Ajara wà láàrin wa báyìí, O ń wo ǹkan tí à ń ṣe.....Alfa Ibrahim to rọ́ wáàsí

Ọpọ awọn ọmọ egbẹ Tampan ni ko yọju sibi adura Firdau ọjọ mẹjọ ti wọn se fun aunty Ajara ni ọjọ Ẹti ni ilu Eko.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ẹbi, ara alabagbe pejọ lati ranti oloogbe naa, perete lara awọn akẹgbẹ rẹ ti wọn jẹ ẹgbẹ osere lo yọju sibi eto naa.
Nigba ti BBC Yoruba ba ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ osere yii sọrọ, o ni oun ko le sọ pato idi ti awon akẹgbẹ awọn ko se yọju, sugbọn oun gbagbọ pe ọpọ wọn wa lẹnu isẹ, to le ma fun wọn laaye lati wa nibẹ, ati pe, oun mọ pe, yoo wu ọpọ wọn lati wa ti aaye ba wa fun wọn lati se bẹẹ
Kini awọn Alaafaa sọ nibi adura ọjọ kéjọ yii?
Adura ọjọ kẹjo fun agba oṣere ti ọpọ n pe ni Aunty Ajara lo waye ni ilu Eko, lọjọ kejila, oṣu keji, odun 2026.
Aafa Ibrahim Walahiri to rọ waasi nibi adura naa sapejuwe Ajara bi onirele eniyan.
O ni pe ki onikaluku ṣọra fun iwa igberaga ati ọrọ buruku sisọ lẹnu.
O ni ki wọn ma sunkun mọ sugbọn ki wọn maa sadura fun un nitori pe Ajara n wo gbogbo nkan ti onikaluku n ṣe bayii.
Bakan naa lo sọ pe owo adura ti wọn n gba jẹ fun titọrọ fun Ajara.
Aafa Ibrahim ni ki onikaluku gbe ile aye ṣe oun rere bi Olorun se n fọrun kẹ Ajara.
O parọwa pe ki awọn eeyan da owo daadaa fi tọrọ fun Ajara ẹyin iku rẹ nitori pe ati eni kukuru ati ẹni giga ni Olorun ni iṣẹ to ran wọn si.

Oríṣun àwòrán, Others
Lónìí ni àdúà ọjọ́ mẹ́jọ fún Anti Ajara, òṣèré tíátà tó jáde láyé
Oni Ọjọbọ, ọjọ kejila, oṣu Keji ọdun 2026 ni eto adua ọjọ mẹjọ ti a mọ si Fidau yoo waye fun Oloogbe Ajara Morenikeji Lasisi, gbajumọ oṣere tiata to jade laye l'Ọjọbọ to kọja.
Oṣere ti ọpọ eeyan mọ si Anti Ajara naa jade laye lọjọ karun-un oṣu Keji ọdun 2026 yii, lẹyin aisan to ni I ṣe pẹlu ẹdọ, to si tun wa nipo iloyun lasiko ti ọlọjọ de naa.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn ololufẹ Anti Ajara ko tete mọ pupọ nipa rẹ lasiko to jade laye naa, atẹjade ti wọn fi kede adua ọjọ mẹjọ rẹ yii sọ diẹ nipa rẹ.
Gẹgẹ bi ikede naa ṣe wi, ọjọ kẹjọ, oṣu Keje ọdun 1999 ni wọn bi Oloogbe Ajara Morenikeji Lasisi.
Nigba ti yoo fi jade laye yii, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27) ni wọn ni Anti Ajara jẹ.

Oríṣun àwòrán, Others
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ ti Anti Ajara ku naa ni wọn sin in nilana ẹsin Islam.
Nipa ibi ti isinku naa yoo ti waye, ojule kẹrin, opopona Terry Grillo, Beckely Estate, Abule Egba nipinlẹ Eko ni wọn pe e.
Aago mẹrin irọlẹ ni wọn si fi eto ọhun si.
BBC News Yoruba yoo maa mu bi eto naa ba ṣe lọ wa fun yin.


























