Ẹ san N100m ní kíákíá tàbí ká kọ lùyín- Àwọn agbébọn kọ lẹ́tà si aráàlú

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn agbebọn ni apa guusU ipinlẹ Kebbi ti beere fun ọgọrun un milọnu naira lati ọwọ awọn olugbe agbegbe Ngaski, ti wọn si n leri pe awọn yoo kọlu ilu ti wọn ko ba san owo naa.

Ibeere yii lo wa ninu lẹta kan ti awọn agbebọn fi ransẹ si awọn araalu.

Idunkoko yii waye lasiko ti eto aabọ mẹhẹ ni awọn agbegbe kan nipinlẹ Kebbi, ti awọn agbebọn si n kọlu ọpọ agbegbe.

Ninu lẹta ti Daily Trust gbe sita, awọn agbebọn kilọ fun awọn araalu pe ki wọn ma fi ọwọ kekere mu ohun ti wọn ki wọn ṣe.

"Eyi ki n ṣe awada. Ẹ gbọdọ san N100m. Ti ẹ ba kọ, ẹ o kan idin ninu iyọ, ti ẹ si da ara yin ni ẹbi. Koda ti ẹ ba pe sọja, wọn ko le da wa duro," lẹta naa ṣalaye.

Ikọ agbebọn tun ni ki awọn araalu ma gbagbe ohun to waye ni ilu Woro nijọba ibilẹ Kaiama nipinlẹ Kwara, nibi ti ọpọ eeyan ti padanu ẹmi wọn lẹyin ti wọn gba ikilọ lọwọ awọn agbebọn.

Awọn araalu lo n gbe pẹlu inu fu aya fu lasiko yii.

Olugbe agbegbe, Abbas Alkali, ni , "Bẹẹni, wọn kọ lẹta si wab ere fun ọgọrun milọnu naira lọwọ ilu.

"Gbogbo wa ni a n gbe pẹlu ibẹru bayii nitori idunkoko awọn agbebọn pe ki a san owo.

"A ti fi ọrọ naa to alaga ijọba ibilẹ leti, t imo si gbọ ope ijọba ipinlẹ ati awọn ẹsọ alabo naa ti gbọ si lẹta naa, ti wọn si ti n gbe igbesẹ.

"A ko fẹ fi nnkan silẹ. A mọ pe wọn le wa bi wọn ṣe ti ṣe ileri. Awọn eeyan kan ti kuro ni ilu lati lọ si ibo miiran ti aabo wa ṣugbọn a wa kan wa , ti a ko ni ibikibi lati lọ, a n gbadura pe ki aabo Ọlọrun wa lori wa," o sọ.

Malam Sa'ad Suleiman, talọ ni ilu naa sọ pe inu ibẹru boju ni ọpọ awọn olugbe ilu naa wa bayii.

"Ki ṣe pe wọn kọ lẹta si alufaa kankan; wọn kọ si gbogbo ilu ni. O se ni laanu pe eyi n waye lasiko oṣu Ramadan.

"Ki ijọba pe se aabo fun wa nitori wọn le ṣe ikọlu niigbakugba, " o sọ.

Ki ni ijọba sọrọ lori lẹta naa?

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Kebbi, Ahmed Idris sọ pe ijọba ti n gbe igbesẹ lati ri pe ikọlu ko waye rara.

"Mo ṣẹsẹ ba olori ajọ eleto aabo sọrọ, o fidi iroyin naa mulẹ, to si ni awọn ẹsọ alabo ti w ani agbegbe lati pese aabo fun awọn araalu, o ṣalaye.

O fikun pe ijọba ko fi ọwọ kekere mu ọrọ yii rara.

"Ijọba, pẹlu ajọsepọ awọn ẹsọ alabo, ti gbe awọn ọmọ ogun lọ si agbegbe naa.

"O da mi loju pe ẹ mọ ijọba ipinlẹ yii ko ki n fi ọrọ nipa eto aabo ṣere. Ọlọlajulọ mu ọrọ yii tọkantọkan, ti yoo si ri daju pe eyi ko waye," o sọ.