Pásítọ̀ bá akọrin ìjọ, ọmọ ọdún mẹ́rìnlà sùn, ẹ̀jẹ̀ kò dá lẹ́yìn oṣù mọ́kànlá

Oríṣun àwòrán, Ogun state Police
Awọn isẹlẹ akanilaya to n waye lawọn inu ijọ Ọlọrun nipinl Ogun yii kọja sisọ.
Bii ọjọ mẹta la mu iroyin wa fun yin nipa olusọ agutan kan to fun ọmọ ijọ rẹ, ọmọ ọdun mejila loyun.
Amọ iroyin pasitọ miran tun ti jade nipinl Ogun yii kan naa, to ba ọmọ ọdun mẹrinla lopọ ninu ijọ rẹ bakan naa.
Igbe nibo ni aye yii wa n lọ, ni ọpọ eeyan n pariwo nitori wọn ni ti ẹni ta fẹyinti, ba fi ẹgun sọwọ, ki lo yẹ ka se?
Mama ọmọbinrin naa rinrin ajo ni pasitọ ti tan ọmọ rẹ wọ yara
Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun lo fi iroyin sọwọ fawọn akọroyin , to fi mọ ileesẹ BBC Yoruba, nipa olusọ aguntan kan to tun ba ọmọ lopọ.
Pasitọ naa, Israel Adebayo lo jẹ oludasilẹ ijọ The Beloved Chapel, eyi to wa ni adugbo Agbado nipinlẹ Ogun.
Pasitọ naa si lo ti jẹwọ fun awọn ọlọpaa pe lootọ ni oun ni ajọsepọ pẹlu ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹrinla naa, to jẹ ọmọ ẹgbẹ akọrin ijọ rẹ.
Adebayo, tii se ẹni ọdun mejidinlogoji, ni iya ọmọ naa salaye fawọn ọlọpaa pe o tan ọmọ oun wọnu yara, to si fi tipa ba lopọ.
Iya ọmọ naa lo ni oun rinrin ajo lọ sibi kan ni, lati lọ tọju ara ara oun nitori aisan kan to n ba oun finra, lasiko ti isẹlẹ naa waye.
Ko tiẹ ye mi bi mo se fipa ba ọmọ ọdun mrinla lopọ - Pasitọ
Nigba to n salaye bi ọrọ naa se jẹ, Pasitọ Israel Adebayo ni bi isẹlẹ se waye ko ye oun rara amọ lootọ ni ajọsepọ waye laarin oun ati ọmọ ọdun mẹrinla naa.
Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi ni se ni pasitọ naa n bẹbẹ fun idarijin lasiko ti wọn n fi ọrọ wa lẹnu wo.
Oyeyemi ni pasitọ naa ni oun ati idile ọmọbinrin naa sunmọ ara wọn pẹkipẹki amọ ko ye ohun idi ti iru iwa bẹẹ se waye.
‘Iya ọmọdebinrin yii ko fẹ ka gbe pasitọ nitori ko fẹ sẹ ẹ amọ ẹjẹ to n da loju ara ọmọdebinrin ko se pa mọra’
Agbẹnusọ ọlọpaa ni awọn ko ba ti gbe olusọ aguntan naa si ahamọ tipẹ tipẹ amọ iya ọmọdebinrin naa lo n se idiwọ nitori pe ko fẹ sẹ pasitọ rẹ.
“Amọ nigba ti ọmọbinrin yii n da ẹjẹ loju ara lemọ lemọ lati igba ti isẹlẹ naa ti waye losu kẹwa ọdun 2021, ni iya rẹ to gba wa laaye lati mu pasitọ naa eyi to fẹ to ọdun kan.
Ọmọbinrin naa sọ fun wa pe Pasitọ ni ọkunrin akọkọ ti yoo kọkọ ba oun ni ajọsepọ ri, ta si ti gbe ọmọdebinrin naa lọ sile iwosan nibi to ti n gba itọju.
‘Obi to ba dọwọ bo ọdaran to fipa ba ọmọ rẹ lopọ gan le jẹbi ẹsun lilẹ idi apo pọ mọ ọdaran lati huwa ibi’
Nibayii, Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Lanre bankọle ti pasẹ pe ki wọn gbe ẹjọ Pasitọ naa lọ si ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileesẹ ọlọpaa fun iwadii to yẹ.
Bankọle wa kilọgidi fawọn obi lati ye da ọwọ bo ẹnikẹni to ba fipa bawọn ọm wọn obinrin lopọ lai wo bi wn se sun mọ onitọun si.
Ọga ọlọpaa nipinl Ogun ni irufẹ awn obi bẹẹ gan le jẹbi ẹsun lilẹdi apo pọ mawn ọdaran naa lati huw aibi yii sawn ọmọde.
Ọwọ́ tẹ àgbẹ̀ tó fi ipá bá abarapá lòpò tipátipá nínú oko

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ileeṣẹ ọlọpaa ti gbe ọkunrin agbẹ ẹni ọdun mejilelogoji lọ si ile ẹjọ fun ẹsun ifipabanilopọ.
Arakunrin Gboyega Awoyinka naa ni wọn fi si ẹwọn fun ẹsun fifi ipa ba obinrin aparapa, Rhoda Adeboye lopọ ninu oko koko.
Agbegbe Kajola ni Ojurin, ilu Ọrẹ, ni ijọba ibilẹ Odigbo, ni ipinlẹ Ondo.
Amọ lasiko ti afẹsunkan naa n sọrọ ni ileẹjọ lo ni wi pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.
Ọlọpaa to gbe afurasi naa lọ si ileẹjọ, Inspector Jimmy Amuda rọ ileẹjọ lati fun oun ni aaye ki wọn gbe ẹjọ naa lọ si ọfisi to n gbọ ẹjọ awọn araalu, Director of Public Prosecutions (DPP) lori ọna lati tẹsiwaju lori igbẹjọ naa.
Adajọ Magisireti B.A.Ikusika ti fi ẹni ti wọn fẹsun kan naa si ẹwọn ni ilu Okitipupa titi ti Ajọ DPP naa yoo fi fi imọran wọn lori igbẹjọ naa lede.
Magsireti naa ti sun igbẹjọ di Ọgbọnjọ, Osu Kẹsan an ,ọdun 2022.












