A ti fi ikọ ológun tí yóò kún Naijiria lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun agbésùnmọ̀mí ránṣẹ́- Ológun America

Oríṣun àwòrán, USAFRICA/COMMAND/X
Ileeṣẹ ologun ilẹ America ti kede pe oun ti fi iko ologun kekere kan ranṣẹ si Naijiria, lati ran awọn ologun ilẹ yii lọwọ ninu iyanju wọn lati ṣẹgun awọn agbesunmọmi.
Ọga ologun oju ofurufu, Dagvin R. M. Anderson to n ri si ọrọ ilẹ Africa l'America; 'U.S. Africa Command' (AFRICOM), lo fidi eyi mulẹ lọjọ Iṣẹgun ana.
Ọgagun Anderson sọ fun awọn akọroyin pe, awọn ran ikọ naa wa si Naijiria lẹyin ti ajọsọ ti waye laaarin ijọba orilẹede mejeeji.
Ọgagun Anderson fi kun un pe ipade kan to waye pẹlu Aarẹ Tinubu lo bi wiwa ti awọn ologun America wa si Naijiria bayii, wọn yoo si ṣe iṣẹ to gbe wọn wa bo ṣe yẹ.
O ni ohun gbogbo wa lojuna ati mu ajọṣepọ ti yoo ṣẹgun awọn agbesunmọmi waye ni Iwọ-Oorun Africa.
Ọgagun Anderson ṣapejuwe ikọ ologun tuntun ti wọn ran wa si Naijria bayii bii awọn ti wọn n gbe agbara to yatọ bọ lati America.
Amọ ko ṣalaye bi awọn ologun ọhun ṣe pọ to, tabi iṣẹ ti wọn yoo fi bẹrẹ pato.
Ikede yii n waye lẹyin ikọlu iṣaaju ti America ṣe si Naijiria lọjọ Keresimesi ọdun 2025.
Ohun ti Aarẹ Donald Trump sọ nigba naa ni pe oun doju kọ awọn alakatakiti ẹsin Islam ti wọn jẹ ẹgbẹ agbesunmọmi, ti wọn si n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹgbẹ naa to wa ni ẹkun miran.
Eyi ni igba akọkọ ti orilẹede America yoo kede ni gbangba pe oun fi ọmọ ogun ranṣẹ si Naijiria, lẹyin ikọlu akọkọ to waye lọdun to kọja.
Ado oloro ti wọn ju si apa kan ipinlẹ Sokoto lọdun to kọja naa ni wọn lo mu awọn agbesunmọmi to wa lagbegbe naa balẹ.
Tẹ o ba gbagbe, ikọlu, ipaniyan, ijinigbe ati ai si ifọkanbalẹ to gbilẹ lẹka aabo ti n waye tipẹ ni Naijiria.
Bo tilẹ jẹ pe awon to n ṣiṣẹ laabi yii ko mọ Kristeni yatọ si Musulumi, to jẹ bi wọn ṣe n wọ ṣọọṣi paayan naa ni won n wọ mọṣalaṣi.
Ṣugbọn ohun ti Aarẹ Donald Trump sọ ni pe ipanirun (Genocide) lo n koju awon Kristẹni ni Naijiria.
Idi si niyẹn ti ọwọja rẹ ṣe de ipinlẹ Sokoto ti wọn kọkọ dojukọ ni Naijiria lọjọ ọdun Keresimesi to kọja.
A ti gba ikọ ologun America ni Naijiria-
Nigba to n fidii wiwa awọn ologun America naa mulẹ ni Naijiria, Minisita eto idaboobo, Ọgagun Christopher Musa, sọ fun BBC pe ikọ ologun kekere naa yoo maa kọ awọn ologun Naijiria niṣẹ.
Ọgagun Musa ko ṣalaye bi awọn ologun America naa ṣe pọ to, tabi asiko ti wọn yoo fi wa ni Naijiria dà.
Fun ọdun pipẹ ni ologun Naijiria pẹlu America ti jọ kẹkọọ pọ lori iṣẹ ologun.
Ohun ti ẹkọ naa si maa n da le lori ni ọtẹlẹmuyẹ, igbogunti wahala ati idari.


























