Ọ̀dọ́mọdé Kábíyèsí tó ń kẹ́kọ̀ọ́ ní fásítì bó ṣe ń ṣàkóso ilú sọ ìrírí rẹ̀ lórí oyè

Ọba Oloyede Adeyeoba Akinghare Keji ti Okeluse nipinlẹ Ondo ti sọ pe nnkan to mu oun gẹgẹ bi ori ade kuro laafin lọ si ile ẹkọ tumọ si pe ẹkọ ṣe pataki ni.
Ọba Akinghare ni awọn akẹkọọ ko mọ pe ọba alade loun lọjọ toun kọkọ de ile ẹkọ.
Ọba Oloyede jẹ ọkan lara awọn ori ade ti ọjọ ori wọn kere julọ nilẹ Yoruba.
Lọdun 2022 to si wa ni ile ẹkọ girama ni kabiyesi Akinghare gori oye.
Lẹyin naa ni o tẹsiwaju ẹkọ rẹ ni ile ẹkọ giga fasiti Afe Babalola.
Ọba Akinghare ni ''idi ti mo fi wa si fasiti ni pe mo fẹ kọ ẹkọ nipa eto iṣelu nitori o papọ mọ nnkan ti mo n ṣe gẹgẹ bi Ọba ilu Okeluse.
Mo maa n rin bi awọn akẹkọọ yooku lọ si yara igbẹkọ lati ibi to mo n gbe ni.
Ẹkọ ti mo n kọ ko ṣe idiwọ fun mi lati ṣe eto ilu gẹgẹ bi ọba.
Mo maa n kọju mọ eto ẹkọ mi nigba kugba ti mo ba ti wa nile ẹkọ.
Awọn ijoye mi naa si maa n ran mi lọwọ pẹlu iṣẹ ilu nigba ti mo ba ti wa nile ẹkọ.
Ohun kan ti wọn kan maa n beere lọwọ mi aṣẹ lati ṣe nnkan to ba nilo aṣẹ mi.''
Ọba ilu Okeluse sọ pe iwe toun n ka ti jẹ ki bi oun ṣe n ronu yatọ si ju ti atẹyinwa lọ.
Kabiyesi naa ni bo tilẹ jẹ pe ọdọ loun, Eledua foun ni ọgbọn ati imọ lati maa dari awọn eeyan Okeluse.
Ọba Akinghare wa rọ gbogbo awọn ọdọ ilu Okeluse wi pe ki wọn kọju mọ ẹkọ wọn tori ẹkọ ṣe pataki gan an.






