Ọ̀fọ̀ ńlá tún ṣẹ̀ lágbo tíátà, àgbà òṣèré, Okemesi jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Instagram
Gbajugbaja adẹrinpoṣonu, Bamidele Tope Saint, ti ọpọ mọ si Okemesi ti jade laye.
Okemesi ni a gbọ pe o jade laye ni ile iwosan ni ọjọ Isẹgun, ọjọ Kẹrinlelogun oṣu Keji ọdun 2026 ni dede ago mejila ku isẹju mẹwaa.
Agba oṣere naa papoda lẹyin to lo wakati diẹ ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun ni ile iwosan.
Nigba to n kede iku rẹ loju opo Instagram, Tony Montana Jeff, ti oun naa jẹ agba oṣere ni awọn ti gbe oku naa lọ si ile igbe oku si.
"Pẹlu ibanujẹ ọkan, mo n kede fun aye pe Okemesi ti jade laye. Dokita kede iku rẹ ni deede aho mejila ku isẹju mẹwaa ni owurọ yii, Ọjọ kẹrinlelogun oṣu keji ọdun 2026. Okemesi ti lọ o
"A ti gbe oku rẹ lọ si ile igbe oku si. Mo ma a ba yin sọrọ lori eto isinku rẹ to bay a.
"A dupẹ lọwọ gbogbo awọn to dide iranlọwọ fun Okemesi. Ki Ọlọrun b awa tẹ Okemesi si afẹfẹ rere, ko si tun forijin." Tony Montana sọ.
Bakan naa ni Tony Montana tun rọ awọn eeyan ati ololufẹ Okemesi pe ki wọn ma fi owo ranṣe si apo owo ti wọn gbe sita fun iranlọwọ.
"Ẹ jẹ ki n fi asiko yii sọ fun yin, ẹ ma fi owo ransẹ si apo owo ti a gbe sita mọ. Okemesi ti ku.
"A o lọ fi opin si apo owo naa nitori a mọ pe fidio ti a n ṣe yii le ma de si ọdọ ọpọ awọn eeyan."
Ki lo ti sẹlẹ ṣaaju?
Okemesi gbe fidio kan sita saaju lati ṣo bi aisan naa ]se n ba finra, to n beere fun iranlọwọ awọn eeyan.
O ni oun n gba itọju ni ile iwosan kan nipinlẹ Eko, ko to di pe wọn gbe lọ si ilu Osogbo nipinlẹ Osun, nibi to ni wọn ti n fi adura jagun fun un.
























