Ọdún Ajé gbéra sọ ní Ile-Ife lónìí

Igbagbọ Yoruba pe Orisa aje jẹ oriṣa ti ko ṣe fi ọwọ rọ sẹyin ninu awọn oriṣa to wa nilẹ Yoruba, paapa niluu Ile Ife.
Ọdun Aje yii maa n waye lọdọọdun ni Ile Ife nipinlẹ Osun, to si tun ti bẹrẹ lonii, ọjọ Kẹrindinlogun, oṣu keji ọdun 2026.
Orisa Aje je ọkan lara awon orisa ilẹ Oodua ti wọn n bọ ni ilu Ile Ife nipinle Osun ni guusu Iwo oorun Naijiria.Irinwo o le kan ni oriṣa to wa ni ile-ifẹ, ṣugbọn oriṣa aje olokun jẹ akọkọ ti wọn kọkọ mọ ṣe ọdun rẹ lati fi lana fun awọn oriṣa to ku ati lati fi wure.
Bawo ni wọn ṣe ma n ṣe ọdun yii?
Bi oni ṣe jẹ ọjọ ti wọn n ṣe ayẹyẹ ọdun oriṣa aje olokun ni ile-ifẹ. Kabiyesi Ọba Adeyeye Enitan ogunwusi Ọọni ti Ile-ifẹ yoo gbe igba oriṣa aje olokun pẹlu iyọ lọ si idi oriṣa aje lati aafin.
Ni akoko naa ni Kabiyesi yoo mọ fi iyọ to wa ni ọwọ wọn ṣe iwure fun awọn oriṣa to ku ati gbogbo eeyan patapata titi wọn yoo fi de idi oriṣa aje.
Lẹyin naa ni awọn atọkun oriṣa aje yoo gba igba aje olokun lọwọ kabiyesi, ti wọn yoo si wure fun kabiyesi naa pada.
Lara bi wọn ṣe mọ kii oriṣa aje olokun naa leyi. Loni Ojo Aje, mo pe ọ Orisha Aje Olokun, Aje Oguguniso, Onisoiboji, wa fi Ile wa se bugbe. Ati bẹẹ bẹẹ lọ.























