Ọ̀kadà tí wọn gbé wa tó 80, wọ́n tò ní méjì, mẹ́ta sórí ọ̀kadà kọọkan, wọ́n mura bii ológun- Emir Kaiama

"Wọn ti kọkọ kọwe si olori ilu Woro, Saliu Bio Umar ni osu Kejila ọdun to kọja wi pe awọn n bọ wa ṣe waasi ni ilu naa ti Saliu si wa fi ọrọ naa to mi leti.
"Ohun lo faa ti ijọba fi ko awọn sọja, awọn aṣọgbo ati awọn agbofinro mii lọ sibẹ lati maa daabo bo ilu naa.
"Igba to pẹ ti a ro wi pe wọn ti gbagbe, wọn ko awọn ikọ ogun wọnyi kuro lọ awọn agbegbe mii ti wọn nilo aabo.
Emir ti ilu Kaiama ni ijọba ibilẹ Kaiama ni ipinlẹ Kwara, Alhaji Sheu Umar Muazu Bagidi, ti sọ pe awọn agbebọn to ṣekọlu si ilu Woro ati Nuku ti kọkọ kọwe ransẹ pe awọn n bọ wa ṣe waasi lai mọ pe ipaniyan ni wọn fẹ wa ṣe.
Awọn ilu mejeeji yii ti wọn wa labẹ isakoso Emir naa ni awọn agbebọn kọlu lọjọ Kẹta, oṣu Keji, ọdun 2026, ti wọn si pa awọn ọkunrin to n lọ bi ọgọrun-un.
Lẹyin naa ni ji, awọn obinrin ati awọn ọmọde ti gbogbo wọn le ni aadọta, gbe sa lọ.
BBC News Yoruba sabẹwo si ilu Kaiama, Woro ati Nuku lati mọ ohun ti o fa ikọlu yii ati iye awọn eniyan to ba ikọlu naa lọ ni pato.
'Wáàsí làwọn agbébọn tọ ṣèkọlù sí Woro ní àwọn ń bọ̀ wá ṣe, àfi bí wọ́n ṣe dé tí wọ́n ṣíná ìbọn bolẹ̀'
Ni aafin Emir ilu Kaiama ni Emir naa ti salaye fun awọn akọroyin bi iṣẹlẹ naa ṣe waye.
"Wọn ti kọkọ kọwe si olori ilu Woro, Saliu Bio Umar ni osu Kejila ọdun to kọja wi pe awọn n bọ wa ṣe waasi ni ilu naa ti Saliu si wa fi ọrọ naa to mi leti.
"Ohun lo faa ti ijọba fi ko awọn sọja, awọn aṣọgbo ati awọn agbofinro mii lọ sibẹ lati maa daabo bo ilu naa.
"Igba to pẹ ti a ro wi pe wọn ti gbagbe, wọn ko awọn ikọ ogun wọnyi kuro lọ awọn agbegbe mii ti wọn nilo aabo.
"Igba to di ọjọ Kẹta osu yii, bi wọn ṣe de niyẹn o, gẹgẹ bi wọn ṣe fi to mi leti, ọkada ti wọn gbe wa to ọgọrin, wọn to meji meji, mẹta mẹta lori ọkada kọọkan."
Emir naa ṣalaye pe awọn agbebọn naa mura bi awọn ọmọ ogun ti wọn si sina ibọn bolẹ, awọn kan sa asala wọ inu igbo lai mọ pe wọn ti yii gbogbo ilu ka.
"Awọn tinu igbo yinbọn fun wọn, wọn kọja lọ ile olori ilu, wọn yinbọn pa ọmọ rẹ ọkunrin meji ti wọn sẹsẹ yege gẹgẹ bii dokita oyinbo, wọn si ji awọn iyawo ati ọmọ obinrin gbe lọ.
O sọ pe ẹsun tawọn agbebọ naa fi kan awọn araalu ti wọn ṣe ikọlu si ni pe kaka ki wọn farabalẹ fun ẹkọ waasi awọn, ilu lọ fẹjọ awọn sun awọn agbofinro.
Emir fi kun pe awọn agbebọn naa so awọn eeyan lọwọ sẹyin ki wọn to maa dunbu wọn bi ẹran tabi ki wọn fun wọn nibọn lórí.

