A ti sin òkú Aunty Ajara, ẹ má dá owó fún ẹnìkankan mọ́- Ridwan Lasisi

Oríṣun àwòrán, Others
Wọn ti sin òkú Aunty ajara nilana ẹsin Musulumi ni ana.
Ajara Lasisi, Oṣerebinrin ti ọpọ mọ si Aunty Ajara ni wọn ti sin ara rẹ si kaa ilẹ lana, ọjọ karun un, oṣu keji, ọdun 2025 lẹyin ti ẹgbọn rẹ. Lasisi Ridwan kede pe o ti papoda to si ni ki awọn eeyan to n dawo ile iwosan ma da a mọ pẹlu ọpẹ si awọn ọmọ Naijriia fun aduroti.
Ọpọ ero lo peju [pesẹ sibi isinku naa pẹlu omije loju.
Awọn Aafa nilana Musulumi kirun si Aunty Ajara lara lẹyin ti wọn ti fi aṣo fun fun wee ki wọn to tun fi ẹni we e, ki wọn to gbe ara rẹ sinu saare ti wọn ti gbẹ silẹ.
Awọn ẹbi, ara ati ọrẹ lo wa nibi eto isinku naa pẹlu ẹkun ati idaro ti wọn si n ṣapejuwe Aunty ajara gẹgẹ bii ẹni to ni iwa tutu.
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ṣi n ranṣe ibanikẹdun lori ayelujara ti wọ si n ṣapejuwe iru ẹni ti Aunty Ajara jẹ.
Ridwan Lasisi to jẹ ẹgbọn oloogbe sọ pe ki ẹnikẹni ma da owo iranwọ mọ nitori Aunty Ajara nitori pe ẹmi rẹ ti pada sọdọ Olodumare to daa wa saye.
Saaju ni wón ti n beere fun iranlọwọ oloju aanu lati le fi ṣe itọju Aunty Ajara to wa lori idubulẹ aisan pẹlu oyun ninu nigba naa.
Àǹtí Ajara onítíátà jáde láyé lẹ́yìn àìsàn ẹ̀dọ̀ àti oyún tó ní
Gbajumọ oṣerebinrin tiata Yoruba ti ọpọ eeyan mọ si Anti Ajara ti jade laye.
Oṣere ẹgbẹ rẹ miran, Kudirat Shoremi (Mama no network), fidi iku naa mulẹ fun BBC News Yoruba laaarọ oni.
Gẹgẹ bo ṣe wi, mọjumọ oni Ọjọbọ, ọjọ karun-un oṣu Keji ọdun 2025 ni Anti Ajara jade laye.
Ṣaaju ni awọn oṣere ẹgbẹ rẹ ti ke gbajare, pe ki awọn ọmọ Naijiria ran awọn lọwọ nipa owo ti wọn yoo fi tọju Ajara, ẹni ti wọn ni ẹdọ rẹ ni iṣoro ba, ati pe oyun to ni lo da gbogbo wahala naa silẹ.
Igbiyanju ati ri owo naa ti i ṣe 100m ni won n ṣe lọwọ ti oṣere to jẹ akanda nipa aiga naa fi jade laye.
Ki lo pa Anti Ajara gan-an?
Gẹgẹ bi Mama no network ṣe ṣalaye, o ni:
" Nnkan bii oṣu Kọkanla ọdun to kọja ni ọrọ oyun to ni yẹn bẹrẹ.
" O maa n wa sọdọ mi daadaa, mo dẹ maa n ri i to maa n ba ọkunrin kan sọrọ lorii foonu, ti wọn a jọ maa sọrọ ifẹ, ṣugbọn mi o mọ ọkunrin naa.
"Oyun yẹn lo fọ gbogbo ẹ loju ninu aarẹ yii, aisan ẹdọ ni awọn dokita sọ pe o n ṣe Ajara, ṣugbọn oyun yẹn tun ko ba a.
"Wọn ni ka lọ mu 100m wa lati fi gbe e lọ si India fun itọju, nibo ni onitiata ti fẹẹ ri 100m, ohun to je ka jade beere iranlọwọ niyẹn, ṣugbọn awọn ti ko ye n bu wa.
"Ohun ti wọn o mọ ni pe ka too beere iranlọwọ, ọpọ ninu wa lo ti gbe owo silẹ, ẹni to gbe 500, 000 silẹ wa, kalulu da owo jọ fun Ajara, tori ọmọ daadaa ni."
Mama no network tẹsiwaju pe awọn gbiyanju fun Anti Ajara, ileewosan Ayinke lo wa n'Ikeja ki wọn too ni kawọn gbe e lọ sileewosan miran lati ibẹ.
O ni ọsibitu nla ni Oloogbe ti n gba itọju ti awọn si n wa owo fun un ki ọlọjọ too de .
Nipa ọkunrin to fun Anti Ajara loyun, Mama No Network ni iwadii ṣi n lọ lori rẹ, nitori Oloogbe funra rẹ ko sọ ẹni to fun un loyun ti ọlọjọ fi de
Ta a ni Anti Ajara?

Oríṣun àwòrán, Anti Ajara/ Instagram
Ko ti i pẹ ti Anti Ajara di ẹni ti igba oju mọ.
Mama no network sọ fun wa pe ko ti i ju ọdun meji lọ to de agbo tiata.
O ni Wumi Toriola lo mọ ọ daadaa to si gbe e jade, oun ni Ọlọrun lo lati sọ Ajara di 'star'.
O tẹsiwaju pe bo ṣe kuru ko di iṣẹ rẹ lọwọ, gbogbo oko ere lo maa n lọ.
Mama no network ṣalaye pe to ba rẹ Ajara sori ìrìn, ti ko le rin daadaa mọ, awọn eeyan maa n gbe e nibi ti wọn fẹran rẹ de.
"Ọmọ to nitẹriba ni Ajara, o daa, o ni ibọwọ fun agba, bẹẹ lo ni aanu obi.
"Iya rẹ ṣi wa laye, iya naa ni arun rọparọsẹ, Ajara maa n lọ fun wọn lowo to ba ṣiṣẹ. Iku ọmọ yii dun mi gan-an.''
Bẹẹ ni oṣere toun naa maa n kopa akanda ẹda ti ki i gbọrọ bọrọ naa sọ nipa Anti Ajara, oṣerebinrin ti wọn gbiyanju fun ṣugbọn ti ẹpa ko boro mọ.
Ninu ifọrọwerọ kan ti Oloogbe Ajara ṣe ri lo ti ni oun ti figba kan loyun ri ti oun si bimọ naa, o ni ṣugbọn ọmọ ọhun ko yè.
O ṣalaye nigba naa pe ẹni to fun oun loyun naa fipa ba oun laṣepọ ni.


























