Ìtàn tó rọ̀ mọ́ orúkọ Kòbọmọjẹ́ ní Ibadan àti ìdí tí àṣà dídá abẹ́ f'ọmọbìnrin ṣe dohun ìgbàgbé ní agboolé náà

Àkọlé fídíò, KOBOMOJE
Ìtàn tó rọ̀ mọ́ orúkọ Kòbọmọjẹ́ ní Ibadan àti ìdí tí àṣà dídá abẹ́ f'ọmọbìnrin ṣe dohun ìgbàgbé ní agboolé náà

Láyé àtijọ́ nílẹ̀ Yorùbá, ọmọbìnrin tí kò bá dábẹ́ kò pé lọ́mọbìnrin gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn babańlá wa.

Ìgbàgbọ́ wọn ni pé ọmọbìnrin tí wọ kò bá dábẹ́ fún ṣeéṣe kó máa rin ìrìn àrè tàbí kó má lè mú ara dúró láì rí ọkùnrin.

Ọ̀pọ̀ ìdílé ni wọ́n yan iṣẹ́ abẹ dídá láàyò láyé àtijọ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ àmọ́ lóde òní àṣà yìí ti ń di ohun ìgbàgbé nítorí àwọn ewu tó rọ̀ mọ́.

Bákan náà ni àyípadà ti ń bá abẹ́ dídá fún ọmọbìnrin nítorí òfin tó de abẹ́ dídá.

Ìjọba Nàìjíríà ní ipele ìjọba àpapọ̀ àti àwọn ìpínlẹ̀ ni wọ́n ti gbé òfin kalẹ̀ láti dènà dídábẹ́ fún ọmọbìnrin.

Èyí ló gbé BBC News Yorùbá dé Agboolé Kòbọmọjẹ́ ní ìlú Ibadan, olú ìlú ìpínlẹ̀ Oyo níbi tí àṣà abẹ́ dídá fún ọmọbìnrin ti máa ń wáyé tẹ́lẹ̀.

Ohun eelo fun abẹ dida ati aworan Mogaji ile Kobomoje

'Àṣà ni ilà kíkọ nílẹ̀ Yorùbá, fún ìdánimọ̀ sì ni'

Mogaji ilé Kòbọmọjẹ́, Abdulwasiu Ademola Balogun ṣàlàyé pé àṣà ni ilà kíkó jẹ́ nílẹ̀ Yorùbá àti pé wọ́n máa ń lò ó láti gẹ́gẹ́ ohun ìdánimọ̀ ni.

Ó sọ pé ilà kíkọ bẹ̀rẹ̀ ní ìdílé wọn nígbà tí babańlá àwọn máa ń bí àbíkù púpọ̀.

Ó ní ìgbà tí wọ́n kàn sí Ifá láti mọ ìdí tí wọ́n fi ń bí àbíkù ni ifá sọ fún wọn láti máa kọ ilà tó wà lójú ìyáńlá àwọn.

Ó ní èyí ló bí ilà kíkọ ní ilé àwọn àti pé wọ́n máa ń gbé olólà láti ìta láti wá kọ ilà fún ojú àti ti ìdí nígbà náà ni.

Ó fi kun pé gbogbo nǹkan yìí ti di ohun ìtàn báyìí nítorí ọ̀pọ̀ àwọn ni kò mọ iṣẹ́ náà ṣe àti pé ayé ti lajú ju gbogbo àwọn ìgbàgbọ́ àwọn babańlá wa.

"Òfin ti wà tó de abẹ́ dídá fún obìnrin ní ìpínlẹ̀ Oyo àti Nàìjíríà lápapọ̀. Àwọn obìnrin tó lajú ló wà nísìnín, wọn ò ní gbé ọmọ wọn sílẹ̀ fún irú àṣà bẹ́ẹ̀.

"Ayé ìgbà kan nìyẹn, ilé ìwòsàn ìgbàlódé ni à ń bímọ sí báyìí, ayé ìgbà yẹn ilé lọ̀pọ̀ ń bímọ sí.

Mogaji náà sọ pé ìdí nìyí tí òun fi gbé ètò kan kalẹ̀ láti fi ṣe ìlanilọ́yẹ̀ fáwọn èèyàn lórí ewu tó wà nínú dídábẹ́ fọmọbìnrin.

Báwo ni wọ́n ṣe gba orúkọ Kòbọmọjẹ́?

Abdulwasiu Ademola Balogun

Mọgaji náà ṣàlàyé pé láyé Babańlá àwọn tó jẹ́ Balogun tó kópa ribiribi sí ọ̀rọ̀ ìlú Ibadan ni àwọn gba orúkọ náà.

Ó ní àwọn ìjọba amúnisìn nígbà náà gbé òfin kan dìde pé àwọn obìnrin gbọ́dọ̀ máa san owó orí gẹ́gẹ́ bí àwọn ọkùnrin ṣe ń san.

Ó ṣàlàyé pé Bàbá náà ni pé àwọn kò ní gbà kí àwọn obìnrin máa san owó orí nítorí àwọn kìí ṣiṣẹ́ lásìkò náà àti pé gbogbo Ibadan ti fẹnukò pé àwọn obìnrin kò ní san owó orí.

"Àwọn òyìnbó yẹn lábẹ́ ìdarí Captain Rose bá ní àwọn fún ni ọjọ́ láti fi ìlú, ó dẹ̀fárígá pé nǹkan tí òun sọ yẹn, ẹ̀yìn òun ni wọ́n ti lè ṣé, wọn ò lè ṣe é lójú òun.

"Ìgbà tó délé, ó gbé àsèjẹ sílẹ̀, ó ṣe àjọyọ̀. Ìgbà tí àsìkò tí wọ́n fún un pé, bàbá wọ káà, ó lọ ṣe bí ọkùnrin pé kàkà kí ilẹ̀ kú ilẹ̀ á ṣá."

Ó sọ síwájú pé nígbà tí òyìnbó ri pé ó pa ara rẹ̀ ló wà sọ pé "akọni ni ọkùnrin yìí, ibi tí Kòbọmọjẹ́ ti jáde nìyẹn, ìnagijẹ ni Kòbọmọjẹ́, kìí ṣe orúkọ àbísọ fún wa."