Tani Nasir El-Rufai tí wọn mú sí akoto EFCC àti DSS báyìí?

Oríṣun àwòrán, Nasir El-Rufai
Mallam Nasir El-Rufai ni aye n pariwo rẹ lọwọlọwọ latari awọn nkan to sọ ni eyi ti o si ti ko si gbaga iwadii awọn ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ati ajọ to n gbogunti iwa ajẹbanu ni Naijiria, iyẹn EFCC lori ẹsun N432 biliọnu naira owo ilu.
Lasiko yii El-Rufai wa lara awọn eekan oloṣelu to jade lati ariwa Naijria to ti ṣe iṣẹ aladani ati tijoba.
Igba Ewe ati igba ọdọ El-Rufai...
Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji, ọdun 1960 ti Naijiria gba ominira ni a bii sile Mallam Ahmad Rufai ni Zaria nipinle Kaduna nibi tẹbi rẹ ti n gbe ni abule Daudawa nipinle Katsina.
El Rufai padanu baba rẹ lati kekere to si jẹ pe aburo baba rẹ lo tọ ọ dagba.
O lọ sileẹkọ Barewa College ati fasiti Ahmadu Bello ni Zaria to si kawe gboye jade ninu ẹkọ awon to n wọn ilẹ to si gba ipele kinin jade nibẹ.
O ṣe iṣẹ olukọ ni fasiiti naa lẹyin to kawe pari, o si gba oye imọ kun imọ ni MBA ni 1984 ko to tun lọ ka ẹkọ nipa imọ ofin ni London to ti gba oye LLB ni fasiti London lọdun 2008.
O tun gba oye ipele keji eto ẹkọ lati John F. Kennedy School of Government ni fasiti Havard lọdun 2009.
Nasir sinru ilu nilu Abeokuta lọdun 1982 ko to pada si Kaduna lọ da ile iṣe El-Rufai and Partners silẹ.
O bẹrẹ iṣẹ oṣelu ati iṣe ijọba nigba ti Ogagaun Abdulsalam Abubakar yan an gẹge bi ọmọ igbimo Policy Implementation and Monitoring Committee to n ri si ọrọ ara ilu lọdun 1999.
Aare Obasanjo Olusegun naa tun yan El-Rufai gẹgẹ bii Adari agba ajọ BPE to n ri si ọrọ bi wọn ṣe sọ idokowo daladani lọdun 2003 ti wọn si mojuto tita awọn nkan ini Naijiria fun aladani
Lọdun 2014 lo bori ninu idibo to si jade du ipo gomina Kaduna labẹ asia ẹgbẹ Oselu APC to fi wọle lọdun 2015.
Nigba to wa nipo gomina, o yan obinrin mẹfa sipo kọmiṣọnna ati awọn ọdọ sipo adari ile isẹ ijoba ipinle Kaduna.
El Rufai ni oye apọnle Naijiria ti wọn pe ni Commander of the Order of the Niger (CON)
Ìjọba àpapọ̀ gbé El-Rufai lọ ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn títi ọwọ́ bọ fóònù ọ̀gá àgbà àjọ NSA
Ijọba apapọ ti gbe gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ, Nasir El-Rufai lọ sile ẹjọ lori ẹsun pe o tọwọ bọ foonu ọga agba ajọ to n ri si eto abo Naijiria, (NSA), Nuhu Ribadu.
Lọṣe to kọja ni El-Rufai sọ ninu ifọrọwerọ kan pe oun atawọn kan tẹti si ọrọ ti Ribadu n sọ lori foonu rẹ lẹyin ti wọn tọwọ bọ foonu naa tan.
Bo tilẹ jẹ pe pe EL-Rufais sọ pe lasiko naa pe ohun ti oun ṣe ko ba ofin mu, o ni igbesẹ naa kii ṣe ohun tuntun.
Ninu iwe ipẹjọ rẹ to wa ninle ẹjọ bayii ni ijọba apapọ ti sọ pe Nasir El-Rufai tọwọ bọ foonu ajọ NSA.
Awọn ẹsu ti wọn fi kan El-Rufai
- Ẹsun kinni ni pe El-Rufai gba ọna ti ko ba ofin mu lati ti ọwọ bọ foonu Nuhu Ribadu, eyii to lodi si abala 12(1) ofin Naijiria ni ti wọn ṣe atunṣe rẹ lọdun 2024.
- Ẹsun keji ni pe El-Rufua sọ pe oun ṣiṣẹ pẹlu ẹnikan to tọwọ bọ foonu Nuhu Ribadu, eyii to lodi si abala 27(b) ti ofin ori ayelujara ti wọn ṣatunṣe rẹ lọdun 2024.
