Ọmọọba àná mẹ́ta ya bo ààfin Awó láti fi àdá àti òògùn rọ ọba tuntun lóyé

Oríṣun àwòrán, Alawo of Awo
Se ni ọrọ da bi ere ori itage nigba ti awọn eeyan mẹta kan ya bo aafin Aláwó tìlú Awó, pẹlu ada ati oogun ibilẹ lati yọ ọba tuntun loye.
Awọn eeyan mẹtẹẹta naa ni wọn lo jẹ ọọmọọba to gbesẹ nilu ọhun, ti wọn si fẹ fi tipa rọ ọba tuntun to jẹ lẹyin baba wọn loye.
Orukọ Alawo tuntun naa ni Oba Abdulrasaq Adegboye, ẹni to gori itẹ lọjọ kẹtala osu Kẹsan ọdun 2021, eyiun ọdun kan sẹyin.
Orukọ awọn afurasi adaluru naa ni Adebayo Akinsilo, tii se ẹni ogoji ọdun, nigba ti ẹnikeji jẹ Oloyede Babatunde, to jẹ ẹni ọdun mrindinlọgọta.
Ẹnikẹta ti wọn fi ẹsun idaluru kan ni Oloyede Habib, tii se ẹni ọdun mejidinlọgbọn.
Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlgbọn osu Kẹjọ ọdun 2022 yii si ni isẹlẹ ikọlu si aafin Alawo naa waye.
Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti wa wọ awọn eeyan naa l sile ẹjọ lori isẹlẹ yii.
Awọn afurasi yii ti kọkọ dunkooko lori redio kan pe ki n kuro nipo, ere ni mo kọkọ pe isẹlẹ naa - Alawo
Alawo ti ìlú Awo, Oba Abdulrasaq Adegboye ti wa ṣàlàyé bí àwọn afurasi jàǹdùkú naa ṣe ya wọ ààfin rẹ.
O ni wọn wa pẹ̀lú òògùn ibilẹ àti àwọn nǹkan ìjà ogun láti gba àkóso ìlú náà ní ọwọ́ oun ni.
Nígbà tí BBC News Yorùbá kàn sí Ọba Adegboye, Kábíèsí ṣàlàyé pé àwọn afurasí tí wọ́n wá ṣe ìkọlù sí ààfin, ti kọ́kọ́ gba iléeṣẹ́ rédíò kan lọ ní ìlú Osogbo.
Ọba Adegboye ní lórí rédíò náà ni wọ́n ti kọ́kọ́ ń dúnkokò mọ́ òun pé tí òun kò bá kúrò lórí oyè, àwọn máa da ìlú rú mọ́ òun lórí lọ́jọ́ Ẹtì.
O ni wọn fi ẹsun kan oun pe oun ko lẹ́tọ̀ọ́ sí ori itẹ Alawo tí òun wà naa.
‘Wọ́n halẹ mọ mi pe n ko gbọdọ wa ki Jimọ ni Mọsalasi’
Ó ní wọ́n tún sọ wí pé òun kò gbọdọ̀ lọ sí mọ́ṣáláṣì láti lọ kí ìrun Jímọ̀ bíbẹ́ẹ̀kọ́ àwọn ma wá da ìlú rú mọ́ òun lórí.
Ó ní irọ́ ni òun kọ́kọ́ pè é idunkooko yii àfi bó ṣe di ọjọ́ Ẹtì, tí òun rí àwọn ènìyàn bíi méje tó kó kùmọ̀, òògùn àti àdá, tí wọ́n ya wá sí ààfin.
Kábíyèsí ní èyí ló jẹ́ ki òun pe àwọn agbófinró láti fi òfin gbé wọn, tí wọ́n sì fojú ba ilé ẹjọ́.
"Tí mo bá jẹ́ kí àwọn ará ìlú ya bò wọ́n nígbà tí wọ́n wá, orúkọ ọba náà ni wọ́n ma ma pa, ni mo ṣe pe àwọn ọlọ́pàá láti fi ọwọ́ ìjọba tọ̀ ọ́."
"Ìjọba ti ń bá wa ti ọwọ́ òfin bọ̀ ọ́, gbogbo àwọn jàǹdùkú tí wọ́n ń da ìlú rú ti ń kawọ́ rojọ́ lọ́dọ̀ ìjọba."

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
‘Wọ́n fẹ́ kí àna wọn jọba, ni àwọn ọmọọba àná ṣe kó àdá àti òògùn wá ká mi mọ́ ààfin’
Ọba Adegboye tún tẹ̀síwájú wí pé, àwọn ọmọ Ọba àná to gbèsẹ̀, tí òun fi dé àpèrè àwọn babańlá òun, ló kó àwọn jàǹdùkú láti wá ṣe ìkọlù sí ààfin oun.
