Agbénipa bẹ́ orí, wọ́n tún la àyà òṣìṣẹ́ ìjọba ní Akure

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn agbenipa ni wọn tun ti ṣọṣẹ nilu Akure to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo ni bi wọn ṣe ge ori ọkunrin kan, Gbenga Olofingboyegun, lọ ti wọn si la aya rẹ.

Olofingboyegun to jẹ adari ẹka iwadi ati iṣiro lajọ to n moju to iṣẹ awọn olukọ (TESCOM) nipinlẹ Ondo lawọn mọlẹbi rẹ kede pe wọn ko mọ bo ṣe rin l'Ọjọbọ, ọjọ kini oṣu kẹsan ọdun yi lẹyin to kuro nibi isẹ lai dagbere.

Igbagbọ awọn mọlẹbi rẹ tẹlẹ ni pe wọn jii gbe ni, ti wọn si n reti ipe wọn lati dunadura.

Ẹwẹ ọjọ abamẹta, ọjọ kẹta oṣu yi wọn ri oku kan ti ko lori nile ẹkọ alakọbẹrẹ Saint Theresa nilu Akure ti wọn si fi to awọn agbofinro leti.

 Alukoro ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmi Odunlami, salaye fun BBC Yoruba pe lọsan Ọjọ abamẹta ni awọn araalu fi to awọn ọlọpaa leti pe wọn ri oku kan to ti n ra ninu ileewe kan ladugbo wọn.

 Odunlami wipe oku naa ni wọn ti ge ori rẹ lọ ti wọn si la aya rẹ lati ko awọn ẹya ara kan ninu rẹ leyii to jẹ ko ṣoro lati da oku naa mọ.

Amọ awọn mọlẹbi oloogbe naa lo da ẹni wọn mọ pẹlu aṣọ to wọ kuro nile lọjọ ti wọn rii kẹyin.