- Ẹsun kẹta ni pe Mallam Nasir El Rufai lo imọ ẹrọ lati ṣakoba fun araalu ati abo orilẹede Naijiria nipa bo ṣe tọwọ bọ foonu Ribadu, eyii to sọ funra ninu ifọrọwerọ kan lori ẹrọ amohunmaworan Arise lọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun 2026.

Oríṣun àwòrán, ijoba apapọ
Wayi o, ṣaaju ipẹjọ yii ni awọn ọtẹmuyẹ DSS ti kọkọ gbiyanju lati fi panpẹ ofin mu afurasi naa ni papakọ ofurufu amọ to kọ jalẹ lati jẹ ki wọn mu oun.
O sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC lẹyin igbiyannu naa pe niṣe ni ijọba Naijiria n dunkoko mọ oun, eyii ti ko yẹ ko ri bẹẹ labẹ ijọba awarawa.
Ìdí tí mo fi takú pé mi ò ní í tẹ̀le àwọn agbófinró tó fẹ́ mú mi rèé - El-Rufai

Oríṣun àwòrán, Others
Gomina ipinlẹ Kaduna tẹlẹ, Malam Nasir El-Rufia ti ni mimi kankan ko le mi oun tabi da oun duro lati maa tako ijọba Naijiria, eyi to ni o n fa ọpọ inira fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria lasiko yii.
Lọjọbọ, ọjọ kejila, oṣu Keji, ọdun 2026, awọn oṣiṣẹ alabo gbiyanju lati fi ofin mu gomina Kaduna tẹlẹ naa ni paapa ofurufu Nnamdi Azikiwe niluu Abuja, olu ilu orilẹede Naijiria, kete to de si orilẹede Naijiria lati Egypt.
Ninu ifọrọwerọ akọkọ to ṣe pẹlu BBC lẹyin iṣẹlẹ naa, Nasir El- Rufia salaye ohun to ṣalaye lasiko ti awọn agbofinro fẹ mu.
O ni rogbodiyan bẹ silẹ lasiko ti awọn agbofinro sọ fun pe ki oun tẹle wọn lọ si ọfisi wọn nitori wọn fẹ ri oun nibẹ, to si beere pe ki wọn fi lẹta ipe ti wọn mu wa ran oun ṣugbọn wọn ko ni lẹta ipe kankan.
"Bi mo ṣe n sọkalẹ lati inu baalu, ọdọmọkunrin kan wa ba mi pe oun wa lati DSS, ti wọn si fẹ ri mi agọ wọn. Mo sọ fun pe mo nilo iwe ipe, wọn ni awọn yoo fun mi ni iwe pe naa."
"Nigba ti a jade, awọn olori rẹ wa ba mi, ti wọn si sọ bakan naa. Mo fesi, 'Ti ẹ ba ti fun mi ni iwe ipe, ile mi sunmọ ọfisi yin, to ba jẹ ajọ DSS, mo ma lọ si ile mi. Ti ẹ ba ti ni iwe ipe, ẹ mu wa ba mi, ẹ kan le da mi duro ni paapa ofurufu pe ki n tẹle yin,"' El-Rufia ṣalaye.
O ṣapejuwe igbesẹ ajọ DSS gẹgẹ bii eyi to tako ofin ẹtọ ọmọniyan ninu ofin orilẹede Naijiria.
Gomina tẹlẹ naa ni ẹru ko bao un rara lasiko ti oun le awọn agbofin to fẹ mu danu.
O ni, "N ko bẹru nkankan yatọ si Ọlọrun, ati pe mo ti n ṣiṣẹ ninu ijọba fun ọpọ ọdun, mo n sọ fun ẹnikẹni to ba ni nnkan tako mi, tabi fun mi ni owo tabi pe ọna eru ni mo ko ọrọ jọ, ki wọn ja sita pe irọ ni mo n pa."
El-Rufai ni fun ọdun meji ati abọ bayii ni ajọ EFCC ati ICPC ti n ṣe iwadii lori iṣejọba, ti wọn ko si ti ri nkankan gbamu.
O fikun pe awọn oṣiṣẹ ijọba gbọdọ ṣiṣẹ daada, ki wọn si tẹle ofin ati ilana ti ofin la kalẹ ti wọn ba fẹ ṣe iwadii tabi fi iya jẹ ẹnikẹni ti Naijiri aba fẹ ni ilọsiwaju.
