Iná ṣẹ́yọ ní pápákọ̀ òkúrufú ìlú Eko, òṣìṣẹ́ FAAN dèrò ilé ìwòsàn

Oríṣun àwòrán, FAAN
Ajọ to n ri si irinajo oju ofurufu ni Naijiria, (FAAN) ti kede pe gbogbo nnkan ti pada bọ sipo bayii lẹyin ina to ṣẹyọ ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed, niluu Eko.
Ṣaaju ni awọn fidio kan ṣafihan eefin to n ru lagbegbe Terminal One ni papakọ ofurufu naa lalẹ ọjọ Aje.
Adari ajọ FAAN, Olubunmi Kuku, sọ pe iwadii awọn fi han pe isalẹ Terminal One ọhun ni ina naa ti kọkọ bẹrẹ ko to jo de oke.
Kuku sọ pe awọn eeyan kan farapaa ninu iṣẹlẹ ọhun amọ ẹmi ẹnikẹni ko ba a lọ.
Ṣaaju ni FAAN ti kọkọ kede pe ina kan ṣẹyọ ni papakọ ofufuru naa.
Ninu atẹjade loju opo X rẹ, ajọ ọhun sọ pe oun lo ẹrọ 'crane' lati ṣiṣẹ idoola ẹmi lori oke tente 'Control Tower' papakọ ofurufu naa.
Latari igbiyanju wọn, gbogbo oṣisẹ mẹrinla to ha sori oke tente naa ni wọn doola.
O ni "Apapọ eeyan mẹfa - ọkunrin mẹta ati obinrin mẹta - ni ọrọ naa kan gbọngbọn amọ ara wọn ti balẹ.
"Ẹnikan to farapa ni a ti gbe lọ si ile iwosan olu ọọfisi FAAN fun ayẹwo, ara rẹ si ti n balẹ bayii."
Bi ina naa ṣe bẹrẹ
Ileeṣẹ panapa ipinẹ Eko sọ pe inu yara ayelujara papakọ ofurufu naa ni ina ọhun ti bẹrẹ ki wọn to kapa rẹ.
Ninu atẹjade kan ti adari ileeṣẹ ọhun, Margaret Adeseye buwọlu, o ni yara naa to wa ni orulẹ kẹta ile naa ni ina ọhun ti bẹrẹ.
Iṣẹlẹ naa ṣakoba fun lilọ bibọ ọkọ ofurufu.
Lara awọn ti iṣẹlẹ naa pa lara ni ileeṣẹ Air Peace to kede fun awọn onibra rẹ pe atunṣe yoo waye si awọn irinajo kan.
Lọdun to kọja ni minisita irinajo ọkọ ofurufu, Festus Keyamo kede pe ijọba fẹ ṣe atunṣe agbegbe Terminal One naa pẹlu owo ti iye rẹ to ₦712bn.
Amọ ọpọ araalu lo bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa pe kii ṣe asiko ti ọpọ araalu ko ri ounjẹ jẹ lo yẹ ki ijọba maa na obititi owo fun atunṣe papakọ ofurufu.
Amọ Keyamo fesi pada pe atunṣe ọhun ṣe pataki lasiko yii, bi bẹẹ kọ, ọpọ awọn ileeṣẹ ọkọ ofurufu ilẹ okeere ni yoo fi Naijiria silẹ lọ ilẹ mii ti papakọ ofurufu wọn jọju.


























