"Arọ kan dìde rìn, nígbà tí à ń lé wèrè kúrò nílùú"

Oríṣun àwòrán, Entraco
Ọrọ di awada kẹri-kẹri, a fi bi ere ori itaga nigba ti ‘arọ’ dide rin, ti were si ri iwosan, lasiko ti awọn oṣiṣẹ ajọ to n mojuto ayika nipinlẹ Imo yawọ igboro.
Laipẹ yii ni ijọba ipinlẹ naa bẹrẹ si ni ko awọn were kuro ni aarin ilu, paapaa nilu Owerii, to jẹ olu ilu ipinlẹ naa.
Oludari ajọ ọrọ ayika, Nkem Frank Nzenwodo, sọ fun BBC pe ọpọlọpọ eeyan ti awọn ro pe were ni nigboro ilu Owerri, ni kii ṣe alarun ọpọlọ rara.
O ni pupọ ninu awọn eeyan ọhun lo ti ẹ tun ṣe bi arọ ati afọju, amọ to jẹ pe ko si nkankan to sẹ wọn ni agọ ara.
“Eyi to ti ẹ ya mi lẹnu ni ti were kan ti a fẹ gbe. Ṣugbọn ba ṣe n gbiyanju lati gbe, ni ẹni kan to jẹ arọ to wa lori kẹkẹ dide pẹlu ẹsẹ rẹ mejeeji, to si gbiyanju lati salọ.
“Igba yẹn ni mo ro o pe, ah! Nkan n ṣẹlẹ laye.”

Oríṣun àwòrán, Entraco
Ọgbẹni Nzenwodo tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe, iwadii ajọ naa fihan pe ọpọlọpọ awọn eeyan ti araalu ro pe were ni wọn, lo jẹ adigunjale nilu Owerri.
O ni awọn ba ibọn ati baagi ogun oloro lọwọ awọn eeyan naa nigba ti awọn n le wọ̀n.
Bakan naa lo sọ pe diẹ lara awọn eeyan naa to juwe ilu ti wọn ti wa ni awọn ti pe ẹbi wọn lati wa a mu wọn.
