El-Rufia ni oun ti gba lati jẹ ipe ajọ EFCC, ti ohun si ti fi ohun ransẹ si wọn pe oun yoo ri aye ni Ọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlogun oṣu keji, ni deede ago mẹwaa.
Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu BBC, El-Rufia ni bo tilẹjẹpe wọn ko ti mu oun, wọn ti mu ọpọ eeyan to sumọ oun, ti oun si gbagbọ wọn yoo mu oun naa ni laipẹ.
"Wọn ni awọn eeyan ti a ba ṣiṣẹ ni Kaduna, to ba to asiko temi, mo ma ja fun ara mi," El-Rufia sọ fun BBC ninu ifọrọwerọ to ṣe.
Ṣé lóòótọ́ ni agbófinró gbìyànjú láti mú Nasir El-Rufai ní pápákọ̀ òfurufú? Ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Mallam El-Rufai/ Facebook
Gomina ipinlẹ Kaduna nigba kan, Nasir El-Rufai, ni iroyin deede gbode nipa rẹ l'Ọjọbọ, pe awọn agbofinro fẹ mu un ni papakọ ofurufu ilu Abuja, nigba to n bọ lati orilẹede Egypt.
Bi iroyin naa ṣe gbode ni ọpọ eeyan n beere ohun to ṣẹlẹ ti wọn yoo fi mu El-Rufai, ko si pẹ ti El-Rufai funra ẹ fi fidi ẹ mulẹ nipasẹ Olugbani-nimọran lori iroyin rẹ, Muyiwa Adekeye.
"Awọn ẹṣọ alaabo fẹ mu Malam Nasir El-Rufai bo ṣe n sọkalẹ ninu baaluu lati Cairo"
Adekeye lo sọ bẹẹ, o ni ṣugbọn El-Rufai ko gba fun wọn lati mu un.
Idi eyi bo ṣe wi ni pe awọn to fẹ mu un naa ko mu iwe ipe to fun wọn lẹtọọ lati mu El-Rufai wa.
O ni ṣugbọn awon ẹṣọ naa ja iwe irinna gomina tẹlẹ naa gba lọwọ ẹṣọ El-Rufai kan.
O ti tojọ mẹta ti El-Rufai ko ti si ni Naijiria, awon to sunmọ ọn nikan lo si mọ pe Ọjọbọ oni naa ni yoo balẹ si Naijiria
Ninu fọto kan ti Olugbani nimọran lori iroyin fun El-Rufai fi soju opo X rẹ, o ṣafihan gomina tẹlẹ naa to duro nibi kan ni papakọ ofurufu naa, ti awon eeyan si pẹjọ ti i.
Fidio miran ṣafihan ibi tawon kan ti waa lati pade rẹ.
"Ileeṣẹ agbofinro kankan ko ti I sọrọ lori iṣẹlẹ yii"
Lasiko ti a n kọ iroyin yii, ko ti I si ileeṣẹ agbofinro kankan to jade pe oun loun wa nidii igbesẹ ati mu El-Rufai.
Fidio kan naa tun ṣafihan ibi ti Nasir El-Rufai nibi to ti n koju ẹṣọ kan to duro niwaju rẹ.
Tẹ o ba gbagbe, ninu ọsẹ yii ni El-Rufai sọrọ nipa Aarẹ Bola Tinubu, to ni Aarẹ ki i ṣe ọrẹ oun latilẹ, ati pe awọn ko figba kankan jẹ ọrẹ ri.
O ni oun ti ẹgbẹ Aarẹ Tinubu lẹyin ni 2023 nitori Iwọ Oorun Naijiria nipo naa kan ni, awọn eeyan nla si tun bẹ oun lati ti I leyin.
Tẹlẹ ri, Tinubu ti figba kan ka El-Rufai mọ ara awon ti yoo se minisita ninu ijoba re, sugbon ọrọ pada daru.
Oṣu Kẹta ọdun 2025 ni El-Rufai kọ APC silẹ, to darapọ mọ Social Democratic Party (SDP).
Ta ni El-Rufai?
Nasiru El-Rufai ni gomina ipinlẹ Kaduna laaarin ọdun 2015 si 2023.
2014 lo kọkọ bori ninu eto idibo abẹle ninu ẹgbẹ APC.
El Rufai ti ṣe minisita eto karakata lẹẹmeji.
O ṣe minisita ilu Abuja lati oṣu Keje 2003 titi de oṣu Karun-un 2007.
2025 to darapọ mọ SDP naa lo tun di ọmọ ẹgbẹ ADC, lati gbe ẹgbẹ ti yoo le Tinubu danu ni 2027 kalẹ.


























