Àṣeyọrí Atiku ló ń ṣẹ̀rù ba Tinubu ló fi ń dojú kọ ọ́ – PDP fèsì

aworan Atiku ati Tinubu

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar ati Bola Ahmed Tinubu

Ẹgbẹ oṣelu PDP ti sọ pe aseyọri oludije ẹgbẹ oṣelu awọn, Atiku Abubakar lo n ṣeru ba ẹgbẹ oṣelu APC ati oludije rẹ, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu.

Agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Debo Ologunagba lo sọ eleyii di mimọ ninu atẹsita to gbe sori ayelujara.

O ni Tinubu ko koju osuwọn to lati di aarẹ ati pe ẹgbẹ APC ti kogba wọle nitori gbogbo lasigbo ti wọn ko ba orilẹede Naijiria.

Ologunagba ni ẹgbẹ oṣelu PDP wa ni isọkan, ti isẹ si n lọ lọwọ lati gba orilẹede Naijiria lọwọ PDP.

“Ohun iyalẹnu lo jẹ fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria bi oludije sipo aarẹ fẹgbẹ APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu se gbiyanju lati fi oju pa asise ẹgbẹ rẹ, to si kọju si ẹgbẹ oṣelu PDP ati Atiku Abubakar.

“Gbogbo awọn ọrọ yii lo tu asiri Tinubu gẹgẹ ẹni ti ko mọ nkan to yẹ, ti aseyọri oludije PDP ati Atiku Abubakar si n sẹru ba a saaju idibo ọdun 2023.

“Ẹgbẹ oṣelu APC ti ku tipẹ ti PDP si wa laye, fun idi eyi, ọrọ Tinubu ni ko ye.

PDP wa ni isọkan ti a si gbajumọ bi orilẹede Naijiria yoo ṣe ri itusilẹ gba lọwọ ẹgbẹ oṣelu APC.”

Aworan Asiwaju Bola inubu

Oríṣun àwòrán, others

Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni ọgbọn àti oyè jù PDP lọ - Tinubu

Saaju ni oludije ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti se apejuwe ẹgbẹ oselu rẹ, APC gẹgẹ bi ẹgbẹ to ni ọgbọn lori lati tu ọkọ ati lati peṣe ọna abayọ si gbogbo iṣoro orilẹede Naijiria.

Tinubu sọ eleyii ni ilu Abuja nigba ti wọn ṣe afihan awọn nkan ipolongo lati bẹrẹ ipolongo ile si ile, ti awọn adari ile aṣofin lati ariwa orilẹede yii gbe kale ni ọjọ Satide.

 O ni ẹgbẹ oselu APC ni agbara lati mu ilọsiwaju ba orilẹede Naijiria ati awọn araalu pẹlu.

“Ẹgbẹ oselu oni ilọsiwaju ni wa. A fẹ ẹkọ to yanranti fun awọn ọmọ wa, ilọsiwaju Naijiria lati bi nkan ọgbin ati awọn akanṣe isẹ ti yoo mu itẹsiwaju ba orilẹede Naijiria.

“O da wa loju, a ni nkan ti a le fi mu wa si imusẹ. A ti pinnu lati ṣe awọn nkan wọnyii.”

Oludije naa wa tẹsiwaju pe ẹgbẹ People’s Democratic Party ko ki n ṣe isoro fun APC ati pe ko yẹ ki awọn maa fi omijomitoro ọrọ pẹlu ẹgbẹ oselu naa.

“A wa ko ni maa ba wọn wijọ nitori a ni ọgbọn ori ju wọn lọ. A gbọn, a loye. A yatọ si wọn.

“Wọn ni ọdun mẹrindinlogun lati ṣejọba sugbọn wọn gbagbe gbogbo ohun to ye ki wọn ṣe fun awọn araalu''

O wa rọ ẹgbẹ oṣelu PDP lati tete gba pe awọn padanu eto idibo lọdun 2023.