A ti sin òkú tó le ní méjìdínlọ́gọ́rin, o ti rẹ awọn to n gbẹlẹ gan – Araalu
Ọkan lara awọn eekan ilu ni Kaiama, Abdullahi Umar Usman sọ pe o seese ki agbodegba wa laaarin awọn ọmọ ilu.
O ni ti koba si agbodegba ni, bawo ni wọn ṣe mọ ibi ti olori ilu n fi kọkọrọ ọkọ rẹ si ti wọn fi ji iyawo atawọn ọmọ rẹ gbe lọ.
O ni oun gbagbọ pe ti iku ile ko ba pani, tita ko le ni agbara lori awọn.
Oku eeyan mejidinlọgọrin ni wọn ti sin ni ilu Woro ati Nuku ti ikọlu naa ti waye.
Ọkan lara awọn to n seto bi wọn ṣe n sin awọn ti wọn pa, Mohammed Bawa Aliu, sọ fun BBC News Yoruba pe awọn ti sin oku to le ni mejidinlọgọrin to si tun jẹ pe oku si tun ku nilẹ, sugbọn o ti rẹ awọn to n gbẹlẹ, wọn o lokun mọ lati tẹsiwaju.
O fi kun pe ọkọ olori ilu naa ni wọn fi gbe awọn iyawo ati awọn ọmọ rẹ lọ.
Gbogbo ìlú dá páro, kò sí èèyàn kan mọ́ nílùú Woro

Nigba ti BBC News Yoruba de ilu Woro ni oru ọjọru mọjumọ ọjọbọ, a ri pe ko si araalu kan mọ nibẹ, niṣe ni gbogbo ilu da paro.
Awọn ti o mọribọ nibi ikọlu naa ti sa kuro latari ọgbẹ ọkan ati ibẹrubojo, to si jẹ pe awọn ọmọ ogun, to n da aabo bo ilu naa lo ku sibẹ.
Ni nnkan bii aago kan oru ti BBC News Yoruba de si ilu Woro, niṣe ni ina ṣi n jo ninu awọn ile tawọn agbebọn naa dana si.
Ohun ti a gbọ ni pe niṣe ni awọn agbebọn naa ko awọn fijilante ti ibọn ko wọle si lara sinu ile kan, wọn si sọna sile naa titi tawọn eeyan naa fi jo pa mọnu ile.
Bakan naa ni wọn tun sọna sawọn ile mii lati jo ọpọ ile.
Iwadii wa fi han pe nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kẹta, oṣu Keji lawọn agbebọn naa bẹrẹ ọṣẹ niluu naa, ti wọn si wa nibẹ di nnkan bii aago marun-un si mẹfa idaji ọjọ keji ti n ṣe ọjọru, ọjọ Kẹrin.
Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq naa ṣe abẹwo si ilu naa to si bawọn kẹdun lori adanu wọn ati lati mọ igbesẹ to ku lati gbe lati dẹkun awọn isẹ laabi yii.
Àwọn agbébọn tó lé nígba ló yawọ ìlú wa, wọ́n pa àwọn èèyàn bí ẹran - Aráàlú Woro ní Kwara

Oríṣun àwòrán, Others
Ọjọ buruku esu gbo mimu ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kẹta, oṣu Keji, ọdun 2026 jẹ fun awọn eeyan ilu Woro ati Naka ni ẹkun ariwa ipinlẹ Kwara latari bi awọn agbebọn ṣe yawọ ibẹ, wọn si ṣekupa o kere tan, eeyan mejilelọgbọn, ti wọn si tun dana sun ọpọ ile.
Iwadii BBC News Yoruba fi han pe, awọn agbebọn ti wọn le ni igba lo yawọ awọn ilu yii ni bii aago mẹfa irọlẹ, ti wọn si dabọn bolẹ lati da ibẹrubojo silẹ.
Araalu kan ti ko fẹ ka darukọ oun sọ fun wa pe awọn agbebọn naa le ni igba, wọn si pa ọpọlọpọ eniyan, ọpọ eeyan si tun sa asala fun ẹmi wọn wọ inu igbo.
