Wo àwọn olóṣèlú tí ìjọba Tinubu ti fẹ̀sùn kíkó owó Naijiria sápò kan

Oríṣun àwòrán, Abubakar Malami/El-Rufai/ Sule Lamido/ Aminu Tambuwal/X/Facebook
Ki I ṣe tuntun lagbo oṣelu Naijiria lati maa wadii awọn oloṣẹlu ti wọn ba fura si pe wọn ko owo ilu sapo ara wọn lasiko ti wọn di ipo kan tabi ikeji mu.
Nigba mi-in, igba ti awọn oloṣelu naa ba ṣi wa nipo ni wọn maa n fi ẹsun kan wọn, ti wọn yoo si tọpinpin wọn.
Ṣugbọn lọpọ igba, wọn ti maa n kuro lọfiisi ki wọn too maa wadii ohun ti wọn fi ipo wọn ṣe labala owo ilu.
Latigba ti ijọba Aarẹ Bola Tinubu yii ti bẹrẹ ni iwadii awọn oloṣelu bẹẹ ti n waye, to bẹẹ ti awọn oloṣelu ẹgbẹ alatako n sọ pe APC n mọ-ọn-mọ lo ọwọ agbara lori awon ni.
BBC ṣagbeyẹwo awọn oloṣelu ti ijọba Tinubu ti fi ẹsun ajẹbanu kan latigba ti Aarẹ Tinubu ti gbajọba.
- Abubakar Malami
Abubakar Malami; Olootu ati minisita eto idajọ nigba ijọba Aarẹ Oloogbe Muhamaadu Buhari, n jẹjọ lọwọ bayii lori kiko owo Naijiria sapo ara ẹni.
Ajọ EFCC to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu mọkumọku lo n ba Malami fa a pẹlu ẹsun mẹrindinlogun (16) ti wọn fi kan an.
Wọn fẹsun kan ọmọ rẹ ọkunrin ati iyawo rẹ pẹlu, dukia to le ni N8.7 billion ni wọn ni wọn fi owo Naijiria ko jọ.
Amọ Malami ni oun ko jẹbi awọn ẹsun naa, o ni ijọba Tinubu wulẹ n lo agbara le oun lori ni.
- Aminu Waziri Tambuwal
Loṣu Kẹjọ ọdun 2025, EFCC ranṣẹ pe gomina ipinlẹ Sokoto nigba kan, Aminu Tambuwal, wọn ni ko waa ṣalaye lori N189 billion owo Naijiria ti wọn lo ko sapo ara rẹ lasiko to ṣejọba
EFCC fẹsun kan pe o gba owo naa lasiko to wa nipo gomina, awọn atọpinpin si fidi rẹ mulẹ pe eyi lodi sofin.
- Nasir El-Rufai
Latigba ti Nasir El-Rufai ti kuro nipo gomina ipinlẹ Kaduna ni 2023, to si tun kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC lo ti n koju ẹsun ajẹbanu lati ọdọ ijọba to de lẹyin rẹ.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ko fọwọ ofin mu un, ti wọn ko si pe e lẹjọ, sibẹ, ẹnu ko sin El-Rufai nipa ajẹbanu .
Bi eyi ṣe n lọ lọwọ naa ni El Rufai paapaa ko yee fẹsun kan ijọba Tinubu, bẹẹ lo n tako ẹgbẹ APC to ti ṣejọba Kaduna fọdun mẹjọ.
Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu BBC, El-Rufai sọ pe loootọ ni wọn ko ti I fi ofin mu oun, amọ wọn ti mu awon to sun mọ oun.
El Rufai sọ pe oun mọ pe won le mu oun naa laipẹ.
Ọjọbọ ọsẹ yii ni awọn agbofinro kan si gbiyanju lati mu un ni papakọ ofurufu l'Abuja loootọ, bo ṣe n sọkalẹ ninu baaluu to gbe e de lati Cairo, orilẹede Egypt.
Gomina Kaduna tẹlẹ naa ti wa fẹsun kan APC, o ni bi wọn ṣe n mu awọn oloṣelu to jẹ ọmọ ẹgbẹ alatako lo jẹ kawọn eeyan maa fi ẹgbẹ naa silẹ.
- Sule Lamido
Gomina ipinlẹ Jigawa nigba kan ri ni Sule Lamido, ọpọ igbẹjọ lo si ti koju lati ọdọ EFCC lori N1.3 billion ti wọn lo ko sapo ara rẹ, pẹlu awọn ẹsun miran to n jẹjọ rẹ lati 2015.
Wọn ti figba kan ju u si ahamọ pẹlu ọmọ rẹ; Aminu Mustapha.
Ẹsun kiko owo Jigawa jẹ nipasẹ awọn ileeṣẹ mọlẹbi rẹ wa ninu ohun ti Sule Lamido n jẹjọ rẹ.
Ni 2012, EFCC mu ọmọ Lamido, Aminu Sule, wọn ni o fẹ ko owo ilu to ji sa lọ silẹ okeere.
Ninu awijare Sule Lamido to jẹ olori ninu PDP, o ni ijọba APC fi ẹtẹ silẹ wọn n pa lapalapa.
Lamido sọ pe APC ko dojukọ igbogunti ajẹbanu mọ, wọn doju kọ PDP to ṣejọba fọdun mẹrindinlogun.
Awọn ọmọ ẹgbẹ APC to n koju iwadii
- Yahaya Bello
Lọwọlọwọ, EFCC n ba gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ, Yahaya Bello, ṣe ẹjọ lori 80.2 billion naira ti wọn lo ko jẹ.
Ni 2024 ni ajọ naa yabo ile Yahaya Bello to ṣejọba Kog fun ọdun mẹjọ gbako, wọn fẹ fọwọ ofin mu un.
Amọ iroyin sọ pe Usman Ododo, gomina to gba ipo lọwọ Yahaya Bello, wa ọna to fi gbe Bello jade, ti EFCC ko si pada ri i mu.
Bello pada foju han ni kootu nipari ọdun 2024, wọn si ti I mọ ahamọ fungba diẹ lai fi aaye beeli silẹ fun un.
Loṣu Kin-in-ni ọdun 2026 yii, Alaga EFCC, Ola Olukoyede, sọ pe ẹjọ naa ṣi wa ni kootu, awọn si n ṣiṣẹ lati ri i pe awọn ridi okodoro.
- Hadi Sirika
Hadi Sirika ni minisita eto irinna ofurufu nigba ijọba Oloogbe Muhammadu Buhari.
Ileeṣẹ Nigeria Air ti Sirika fi lọlẹ nigba ti saa rẹ n tan lọ lo pada di ariwo mọ ọn lọwọ.
Awuyewuye naa lo si mu ijọba Tinubu fagile akanṣe iṣe to fẹ da ileeṣẹ ọhun silẹ.
EFCC ti wa pe Sirika lẹjọ lori idasilẹ ileeṣẹ to jẹ ijọba Naijiria lo ni in.
Ẹjọ ọhun ṣi wa ni kootu.


























