"Àkọ̀bí mi tó ń tọ́jú èmi àtàwọn àbúrò rẹ̀ ní wọ́n pa nínú ìjà Hausa àti Yorùbá n'Ibadan"

Oríṣun àwòrán, BBC/ Habeeb Olajide
Obinrin kan ti ọpọ eeyan mọ si Iya Habeeb, ọkan lara awọn to padanu ọmọ ninu ija ẹya Hausa ati Yoruba niluu Ibadan lọjọ Iṣẹgun, ti fi omije fọhun aro lori iku ọmọ rẹ, Habeeb Olajide to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Bakan naa ni ọwọ ṣikún ọlọpaa ti tẹ awọn eeyan mẹrin kan ti wọn fura si pe wọn lọwọ ninu rogbodiyan ija ẹya Hausa ati Yoruba naa to waye lagbegbe Ojoo, niluu Ibadan.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Olayinka Ayanlade, fidi eyi mulẹ ninu atẹjade to fi sita l'Ọjọbọ.
Ninu alaye DSP Ayanlade lo ti ni awọn afurasi naa ti wa ni ahamọ lẹka to n wadii iwa ọdaran n'Iyaganku, niluu Ibadan.
Ileeṣẹ ọlọpaa Oyo koro oju si bawọn kan ṣe da wahala silẹ nipa ṣiṣe idajọ lọwọ ara wọn, to bẹẹ ti ẹmi awọn eeyan kan tun fi ba rogbodiyan lọ yatọ si tawọn to bẹrẹ wahala naa.
Ibanujẹ dori agba kodo, Baba Iya Habeeb lo kọkọ ṣalaye iku ọmọ -ọmọ rẹ
BBC News Yoruba kan si Iya Habeeb ti ọmọ rẹ ku ninu rogbodoyan naa, amọ iya naa ko le tete sọrọ.
Baba to bi Iya Habeeb, Alagba Bashiru Ishola Olalere, lo kọkọ ṣalaye fun wa pe:
"Inu ile ni mo wa ti wọn ti pe mi pe wọn ti gun ọmọ-ọmọ mi pa l'Ojoo, ohun to fẹ jẹ lo lọ ra.
"Awọ ọrẹ Habeeb meji lo sare wọle waa ba mi, ti wọn si beere Iya Habeeb lọwọ mi.
"Mo salaye fun wọn pe iya rẹ ti lo ìsọ̀, lẹyin naa ni Iya Habeeb funra ẹ pe mi pe awọn Hausa ti gun Habeeb pa ni Ojoo.
"Mo gbera, o di ọsibitu ti wọn ni ọmọ-ọmọ mi wa. Mo ri i ninu yara ti wọn tẹ ẹ si, mo ri i pe wọn ti gun un loju ati aya, bawọn ọlọpaa ṣe ni ki n ma pariwo niyẹn.
'Ṣugbọn bi Iya Habeeb to jẹ ọmọ mi gangan ṣe ri mi bayii, o bu sẹkun ni, o si bẹrẹ si i gbe ara rẹ dalẹ, bi a ṣe gba agọ ọlọpaa lọ niyẹn."
Iya Habeeb fi omije sọrọ
Ninu ọrọ diẹ ti Iya Oloogbe Habeeb pada ba akọroyin wa sọ lo ti fi omije sọ pe:
"Habeeb ni akọbi mi, oun lo n tọju emi ati awọn aburo rẹ meji, awon to pa mi lọmọ da mi loro nla ni.
"Oniwa irẹlẹ lọmọ mi, ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ okunkun kankan, jẹjẹ rẹ lo maa n lọ laduugbo.
"Mo bẹ Gomina Oluwaseyi Makinde, ẹ ma jẹ ki iya yii jẹ mi gbe.
"Mo n rawọ ẹbẹ sijọba ipinlẹ Oyo lati ṣe iwadii gidi lori ọrọ yii, mo si n fẹ idajọ ododo lori iku Habeeb."