Wọ́n pa àwọn ènìyàn bí ẹran
Fun ọgbẹni Ahmed Alhassan, adanu nla ni iṣẹlẹ naa jẹ fun wọn nitori oku ti wọn ti ri, lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, ti le ni mejilelọgbọn, wọn si tun jo ọpọlọpọ ile, to fi mọ ile ọba Wọrọ.
Alhassan ṣalaye pe ilu Wọrọ ati Nuku w ani ẹgbẹ ara wọn ti eyi si mu ko rọrun fawọn agbebọn naa lati ṣekọlu si ilu mejeeji lẹẹkan naa.
"Wọn pa awọn eeyan bi ẹran, wọn o tun pa wọn lasan, ṣe ni wọn so wọn lọwọ sẹyin ki wọn to yin wọn ni ibọn.
"Lẹyin eyi ni wọn tun sọna si awọn ile igbe ati ile ọba Wọrọ."
O ni ohun iyalẹnu ni pipa awọn eeyan lọpọ yanturu yii jẹ nitori ohun ti awọn agbebọn naa maa n ṣe sẹyin ni lati ji awọn eeyan gbe lati fi gba owo.
"Ohun ti a mọ awọn ajinigbe yii si ni ki wọn ji eeyan gbe, ki wọn si gba ransọmu, amọ bi wọn ṣe wa lati pa awọn eeyan yii jẹ ijọlọju.
"Ohun ti emi ro ni pe wọn wa yọ oro ikọlu ti ijọba n ṣe si wọn lọwọ lara awọn araalu ni."
Alhassan fi kun pe ijọba ti kọkọ da awọn ọmọ ogun sinu igbo ti wọn si ti n gbena woju awọn agbebọn wọn yii.
"Mo le ro pe eyii lo bi wọn ninu ti wọn fi wa pa awọn eeyan ni ipakupa."
Kí ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ?
Iléeṣẹ́ ọlọ̀pàá ìpínlẹ̀ Kwara ti fidi ikọlu to waye lawọn ilu Woro ati Nuku mulẹ fun BBC.
Agbẹnusọ ọlọpaa Kwara, Adetoun Ejire-Adeyemi sọ fun BBC pe awọn ko i tii le fidi iye eeyan to ba ikọlu naa lọ mulẹ amọ ọpọ awọn oku ni awọn ti ri, ti awọn si tun ri awọn eeyan to fara gbọta.
Ejire-Adeyemi ni iwadii ṣi n lọ lọwọ amọ ko I tii fidi ikọ agbeṣumọmi to ṣiṣẹ naa mulẹ bayii ṣugbọn awọn fura si awọn agbebọn ati ikọ ISWAP.
O fi kun pe ileeṣẹ ọlọpaa atawọn ọmọ ogun ti wa ni agbegbe naa lati ri pe alaafia bọ sipo lawọn agbegbe naa.
Bakan naa lo ni awọn ko le sọ boya awọn agbebọn naa ji ẹnikẹni gbe.
Awọn agbebọn to ṣe ikọlu si Woro ati Nuku fẹ fọgbọn di awọn ọmọ ogun lọwọ iṣẹ wọn - Ijọba Kwara
Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq ti wa bẹnu atẹ lu ikọlu naa, to si tun ba awọn ti ọrọ kan kẹdun.
Ninu atẹjade ti Rafiu Ajakaye to jẹ agbẹnusọ fun gomina fi lede, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sọ pe iwa ojo gbaa ni awọn agbebọn naa wu.
Gomina ni awọn ṣe ikọlu naa lati gbẹsan bi awọn ọmọ ogun ṣe n gbena woju awọn agbebọn ninu igbo lọwọlọwọ.
O ni oun ba awọn eeyan ilu Woro ati Nuku kẹdun lori adanu wọn paapaa awọn to padanu eeyan wọn ninu ikọlu naa.
Agbébọn tún pa ọ̀pọ̀ èèyàn ní Kwara, dáná sun ààfin ọba

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nnkan ko fararọ nipinlẹ Kwara, pẹlu bi awọn agbebọn ṣe tun ya wọ ilu kan nibẹ ti a mọ si Woro,nijọba ibilẹ Kaiama ti wọn pa ọpọ eeyan, ti wọn si tun dana sun aafin ọba ilu naa.
Ana ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹta oṣu Keji ọdun 2026 yii ni ikọlu tuntun naa waye.
