Òní ni ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ FCT yóò wáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oni ọjọ kọkanlelogun, oṣu Keji, ọdun 2026 ni eto idibo ẹkun mẹfẹfa to wa niluu Abuja yoo waye.
Awọn araalu yoo dibo ni Abaji, Abuja Municipal, Bwari, Gwagwalada, Kuje, ati Kwali lati yan awọn alaga ibilẹ mẹfa atawọn kansẹlọ mejilelọgọta kaakiri olu ilu Naijiria.
Eto idibo naa ni akọkọ iru rẹ ti yoo waye lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubu buwọlu atunṣe ofin eto idibo ti ọdun 2022 lọjọ mẹta sẹyin.
Ofin naa sọ pe wọn gbọdọ fi gbogbo esi ibo ranṣẹ si olu ọọfisi ajọ INEC lati ori ayelujara.
Wọn ni eyii yoo fun awọn araalu lanfani lati maa wo bi esi ibo naa ṣe n wọle lori ayelujara ni ibikibi ti wọn ba wa.
Amọ awọn araalu kan ti tako atunṣe ofin ọhun pe magomago le waye lasiko tabi lawọn ibi ti ẹrọ ayelujara ko ti ṣiṣẹ tabi ja fafa.
Wọn ṣo pe awọn oloṣelu yoo lo anfani naa lati ṣe makaruru lori esi ibo ọhun.
Ẹwẹ, ajọ INEC ni o le ni miliọnu kan abọ ọmọ Naijiria to ti gba kaadi eto idibo, PVC, wọn ni FCT.
INEC ni "awọn ti wọn ni kaadi idibo ti wọn si forukọlsilẹ lati dibo nikan ni yoo lanfani lati kopa ninu eto idibo naa."
Eto idibo yii ni yoo jẹ ekeji iru rẹ ti wọn yoo ṣe labẹ alaga ajọ INEC tuntun, Joash Amupitan.
Awọn onimọ nipa oṣelu Naijiria sọ pe eto idibo naa ni yoo sọ bi ẹgbẹ oṣelu APC ṣe lẹnu to ni FCT.
Wọn sọ pe eto idibo ọhun tun le ṣapejuwe bi awọn araalu yoo ṣe tẹwọgba Aarẹ Tinubu ninu igbiyanju rẹ lati de ipo Aarẹ lẹẹkeji lọdun 2027.


