Bẹẹ ni Iya Habeeb fi ẹdun ọkan pari ọrọ rẹ.
Ta a ni Oloogbe Habeeb Olajide?

Oríṣun àwòrán, Habeeb Olajide Tik/Tok
Ọdọkunrin to n tun kẹkẹ Marwa ṣe to si tun maa n fi kẹkẹ naa ko ero ni Habeeb Olajide nigba aye rẹ.
Ẹni ọdun mẹtalelogun, (23) ni.
Alaye ti baba iya rẹ ṣe fun wa ni pe ọmọ daadaa ti ki I ba ẹnikẹni ja ni Habeeb. O ni ki i ṣe ọlẹ, o niṣẹ rẹ lọwọ.
"Iṣẹ awọn to maa n tun kẹkẹ Marwa ṣe lo kọ, ọdun to lọ lo gba iyọnda, ọmọ wa ki i ṣe ọlẹ, ki i ṣe ole tabi ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun kankan."
Oloogbe Habeeb ni iyawo kan, o si ṣẹṣẹ bimọ ni.
Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?
Tẹ o ba gbagbe, ija bẹ silẹ lagbegbe Ojoo, nijọba ibilẹ Akinyele, niluu Ibadan lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii, o si yi wọ ọjọ keji.
Ọrọ ọkunrin kan onimaruwa kan ti a gbọ pe o gba owo lọwọ Hausa to n ṣe POS lo bi wahala naa.
Ẹni to n ṣe POS sọ pe owo naa ko ti I wọle sọdọ oun, amọ o ti kowo fun ẹni to fẹẹ gba owo.
Ẹnu rẹ ni wọn wa ti wọn ni ẹnikan ti de lara awọn ẹya Hausa naa to si lọ fi ọbẹ gun onimaruwa mi-in to jẹ Yoruba lati ẹyin, ẹni to gun lọbẹ naa ni wọn pe ni Habeeb Olajide.
Ọjọ keji ni Habeek ku, ẹyin rẹ lo si di pe rogbodiyan naa di ija ẹya meji, to pada mu ẹmi awọn eeyan meji miran lọ ti ọpọ si farapa.
Wàhálà bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn Yorùbá àti Huasa ní Ibadan, èèyàn mẹ́ta jáde láyé

Niṣe ni ọrọ di eni ori yọ o dile ni agbegbe Ojoo ni ilu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Oyo nigba ti ija nla kan bẹ silẹ laaarin awọn Yoruba atawọn Hausa to wa ni agbegbe naa.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ, nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ojọ Iṣẹgun ni iṣẹlẹ naa waye laaarin ọkunrin to jẹ Yoruba to n wa kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta ti ọpọ eeyan mọ si maruwa ati awọn Hausa ti wọn maa n ṣa irin aloku ta.
Iroyin sọ pe ija naa tun tẹsiwaju ni owurọ yii ko to di pe awọn ẹṣọ aabo tete ji giri si ko ma ba a di wahala ẹlẹyamẹya laaarin awọn ti ija naa ti waye.
Ni owurọ ọjọru ni awọn ọdọ ti inu n bi di gbogbo opopona to wa ni agbegbe naa, ti wọn si ẹnikẹni ko ni gba ọna naa kọja.
Eyi fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ bi awọn eeyan ko ṣe ri bi kọja ni agbegbe naa ṣugbọn ti wọn pada ṣi ọna leyin ti igbakeji gomina ipinlẹ Oyo ṣabewo si agbegbe naa.
Nigba ti BBC News Yoruba kan si agbegbe Ojoo, ijọba ibilẹ Akinyele ti iṣẹlẹ naa ti waye ṣalaye ohun to ṣẹlẹ ni pato fun wa.
Awọn ọdọ ti inu n bi naa ṣalaye pe ọkunrin to n wa kẹkẹ naa lọ ra ounjẹ noodles lọwọ ọkunrin Hausa to n ta noodles ni agbegbe naa ti o fẹ jẹ ni alẹ ana.