Gẹgẹ bi awọn olori agbegbe Woro ṣe wi, ko din ni eeyan ọgbọn (30) ti awọn agbebọn naa yinbọn pa.
Wọn ni nnkan ija oloro oriṣiriṣi to lagbara gan-an ni awọn apaayan naa gbe wa si Woro.
Wọn fi kun un pe bi wọn ṣe n yinbọn mọ awọn eeyan ni wọn n yinbọn si dukia.
"A gbọ pe oku ti to marundinlogoji si marundinlaadọta''
Ọmọ ile igbimọ aṣofin to n ṣoju agbegbe yii ni Kwara, Ọnarebu Sa'idu Baba Ahmed, sọ fun BBC pe:
"A gbọ pe oku eeyan ti wa laarin marundinlogoji si marundinlaadọta (35- 45), bo tilẹ jẹ pe a ko ti i fidi rẹ mulẹ."
O fi kun un pe ọpọ ṣọọbu ni awọn agbebọn naa tun sọ ina si to jo kanlẹ.
Yatọ si awọn to ni wọn pa, ọpọ eeyan lo tun sa wọgbo lọ pẹlu bi wọn ṣe ti farapa.
Nipa boya awọn to pa eeyan rẹpẹtẹ yii tun ji awọn miran ko wọgbo lọ, Ọnarebu Ahmed ni oun ko le fidi eyi mulẹ.
O ni ṣugbọn awọn agbebọn ọhun sọ ina si Aafin Emir Woro, wọn si jo o kanlẹ.
Bakan naa ni aṣofin yii sọ pe awọn ko ti I ti Arẹmọ Emir naa latigba ti ikọlu yii ti waye, bo tilẹ jẹ pe ọmọ naa ko si ni aafin nigba ti wọn de, ṣugbọn o wa laarin ilu Woro.
" Wọn jo aafin Emir kanlẹ pata ni, titi kan awọn ṣọọbu to wa nitosi aafin naa. "
"Awọn agbebọn ọhun ti kọ lẹta ṣaaju pe awọn n bọ waa kọlu ilu Nuku ati Woro"
Ni itẹsiwaju alaye Ọnarebu Sa'idu Baba Ahmed, o ni lẹta kan wa ti awọn agbebọn yii ti kọ ṣaaju si awọn oloye ilu Nuku ati Woro, ninu eyi ti wọn ti ni awọn n bọ waa kọlu wọn.
Aṣofin naa sọ pe lasiko naa ni awọn ṣeto awọn ologun si agbegbe naa lati koju wọn.
"Ṣugbọn wọn ko yọju lasiko ti awọn ṣọja wa nibẹ, wọn kan deede ya bo ilu lọjọ Iṣẹgun ni.''
O tẹsiwaju pe laipẹ yii naa ni awọn agbebọn kan wọ ilu Nuku, ni Kwara, nijọba ibilẹ Kaiama, to kọju si Woro.
O ni wọn pa awọn eeyan nigba naa pẹlu.
Bi ikọlu ana yii ṣe waye, Ọnarebu Ahmed ṣalaye pe awọn ṣọja to wa lagbegbe naa wọgbo lọ lẹyin ti wọn gbọ ohun to ṣẹlẹ, o ni ṣugbọn ko si aridaju pe wọn ri awọn to ṣiṣẹ ibi yii.
Igbagbọ ọpọ eeyan nipa awọn to ṣe ikọlu ana yii ni pe igbo Borgu, nipinlẹ Niger, ni wọn ti wa, eyi to paala pẹlu Kwara.
Ijọba ipinlẹ Kwara koro oju si iṣẹlẹ yii ninu atẹjade rẹ, bẹẹ ni wọn si ba awọn to padanu ẹbi wọn kẹdun.
Lasiko ti a pari iroyin yii, ileeṣẹ ọlọpaa Kwara ko ti I fi atẹjade kankan sita.
Tẹ o ba gbagbe, awọn ikọlu ti waye leralera nipinlẹ Kwara, paapaa lasiko ti ọdun 2025 n pari lọ, wọn ji awọn eeyan gbe, wọn si pa awọn mi-in.


























