Ọwọ́ tẹ afurasí kan tó fipá bá ọrẹ́ méjì ló pọ̀ ni Eko

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọwọ ti tẹ ọkunrin kan, ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Abidemi Emmanuel, ẹni ti wọn fẹsun kan pe o fipa ba sọrọ-sọrọ lori ayelujara ti ọpọ mọ si Fems Thrift ati ọrẹ rẹ lopọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa lo kede eyi, ti wọn si ni Emmanuel tan awọn ọdọmọbinrin pe oun ni iṣẹ oge ṣiṣe fun wọn ni agbegbe Ajao Estate ni ọjọ Kẹjọ oṣu keji ọdun 2026.

Ninu fidio kan, Fems Thrift ṣalaye pe ọkunrin naa kan si oun lori ayelujara Instagram, pe oun ṣẹsẹ de lati ilu UK, to si fẹ bẹrẹ okowo oge ṣiṣe ni Naijiria.

O tẹsiwaju pe afurasi naa sọ pe oun maa fun oun ni N140,000 fun iṣẹ yii, to si tun bẹ lọwẹ pe ko ṣe igbelarugẹ rẹ.

"Bi a ṣe de sibi ti wọn ti ni ki a wa, ni ọkunrin yii kọlu emi ati ọrẹ mi."

Fems Thrift ṣalaye siwaju , "Nigba ti a de ile afurasi naa, ofifo ni wọn ba ibẹ. Afurasi naa ni oun n lo yara fun yiya fidio ni, to si ni ẹni ti yoo ṣe oge oju wa ti n bọ lọna.

"O ni o sọ pe ara mi kun fun ororo, to si ni ki n lọ wẹ, pe oun yoo fun mi ni aṣọ.

"O fun mi kọkọrọ kan, pe ki n ti ilẹkun, titi awọn yooku yoo fi de. O ti ilẹkun naa, o si duro si ẹgbẹ kan, nibẹ ni ẹru ti n ba mi.

"Ko pẹ ni o yọ ọbẹ sita, to si ni ki a bọ aṣọ wa. O de ọwọ wa, to si ni oun yoo gun wa ti a ba pariwo.

"O bawa fun ni ọpọ igba lai lo idabobo ." o fikun.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Abimbola Adebisi sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori ẹsun naa, ti ọwọ si ti tẹ afurasi.

"Afurasi yii, Abidemi Emmanuel, ẹni ọdun mẹtalelogun, ti wa ni akata wa, ti iwadii si ti bẹrẹ.

"Afurasi yii yoo foju ba ile ẹjọ kete ti iwadii ba ti pari."