Ta ni Halimat Tejuosho, gbajúmọ̀ oníṣòwò tí EFCC kéde pé òun ń wá?

Oríṣun àwòrán, EFCC
Àjọ tó ń rí ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC tí kéde pé àwọn ń wá obìnrin oníṣòwò kan, Halimat Adenike Tejuosho, ẹni ọdún mọ́kànlélógójì tó fi ìlú Abuja ṣe ibùjókòó.
EFCC nínú àtẹ̀jáde tí fi léde sọ pé ẹ̀sùn fífi ọ̀nà èrú gba owó lọ́wọ́ èèyàn ni wọ́n ń wá Halimat fún.
Halimat Tejuosho jẹ́ gbajúmọ̀ obìnrin ní ìlú Abuja, tó sì jẹ́ olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ Haleems Integrated Services Limited.
Àtẹ̀jáde tí EFCC fi sójú òpó wọn èyí agbẹnusọ rẹ̀, Dele Babawale buwọ́lù sọ pé àwọn ń wá obìnrin náà lórí ìwádìí kan tí àwọn ń ṣe lọ́wọ́.
EFCC tó kéde Halimat Tejuosho gẹ́gẹ́ bí ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Eko sọ pé ibi tí àwọn mọ̀ tó ń gbé kẹ́yìn ni House A26, Aso Grove Estate, Maitama Extension ní Abuja.
EFCC rọ àwọn èèyàn tó bá ní ìmọ̀ nipa bí ọwọ́ ṣe le tẹobìnrin náà láti fi tó iléeṣẹ́ náà létí ní gbogbo àwọn ẹ̀kan wọn tó wà ní Ibadan, Uyo, Sokoto, Maiduguri, Benin, Makurdi, Kaduna, Ilorin, Enugu, Kano, Lagos, Gombe, Port Harcourt àti Abuja.
Bákan náà ni wọ́n tún ní àwọn èèyàn tún le kàn sójú òpó wọn lórí ayélujára tàbí kí wọ́n lọ sọ ní àgọ́ ọlọ́pàá tó bá súnmọ́ wọn.
Lára àwọn tó mú ẹjọ́ Halimat Tejuosho lọ síwájú EFCC ni ọ̀kan lára àwọn tó jọ ń ṣiṣẹ́, ẹni tó fẹ̀sùn kàn pé obìnrin náà lo owó tó wà fún iṣẹ́ àwọn méjéèjì fún ara rẹ̀ nìkan.
Ta ni Halimat Adenike Tejuosho?

Oríṣun àwòrán, Others
Ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Eko tó fi ìlú Abuja ṣe ibùjókòó noi.
Òun ni olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ Haleems Integrated Services Limited àti àjọ Queen Adenike Tejuosho Foundation (QATFoundation).
Halimat Tejuosho ni olórí àwọn obínrin City Boys Movement, ẹgbẹ́ tó ń ṣe àtílẹyín fún ààrẹ Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu fún àtúnyànsípò rẹ̀ lọ́dún 2027.
Halimat Tejuosho rapala wọ agbo òṣèlú, táwọn èèyàn kan sì rọ ààrẹ Tinubu láti fun ní ipò Mínísítà fọ́rọ̀ ìbojú àánú woni lọ́dún 2024 lẹ́yìn tí wọ́n yọ Betta Edu nípò náà.
Láti ọdún pípẹ́ ni onírúurú ẹ̀sùn àti awuyewuye ti ń wáyé lórí Halimat Tejuosho, tó sì kojú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ní EFCC lọ́dún 2025.
Ní ọdún 2023 ni wọ́n tún fẹ̀sùn kàn án ó sálọ sílẹ̀ òkèèrè kí ọwọ́ àwọn agbófinró má ba à tẹ̀ ẹ́ lẹ́yìn tí ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ kan lọ fi ẹjọ́ rẹ̀ sùn. Ó jiyàn àwọn ẹ̀sùn náà.
Ní oṣù Kẹfà ọdún 2025 ni EFCC fi ọ̀rọ̀ wá Halimat lẹ́nu wò fẹ́sùn pé ó parọ́ gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn láti báwọn wá iṣẹ́ ìjọba.
Èèyàn kan fẹ̀sùn kàn pé níṣe ni ó fún àwọn èèyàn ní ayédèrú ìwé ìgbanisíṣẹ́ ìjọba èyí tó fi ń gba owó ńlá lọ́wọ́ àwọn èèyàn.




