O ni nítorí wí pé wọ́n fẹ́ kí àna wọn jẹ ọba, ni wọn fi gbe igbesẹ naa.
Alawo ní mẹ́ta lára àwọn méje to wá ṣe ìkọlù náà ló jẹ́ ọmọ ọba àná, tí wọ́n ń fi apá jánú lórí ìyànsípò òun.
Ọba náà fi kun pé, àwọn mẹ́jọ ni àwọn ọlọ́pàá nawọ́ gán lori isẹlẹ naa.
Sùgbọ́n nígbà tí ẹ̀bẹ̀ pọ̀ látọ̀dọ̀ àwọn àgbààgbà àti èèkàn ìlú, ni òun ní kí wọ́n fi àwọn márùn-ún sílẹ̀ nínú wọn.
Ìpàdé ń lọ lọ́wọ́ láti mọ ìgbésẹ̀ tó kàn
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ wí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí wọ́n wà ṣe ìkọlù sí ààfin náà hu ìwà tí kò tọ́, síbẹ̀ ọmọ ìlú náà ni wọ́n.
Ọba Adegboye ní ìpàdé tí ń lọ lọ́wọ́ láti ri wí pé àwọn afurasí náà tọwọ́ bọ ìwé láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, àwọn kò ní dán irú aṣọ irú bẹ̀ẹ̀ ṣorò mọ́.
Àti pé gbogbo àwọn ẹjọ́ lórí wí pé bàbá àwọn tó gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí oyè ló kọ́ ààfin èyí tó wà ní ilé ẹjọ́ àti àwọn nnkan mìíràn, ni wọ́n wọ́gilé.
Alawo fikun pe ní kété tí wọ́n bá ti ṣe èyí, ní ó ṣeéṣe kí àwọn tú wọn sílẹ̀ láti máa bá ìgbésí ayé wọn lọ tàbí gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ lórí ọ̀rọ̀ wọn.
Bákan náà ló ní òun kò ní kí wọ́n má fi ẹ̀dùn ọkàn wọn hàn ṣùgbọ́n kí wọ́n ṣe é lọ́nà ẹ̀tọ́ nípa lílọ sí ilé ẹjọ́ láti fi ẹ̀hónú wọn hàn.
Àwọn ọ̀daràn gbà á ní àwọn tó lọ ṣe ìkọlù sí ààfin Alawo hù - Oluwo
Oluwo tí ìlú Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi Telu Kinni, naa tí bù ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn kan ṣe lọ ṣe ìkọlù sí ààfin Alawo ti ìlú Awo.
Ọba Akanbi ní ìwà náà burú jáì nítorí lásìkò yìí, ìjọba ló ń fi ọba jẹ.
O ni tí ẹnikẹ́ni bá sì ní ìkùnsínú nípa ìyànsípò ọba kan, ọ̀dọ́ ìjọba ló yẹ kí ẹni náà ti lọ ṣe ìfẹ̀hónúhàn.
Oluwo ní ìwà tí àwọn tó lọ yabo ààfin Alawo náà hù èyí tó lòdì sí òfin, ló yẹ kí gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú rẹ̀ fojú winá òfin.
Ó fi kun pé gbogbo àwọn tó bá du ipò ọba gbọ́dọ̀ gbà wí pé ẹnikẹ́ni tó bá ti já mọ́ lọ́wọ́ ní Ọlọ́run yàn.
O si woye pe se lo yẹ kí gbogbo wọn gbárùkù tì ọba tuntun naa láti lè jẹ́ kó rí ìjọba rẹ ṣe.
Adajọ ti gba beeli awọn afurasi mẹtẹẹta naa pẹlu miliọnu meji naira ẹnikọọkan
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun ti wa wọ́ àwọn mẹẹta naa lọ sí ilé ẹjọ́ Májísíréètì ìlú Osogbo.
Ẹ̀sùn ṣíṣe ìkọlù sí ààfin Alawo ti ìlú Awo, Ọba Abdulrazaq Adegboyega si ni wọn fi kan wọn.
Olùpejọ́ fún iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, John Idoko sọ fún ilé ẹjọ́ wí pé ìwà tí àwọn afurasí náà hù lòdì sí òfin ìpínlẹ Osun.
Àwọn afurasí náà ti ní àwọn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn.
Ẹ̀wẹ̀, Adájọ́ Adeyemoye Adeyeba gba béèlì àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pẹ̀lú mílíọ̀nù méjì náírà ẹnìkọ̀ọ̀kan.
Adájọ́ Adeyeba wá sún ìgbẹ́jọ́ síwájú ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹwàá ọdun 2022.

















