Ìjàmbá ọkọ̀ gba ẹ̀mí akẹ́kọ̀ọ́ KWASU tó fẹ́ ṣe ìdánwò àṣekágbá

Aworan ẹnu ọna abawọle Kwasu

Oríṣun àwòrán, KWASU

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ariwo ẹkun gbode kan lọjọ kẹrin Oṣu Keji ọdun yii ni ilu malate ni ijọba ibilẹ Moro nipinlẹ Kwara nigba ti ọkọ gba akẹkọọ kan, to si jade laye lẹsẹkẹsẹ.

Akẹkọọ ọhun, Arẹmun Agboluaje lo wa ni ipele asekagba ni ile ẹkọ giga fasiti ijọba ipinlẹ Kwara KWASU to wa ni Malete

Oloogbe naa fẹ se asakagba idanwo rẹ ni ile ẹkọ naa nigba to jade laye.

Lasiko to n ba akọroyin wa sọrọ, ọkan lara awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa ti ko fẹ ki darukọ oun sọ pe akẹkọọ naa sa ere bọ ki le de idanwo to fẹ ṣe ni ọlọjọ de ba.

O salaye pe iku akekọọ naa dun ọpọ akẹkọọ ati o jẹ nnkan ti ko yẹ wa ye lasiko idanwo asekagba.

Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe waye?

Lọjọ kẹrin Oṣu Keji ọdun yii ni Arẹmu Agboluaje gbera kuro ni ile rẹ, to si morile ile ẹkọ giga fasiti ijọba ipinlẹ Kwara KWASU lati lọ ṣe idanwo asekagba rẹ.

Gẹgẹ bii akẹkọọ kan tọrọ soju ẹ, Fọlasade Raphel ṣe ṣalaye fun akọroyin ileeṣẹ BBC Yoruba sọrọ ni bi Arẹmu Agboluaje ṣe fẹ wọ inu gbọgan idanwo ni awọn alamojuto eto idanwo bere Kadi idanimọ rẹ ID CARD)

O salaye pe ni oloogbe naa ni oun gbagbe rẹ si Ile.

O ni oloogbe naa sare gbe ọkada rẹ to si lọ ile to n gbe lati lọ mu kaadi naa wa ki o le raye ṣe idanwo rẹ.

Folashade salaye siwaju pe bi Arẹmu se n gun ọkada rẹ, ni ọkọ kan kọlu ọkada naa to si jade laye.

O salaye pe iṣẹlẹ naa ba awọn akẹkọ lọkan jẹ pupọ.

O salaye pe ọkada rẹ ti wọn pe ni Lady Machine lo gun lọjọ nna.

Kini ohun ti alaṣẹ ile ẹkọ naa sọ

Akọwe agba ile ẹkọ giga fasiti ijọba ipinlẹ Kwara Dr Kikẹlọmọ Saale ti ba awọn obi akẹkọọ naa kẹdun .

Ninu Atẹjade kan Dr Kikẹlọmọ Salle fi sita ni lorukọ igbimọ alaṣẹ ile ẹkọ ọhun ati lorukọ Ọga agba ile ẹkọ lo ti ba awọn mọlẹbi oloogbe naa kẹdun, to si gba ladura Ọlọrun yoo duro ti wọn.

Ile ẹkọ naa tun ba gbogbo akẹkọọ ile ẹkọ naa kẹdun lori iṣẹlẹ iku ọkan lara wọn.

O fikun pe iṣẹlẹ naa ba ile ẹkọ naa lọkan jẹ pupọ, to si ṣapejuwe iku ọmọkunrin gẹgẹ bii ohun to gba omije loju.

Ile ẹkọ naa gbadura ki Ọlọrun tu awọn obi oloogbe ati awọn akẹkọọ akẹgbẹ rẹ ninu .

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post