹ iroyin.
Kii ṣe ere yii ni akọkọ rẹ gẹgẹ bi oṣere, ati igba ti ọjọ ori rẹ ṣi din ni ogun ọdun lo ti kopa ninu ere to n kọ ni lẹkọ kan ti ajọ UNICEF ṣe onigbọwọ, "I Need to Know".
Lẹyin ile iwe girama, Funke kawe gboye OND ni ile ẹkọ akọṣẹmọṣẹ Moshood Abiola Polytechnic ninu imọ iṣẹ iroyin lẹyin eyi to tun kawe gboye ninu imọ ofin ni ile ẹkọ fasiti ilu Eko.
Ibi ti Funke Akindele ti di gbajugbaja ni ninu ere rẹ to ṣe ni ọdun 2008, "Jennifer" eyi to tan kari aye kari oko.
Lẹyin eyi, Funke tun ṣe agbejade sinima agbelewo to ṣi n han lọwọ lori ẹrọ amohunmaworan, "Jennifer's Diary", eyi jẹ bii amọle ere "Jennifer".
Lẹyin eleyi lo tun ṣe afikun pẹlu agbejade "Return of Jennifer".
Yatọ fun awọn ere tirẹ, Funke ti kopa ninu ọpọlọpọ ere mii yala lede Yoruba tabi Gẹẹsi eyi ti ko ṣee darukọ tan.
Funke Akindele ni oludasilẹ ati alakoso Scene One Film Production ti wọn ti n kọ nipa ere tiata. Bakan naa o ni ile iṣẹ ti ko rọgbọku le ijọba eyi to fi n kọ awọn ọdọ niṣẹ ọwọ.
Latari iṣẹ takun takun rẹ ninu ere tiata, Funke ti gba ọpọlọpọ ami ẹyẹ o si ti ṣe awọn iṣẹ akanṣe bii ipolowo fun oriṣiriṣi ọja ati ile iṣẹ.
Ọ̀fọ̀ míì tún ṣẹ̀ lágbo tíátà, àgbà òṣèré jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Solomon Akiyesi /Facebook
Ẹgbẹ oṣere tiata ilẹ Naijiria ti a mọ si Actors Guild Of Nigeria (AGN) ti kede iku ọkan lara awon agba oṣere nilẹ yii, Solomon Akiyesi.
Ọjọ Aje ni Aarẹ ẹgbẹ naa, Abubakar Yakubu kede pe Solomon Akiyesi to maa n dari ere yatọ si pe o jẹ oṣere, ti jade laye.
Aarẹ AGN fi kun un pe Oloogbe naa sun lalẹ ọjọ Aiku ni, ko si ji saye mọ lọjọ keji.
Ẹni ọdun mejidinlọgọta (58) ni Oloogbe Solomon Akiyesi ko too jade laye.
Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?
Gẹgẹ bi ohun ti ọmọ Oloogbe Akiyesi sọ, o ni ṣaaju ọjọ Aje naa ni Akiyesi sọ pe àyà n dun oun, awon si gbe e lọ sile iwosan.
Lẹyin ayẹwo lo ni awon dokita sọ pe ọgbẹ inu lo n da a laamu.
Ọmọ naa tẹsiwaju pe wọn fun un ni oogun ti yoo lo, awon si pada sile.
Oorun alẹ ọjọ Aiku mọjumọ ọjọ Aje naa ni Solomon sun ti ko si ji saye mọ bo ṣe sọ.
Nnkan bii aago mẹrin idaji ti iyawo rẹ gbiyanju lati ji i lo ri i pe agba oṣere to maa n sabaa ṣe ere oloyinbo naa ti dagbere faye.
Wọn ti gbe oku rẹ sile igbokuusi kan niluu Abuja to fi ṣe ibugbe.
Ta a ni Solomon Akiyesi?

Oríṣun àwòrán, Solomon Akiyesi/ Facebook
Ọmọ bibi ilu, Ososo, nijọba ibilẹ Akoko-Edo, nipinlẹ Edo ni Oloogbe Solomon Akiyesi.
Nnkan bii ọdun 1990 sisalẹ lo ti bẹrẹ si i ṣe ere ori itage ati sinima.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ere oloyinbo lo n sabaa ṣe ju to si maa n dari, Oloogbe Akiyesi kopa ninu fiimu to to ọgọrun-un nigba aye rẹ.
Lara awọn ere to ti ṣe ni Marry Who You Love, Kiss My Pain, Joy of Nakasha, Heart of a Saint, Deadly Affair, Gen Z Wife ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ọmọ orilẹede Naijiria ni Oloogbe Solomon Akiyesi, ṣugbọn wọn mọ riri rẹ nilẹẹ Kenya naa pẹlu awon iṣẹ rẹ to debẹ.
Awọn ololufẹ rẹ lati Kenya ti n kọ orọ ibanikẹdun ranṣẹ, gẹgẹ bi ọpọ ibanikẹdun ṣe ti n jade lati Naijiria naa.





