O ni lẹyin to jeun tan lo fi owo ranṣẹ si Hausa naa lati ori foonu ṣugbọn ti Hausa to n ta noodles naa sọ pe oun ko ri owo naa.
Wọn sọ pe eti lo bẹrẹ ifanfa laaarin awọn mejeeji ko to di pe awọn Hausa mii ni agbegbe dide si wọn, ti wọn si bẹrẹ si ni lu ọkunrin Yoruba naa, fi nnkan gun-un titi ti ẹmi fi bọ lọrun rẹ.
Wọn ni eyi lo mu ki awọn Yoruba to w ani agbegbe naa dide lati gbeja eeyan wọn ti wọn pa, ti ọrọ naa si di wahala nla, ti wọn fi sọ ina si agbegbe tawọn Hausa naa n lo lati ṣe ọja awọn nnkan ti wọn n ṣa.
Nigba to n ba igbakeji gomina ipinlẹ Oyo, Adebayo Lawal, to ṣabẹwo si agbegbe naa ni owurọ yii sọrọ, ọkan lara awọn aṣoju ọdọ ni agbegbe naa, Olamiposi Azeez sọ pe igba akọkọ kọ niyii ti iru wahala bayii ti maa n ṣẹlẹ ni agbegbe Akinyẹle.
Olamiposi salaye pe awọn Hawusa ti wọn wa ni ori oke Ọjọọ ni awọn ohun kan ija oloro lowo eyi ti wọn lo lati fi gbẹmi eeyan mẹta.
O ni lati ori oke ti wọn wa ni wọn ti n yin ibọn si awọn eniyan ti wọn wa ni titi.
O beere pe ki ijọba wa ọna ti wọn fi maa ko awọn Hausa ti wọn n gbe ni ori oke naa kuro nitori wahala to maa n waye lemọlemọ ni agbegbe naa ati pe o ṣeeṣe ki wahala mii tun be silẹ ti awọn ọdọ ti inu n bi lori iṣẹlẹ naa ba tun lọ ṣe ikọlu si wọn.
Gbogbo awọn to lọwọ ninu ikọlu naa lo maa foju wina ofin - ijọba Oyo
Ninu ọrọ rẹ, igbakeji Gomina ipinlẹ Oyo, Amofin Abdulraheem Adebayo Lawal sọ pẹ nnkan ibanujẹ ni ohun to ṣẹlẹ ni alẹ ọjọ Iṣẹgun mọjumọ naa to si le tapo aala si ipinlẹ Oyo.
O rọ awọn ọdọ lati ṣe suuru lori iṣẹlẹ naa, pe ijọba ti gbọ si iṣẹlẹ naa, ti wọn si maa gbe igbesẹ akin lori ikọlu ọhun.
O fi kun ijọba maa ṣe iwadii to looorin lati mu gbogbo awọn ti lọwọ ninu iṣẹlẹ naa ati pe gbogbo awọn ti iwa ọrọ naa ba ṣi mọ lori lo maa foju wina ofin.
Igbakeji gomina naa tun parọwa sawọn ọdọ lati ma ṣedajọ lọwọ ara wọn nitori awọn kan ti fẹ sọ ohun to ṣẹlẹ naa di ija ẹlẹyameya eyi to ni ijọba ko ni faaye gba.
O fi da awọn eeyan loju pe awọn maa fi ofin mu awọn to wa nidii ikọlu naa, ti wọn si maa fi foju wina ofin amọ tawọn ọdọ nilo lati gba ijọba laaye lati ṣe ojuṣe wọn bo ṣe yẹ.
Lawal wa palaṣẹ fun gbogbo awọn ẹsọ alaabo to wa lagbegbe naa lati pese eto aabo to muna doko ni agbegbe naa, ki wọn si ri daju pe ikọlu bẹẹ ko tun waye mọ.




























