Àwọn ajínigbé gba mílíọ̀nù méjìlá náírà, power bank méjì láti tú Ọba Olanipekun tí wọ́n jí gbé ní Kwara sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Pastor Samuel Ajayi
Awọn ajinigbe to ji ọba ilu Aafin Ilere ni ijọba ibilẹ Ifelodun ipinlẹ Kwara, Ọba Simeon Ọlanipẹkun Aniwọ gbe ti yọnda Ọba naa.
Awọn ajinigbe yọnda Ọba Olanipekun lalẹ ọjọru, ọjọ Kẹrin, oṣu Keji, ọdun 2026 lati bii oṣu kan abọ ni akata awọn ajinigbe naa.
Owo milionu mejila naira ni wọn san lati fi gba itusilẹ ọba naa.
Ni ọjọ Kẹrinlelogun oṣu Kejila, ọdun 2025 ni awọn ajinigbe naa ji Kabiyesi ati ọmọ rẹ, Olaolu to jẹ agunbanirọ gbe, ti wọn si yinbọn ba olori.
Ṣaaju ni wọn ti yọnda Ọlaolu ọmọ kabiesi lẹyin ti wọn gba owo ogun milionu naira.
Oníwàásù ijọ CAC ti kabiesi n lọ ni ilu Idọfian, Ẹniọwọ Samuel Ajayi fìdi ẹ mulẹ fun BBC News Yoruba pe awọn ajinigbe naa ti yọnda kabiesi.
O ṣalaye pe awọn ajinigbe naa gba owo millionu mejila naira ati power bank meji, ki wọn to yọnda Ọba Ọlanipẹkun.
O fikun pe inu gbogbo ilu lo dun bi wọn ṣe foju ri kabiesi wọn pada lẹyin ọjọ marundinlogoji ti kabiesi ti lo lakata awọn ajinigbe.
O sọ pe niṣe ni gbogbo awọn ara ilu naa tu jade lati wa wo kabiesi wọn to pada de, ṣe aja to lọ ile ẹkun to bọ o tọ ka ki ku oriire.
Bawo ni Ọba Olanipekun ṣe ko Sakata awọn ajinigbe?
Lalẹ ọjọ aisun ọdun Keresimesi ọdun 2025 ni awọn ajinigbe naa yawọ Aafin ilere to wa ni ẹkun Oreke lagbegbe Babanla ni ijọba ibilẹ Ifẹlodun, ipinlẹ Kwara, ti wọn si ji Ọba Simeon Ọlanipẹkun Aniwọ ati ọmọ rẹ ọkunrin Ọlaolu to jẹ agunbanirọ gbe.
Wọn yinbọn mọ Olori Felicia Ọlanipẹkun lasiko ikọlu naa.
Lati igba naa ni awọn ara ilu naa o ti loju orun mọ ti wọn n sa sokesodo lati doola kabiesi wọn.
Awọn ajinigbe naa ti ṣaaju dunkoko pe awọn maa gbẹmi Kabiesi ati ọmọ rẹ ti awọn mọlẹbi wọn o ba san owo iyọnda ọgọrun-un kan milionu naira ko to di pe wọn din owo itusilẹ naa ku si aadọta milionu naira.
Bawo ni wọn ṣe yọnda Ọlaolu ọmọ Kabiyesi?
Nnkan bi ọsẹ meji sẹyin ni awọn ajinigbe naa yọnda Ọlaolu ọmọ Kabiesi, lẹyin ti wọn gba ogun milion naira.
Agbegbe Oreke lẹgbẹẹ ilu Babanla nijọba ibilẹ Ifẹlodun ni awọn ajinigbe ti yọnda ọmọ kabiesi.
Lasiko to fìdí ọrọ naa mulẹ, Pasitọ Samuel Ajayi sọ pe awọn ọmọ ogun lo pada gbe ọmọ naa de ibi ti o ti wọ ọkọ.
Agbegbe ìjọba ibilẹ Ifẹlodun ipinlẹ Kwara jẹ ibi tawọn ajinigbe n kọlu ni ipinlẹ Kwara.
Lọsẹ to kọja ni kabiyesi pe lori ẹrọ ibanisọrọ pe, ara oun ko le mọ.
Kini igbesẹ ti ijọba gbe lori awọn agbebọn ni Kwara?
Lati bii ọsẹ meji sẹyin lawọn ọmọ ogun ti n ju ado oloro lu ibuba awọn ajinigbe ni ẹkun Guusu Kwara.
Lara awọn agbegbe ti awọn ọmọ ogun ijọba ti n ṣiṣẹ ikọlu naa ni ijọba ibilẹ Ifẹlodun, Ekiti, Isin, Oke ẹrọ ati Irẹpọdun ti gbogbo rẹ wa lẹkun guusu ipinlẹ Kwara.
Eyi to mu ki ijọba gbe gbogbo awọn ile ẹkọ to wa ni ijọba ibilẹ naa ti pa lati inu oṣu Kọkanla ọdun to kọja ki wọn to ṣi wọn pada lọjọ Aje, ọjọ Keji, ọdun yii lẹyin ti awọn ọmọ ogun bẹrẹ si ni gbena woju awọn agbebọn naa, ti wọn si ni awọn agbegbe ti ni aabo.


























