Israel rọ òjò àdó olóró lé Gaza lórí, èèyàn mọ́kànlá jáde láyé

Oríṣun àwòrán, getty
Ọmọ ilẹ Palestine mọkanla lo ti padanu ẹmi wọn lẹyin ikọlu Israle laarọ kutu ọjọ Aiku.
Ileeṣẹ ọmọ ogun ati ileeṣẹ to n ri si eto ilera Palestine lo fidi iroyin naa mulẹ.
Ileeṣẹ ọmọ ogun Israel loun ju awọn ado oloro naa lẹyin ti awọn ọmọ ogun Hamas yẹ adehun jogun-o-mi to wa laarin wọn.
Wọn ni awọn agbebọn to n gba inu iho ilẹ lọ agbege ti Israel n dari lawọn doju ikọlu naa kọ.
Ajọ adoola ẹmi Palestine, Palestinian Red Crescent sọ pe iwaju atibaba ni ariwa Gaza ni ado oloro naa balẹ si nibi to ti gbẹmi eeyan mẹfa.
Wọn ni ado oloro mii tun balẹ si guusu Gaza nibi to ti gbẹmi eeyan marun un mii.
Israel ati Hamas ni wọn ti n fẹsun kan ara wọn lojojumọ pe wọn yẹ adehun jogunomi ti wọn tọwọ bọ ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2025.
Hamas ni ko din ni eeyan 600 to ti ku lati igba ti awọn mejeji ti tọwọ bọwe adehun jogun-o-mi ọhun.
Ni ibẹrẹ oṣu yii ni ado oloro Israel pa eeyan mejilelọgbọn ni Gaza.
Ikọlu to ṣẹṣẹ waye yii lo n waye lasiko ti wọn n mura fun apa keji adehun jogun-o-mi ti ilẹ Amẹrika sagbatẹru rẹ.
Loṣu to kọja, Aarẹ Donald Trump kede ajọ tuntun kan to pe ni Board of Peace, ti ojuṣe rẹ jẹ mimu ẹka eto abọ ajọ UN, iyẹn United Nations Security Council rẹyin ogun naa.
Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keji ti a wa yii lo yẹ ki awọn ọmọ igbimọ naa ṣe ipade wọn akọkọ niluu Washington DC lati bojuto bi alaafia yoo ṣe pada si Gaza lẹyin ogun to n lọ lọwọ pẹlu Israel.
Lọsẹ to kọja, wọn ni Indonesia, to jẹ ọmọ igbimọ Board of Peace yoo fi ẹgbẹrun mẹjọ ọmọ ogun ṣọwọ si Gaza gẹgẹ bii ọkan lara adehun jogunomi naa.
Ogun naa bẹrẹ lẹyin ti Hamas kọlu Israele lọjọ keje, oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 nibi ti wọn ti pa ọmọ Israel 1,200, ti wọn tun ji eeyan 251 mii gbe lọ lara wọn.
Lẹyin naa ni Israel gbe ogun lọ ka Hamas mọle, ninu eyii ti ẹmi eeyan to le ni 71,000 ti lọ si.



























