Ìdí ti ayẹyẹ ọjọ́ ìbí mi fi wáyé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ náà ni ìyá mi jáde láyé rèé- Fathia Williams

Aworan Faithia Williams ati iya rẹ to di oloogbe

Oríṣun àwòrán, Faithia Williams/ Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja oṣere tiata, Faithia Williams, ti ọpọ mọ si Faithia Balogun, ti kede sita pe iya rẹ jade laye.

Williams kede eyi lẹyin wakati diẹ ti o ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi, ọdun marindinlọgọta niluu Eko.

Gẹgẹ bii o ṣe ṣalaye, o ni iya oun ku ni irọlẹ ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ ṣugbọn awọn mọlẹbi ko kede iroyin nipa iku naaa fun oun titi ayẹyẹ naa fi pari.

Ninu ọrọ to gbe sita fi ṣe idaro iya naa, o ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bii aladuroti rẹ, to ni ọpọ igbagbọ ninu rẹ.

O tẹsiwaju pe, iya to di oloogbe naa lo ma n fi adura ran lọwọ ninu gbogbo kan to ba dawọle, to si tun jẹ ọrẹ timọtimọ rẹ.

Willaims wa ke si awọn ololufẹ pe ki wọn ranti oun ati awọn mọlẹbi rẹ ninu adura wọn , to si ni oun yoo kede eto isinku laipẹ.

Ọpọ awọn eeyan jakanjakan lo peju sibi ayẹyẹ ọjọbi naa bii, Funke Akindele, Pasuma, Kazim Adeoti, Wumi Ajiboye, ati MC Oluomo.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Ta ni Faithia Williams?

Ọjọ karun un oṣu keji ni wọn bi agba oṣere yii.

Faithia Williams wa lati ilu Urhobo nipinlẹ Delta ṣugbọn wọn bi si ilu Ikeja nipinlẹ Eko ni odun 1969.

O fi igba kan jẹ iyawo fun gbajumọ oṣere mii, Saheed Balogun, ti wọn si bimọ meji fun ara wọn.

Ere sinima 'Ta lo pa Chief' ni sinima akọkọ to kopa ninu rẹ, to si tẹsiwaju lati gbe ọpọ sinima sita ni orukọ rẹ.

Williams gba ọpọ ami ẹyẹ nidi ere sinima agbelewo.