Àwọn agbébọn tún kọlu agbègbè Kakafu àti Saare ni Kwara

Aworan awọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn afurasi agbebọn tun ti kọlu agbegbe meji kan nipinlẹ Kwara, ti wọn si ji eeyan mẹrin gbe lọ.

Ikọlu yii waye ni agbegbe Kakafu nijọba ibilẹ Patigi, ti omiran si tun waye ni agbegbe Saare, ni ijọba ibilẹ Ifelodun.

Ohun ti a ri gbọ nipa ikọlu to waye ni agbegbe Kakafu ni oe o waye ni deede ago kan abọ ọjọ Aiku, ti awọn agbegbọn yii si ji ọkunrin, obinrin kan ati awọn ọmọ rẹ meji gbe lọ.

Gẹgẹ bii a ṣe ri gbọ, bi awọn agbebọn naa ṣe yawọ ilu naa ni wọn da ibọn bolẹ, ti ọpọ aaalu si n ṣa fun ẹmi wọn kijo-kijo.

Ẹwẹ, oṣojumikoro to ba ileeṣẹ iroyin Channel TV sọrọ ṣalaye pe awọn agbebọn kọlu agbegbe lai si idiwọ kankan, ti wọn sir u awọn eeyan ti wọn ji gbe lọ sibi ti ẹnikẹni ko mọ.

"Wọn ko pa ẹnikẹni. Wọn ji eeyan mẹrin gbe lọ, yin ibọn soke lati ṣe ẹrub ba araalu," o sọ.

Bakan naa ni agbegbe Saare ni ijọba ibilẹ Ifelodun, awọn agbegbe tun kọlu agbegbe naa ni irọle ọjọ Aiku, ti wọn si da rogbodiyan silẹ.

Awọn ẹsọ alabo ilu naaa fidi rẹ mulẹ pe awọn koju awọn agbebọn naa ninu ija ibọn fun odidi wakati, ti awọn agbebọn si ni lati ṣalọ.

Lasiko ti a n kọ iroyin yii, a ko ti le sọ iye eeyan ti wọn ji gbe lọ niluu Saare.

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara ti ni iwadii ti bẹrẹ lori awọn ikọlu naa.

Ki i ṣe igba akọkọ ree ti awọn agbebọn yoo kọlu awọn agbegbe nipinlẹ Kwara, lọsẹ to kọja ni awọn agbesunmọmi gbe fọnran kan sori ayelelujara to safihan ọgọrọ awọn obinrin ati awọn ọmọde ti wọn ji gbe ni Kwara.

Ninu fọnran naa ni eeyan kan ti n sọrọ lede Hausa, to si n bi awọn obinrin naa lere ibi ti awọn ti ji wọn gbe.

Lẹyin iṣẹlẹ naa ni ijọba kede iye eeyan ti wọn ji gbe, to si sọ pe iṣẹ ti n lọ lati doola wọn eeyan naa.

Amọ ṣa, awọn agbesunmọmi naa ti gbe fidio jadem ninu eyii ti wọn ti sọ pe iye eeyan ti awọn ji gbe lọ pọ ju iye eeyan ti ijọba kede faraye.