Báǹkì àgbà Naijiria ṣòfin ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà fún ẹni tó bá fi owó ṣe òdòdó ìfẹ́

Aworan owo Naijiria ti wọn to pọ bii ododo ifẹ

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Bi ayajọ Ololufẹ ti a mọ si Falẹntain ṣe n sunmọ, Banki agba ilẹ Naijiria (CBN) ti fi ofin de awọn eeyan lati ma ṣe fi owo naira ṣe ododo ifẹ (Money bouquet) ti wọn fi n ṣe ẹbun mọ.

Bi ẹnikẹni ba tasẹ agẹrẹ si ofin yii bi CNB ṣe wi, ẹwọn oṣu mẹfa ni tọhun yoo fi gbara.

Iroyin to gba ori ayelujara l'Ọjọbọ naa ṣalaye, pe ijiya to wa fun awọn to ba tabuku owo naira nipa nina a loju agbo, naa lo wa fun ẹni to ba n fi owo ṣe ododo ifẹ lati fi tọrẹ fun ololufẹ rẹ.

Bakan naa ni wọn fi kun un pe fifi owo ṣe ododo ifẹ tumọ si fifi abuku kan naira, ẹsun kan naa si ni pẹlu ẹni to ba rún owo, to ta a fun ẹlomi-in ati ẹni to kọ nnkan si i lara yoo jẹjọ rẹ.

Labẹ ofin Banki agba ilẹ Naijiria, ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ pe o n ṣe owo naira bi ko ṣe yẹ yoo ṣẹwọn oṣu mẹfa, o kere tan, tabi ko san ẹgbẹrun lọna aadọta naira (₦50,000) owo itanran.

CBN rọ awọn ọmọ Naijiria lati da aabo to peye bo owo naira nibi gbogbo, ki wọn si fi ẹjọ ẹni to ba n fi abuku kan owo naa sun, ki iya to tọ le jẹ awọn arufin .

Tẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni Banki agba orilẹede Kenya naa fi ofin de fifi owo ṣe ẹbun ododo ifẹ, ẹwọn ọdun meje ni wọn la kalẹ fun ẹni to ba tapa sofin naa.

Èrò aráàlú ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

Amọ latigba ti ofin naa ti jade ni ero araalu ti ṣọtọọtọ lorii rẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bawọn obinrin ṣe n sọ pe awọn ni ofin naa yoo pa lara ni awọn ọkunrin n sọ pe o kuku daa bẹẹ.

Awijare awọn obinrin to ti n gba owo gẹgẹ bii ododo ifẹ tẹlẹ ni pe awọn ko ṣẹṣẹ maa gba a lọwọ ololufẹ awọn.

Wọn ni lasiko ọjọọbi tabi ijade ifẹ lasan, ọkunrin gidi to ba fẹran obinrin rẹ yoo to owo jọ, yoo fi ṣe ẹbun ifẹ ti obinrin naa yoo mọ riri, ti yoo si fi ifẹ han si ọkunrin naa ju ti tẹlẹ lọ.

Bi Falẹntain ṣe waa ku ọjọ meji, tawọn si ti fọkan si ẹbun ododo olowo rẹpẹtẹ yii, wọn ni bii ẹni to sọ ireti awọn di ofo ni ofin ti CBN ṣe.

Ṣugbọn awọn ọkunrin ni tiwọn n sọ pe ko ṣẹṣẹ digba tawọn ba to owo rẹpẹtẹ pọ bii ẹbun kawọn too fifẹ han si obinrin ti ọkan awọn fẹ.

Wọn ni ko yẹ ki eeyan fi abuku kan Naira bi CBN ṣe sọ.

Awọn ọkunrin n sọ pe eeyan le ra fulawa tootọ ko fun ololufẹ ẹ lọjọ Falẹntain, o le ra ẹbun mi-in, o si le ko owo fun un ko fi ra ohun to ba wu u, dandan kọ ni ẹbun ifẹ alafowo ṣe jare.

Bẹẹ ni wọn ni ko si ofin to ni ọkunrin nikan ni ko ṣaa maa fun obinrin lẹbun, bi obinrin naa ba ṣe bẹẹ fọkunrin, ko buru.