Ṣé lóòótọ́ ni pé èèyàn mẹ́wàá tún ti lùgbàdì Covid-19 ní Naijiria? Ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ipinlẹ Cross River ti tako iroyin kan to gbode, pe arun Covid 19 tun ti mu eeyan mẹwaa mi-in yatọ si ọmó ilẹ China ti wọn kọkọ kede pe o kọlu nipinlẹ naa.
Bakan naa ni awọn ẹka ilera kaakiri ipinlẹ Cross River naa ti sọ pe ko si akọsilẹ arun Corona mẹwaa lọdọ awọn.
Wọn ni ẹnikan ṣoṣo naa ni akósilẹ wa fun pe arun ọhun kọlu.
Ninu ọrọ Kọmiṣanna eto ilera ipinlẹ Cross River, Henry Ayuk, l'Ọjóbọ, o ni :
"Mo fẹ fi anfaani yii sọ fun awọn ọmọ Naijiria, pe iroyin to gbode pe a tun ti ri eeyan mẹwaa to ni aisan Corona ni Cross river ki i ṣe otitọ, akọsilẹ eeyan kan ṣoṣo naa ni a ni."
Ayuk ni boya eeyan mẹwaa ti iroyin sọ pe wọn fara ro ẹni to ni arun naa ni awọn ẹka iroyin kan n tumọ si pe eeyan mẹwaa lo tun ti ni aisan naa ni Cross River.
Eyi ti ko ri bẹẹ ra ra bibi Ayuk ṣe ṣo.
Ki lo n ṣẹlẹ si ọmọ China to ni arun naa lọwọlọwọ?
Gege bi Kọmisanna eto ilera ipinlẹ Cross River ṣe ṣalaye, ọmọ China to lugbadi Covid 19 naa de si Naijiria lọjọ ketadinlogun, oṣu Kẹta ọdun 2026 yii, o si lugbadi aisan naa lọjọ kẹtadinlogun oṣu Kerin ọdun yii kan naa.
O n gba itọju lọwọ, wọn si n ṣayẹwo ilera rẹ daadaa.
"Wọn kọkọ n tọju rẹ nileewosan kan ni ki wọn too gbe e lọ si Calabar.
"Wọn ti fi si yara to da wa ni Calabar, o si n ni alaafia si i bojumọ ṣe n mọ."
"Awon to ti fara ro o ni a ti ṣe akọsilẹ orukọ wọn, ti a si n ṣayẹwo awọn naa fun o kere tan, ọjọ mẹrinla gbako."
Ayuk sọ pe ajakalẹ arun lo ṣẹyọ, ijọba si tete kapa rẹ.
"Bi ewu ba ṣẹyọ bi eyi, ikilọ ni fun gbogbo eeyan to ku, nitori ẹ ni ijọba ko ṣe fi ọwọ yẹpẹrẹ mu un."
O fi kun un pe awon ti ṣe awon eto aabo to yẹ kaakiri si awon ileewosan apapọ ni Cross River, pẹlu awon ẹka ijọba ibilẹ pẹlu.
Àrùn Covid-19 padà bú jáde ní Naijiria, àjọ NCDC àti WHO fi ìkìlọ̀ léde

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ipinlẹ Cross River ti ṣawari eeyan kan to lugbadi arun Covid-19.
Ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ ọhun sọ pe oun ti bẹrẹ iṣẹ lati ṣawari gbogbo awọn to farakan ọmọ orilẹede China to ni arun naa lara lati ya wọn sọtọ fun ayẹwo ati itọju.
Nigba to n ba awọn akọroyin, kọmiṣọna eto ilera ipinlẹ ọhun, Henry Ayuk, fidi rẹ mulẹ pe lootọ arun Covid-19 ti pada sipinlẹ naa amọ awọn ko kawọ gbera lori rẹ.
Ayuk ni igba akọkọ ree ti wọn yoo ri arun naa nipinlẹ ọhun lati ọdun 2022 amọ awọn yoo ri daju pe ko ni tan kanlẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọmọ orilẹede China to ni arun naa wọ Naijiria lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2026 yii.
O sọ pe inu Naijiria lo ti ni arun naa lẹyin ti ọjọ mẹrinla ti arun ọhun maa n lo ko to Farahan ti kọja.
O tẹsiwaju pe ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin ti a wa yii ni apẹrẹ arun naa to bẹrẹ si n farahan lara rẹ.
Kọmisọna ọhun fi kun pe awọn akọṣẹmọṣẹ eto ilera ti lọ si ijọba ibilẹ Akamkpa nibi ti ọkunrin naa n gbe to si ti n ṣiṣẹ lati ri pe arun naa ko tan kalẹ nibẹ.
Ẹnikan lo ni arun naa, ko tii tan kalẹ - NCDC
Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun ni Naijiria ti sọ pe lootọ ni ẹnikan ni arun naa nipinlẹ Cross River.
Ninu atẹjade to fi soju opo X rẹ, NCDC sọ pe ẹnikan ṣoṣọ naa to jẹ ọmọ orilẹede China nikan lo ṣi ni arun ọhun, awọn si ti bẹrẹ iṣẹ lati ri pe ko tan kalẹ.
NCDC sọ pe ko tii si ẹri pe arun naa ti tan kalẹ lọwọ yii ṣugbọn oju ni alakan fi n ṣọri.
WHO kilọ fun awọn ọmọ Naijiria ki wọn maa ṣọra
Ẹwẹ, adari ajọ WHO nipinlẹ Cross River, Yewande Olatunde, ti ke si awọn ọmọ Naijiria ki wọn maa ṣọra latari pe arun Covid-19 ko tii tan nilẹ patapata.
Ti ẹ ko ba gbagbe, nnkan bii ẹgbẹrun mẹta eeyan ni Covid-19 mu ẹmi wọn lọ ni Naijiria gẹgẹ bii akọsilẹ ajọ NCDC.
Ipari ọdun 2019 ni arun Covid-19 kọkọ bu jade ni China ko to tan de awọn orilẹede mii kaakiri agbaye, eyii to mu awọn orilẹede kede ofin konile-o-gbele.
Ikede igbele yii ṣakoba fun ọpọ ọrọ aje awọn orilẹede kaakiri agbaye.



























