Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì, wọ́n dóòlà 10 nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi ní ìpínlẹ́ Sokoto

Aworan ọpọ ọkunrin to wa ninu ọkọ oju omi, ti wọn si n wa lọ. Ọpọ awọn ọkunrin yii ni dudu lawọ.

Oríṣun àwòrán, NEMA/FACEBOOK

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ to n ri iṣẹlẹ pajawiri lorilẹede Naijiria, NEMA ti kede sita pe awọn n wa o le ni ogoji eeyan lẹyin iṣẹlẹ ijamba ọkọ oju omi to waye nipinlẹ Sokoto.

NEMA, ninu atẹjade kan ti wọn lede ṣalaye pe ọkọ oju omi to n gbe eeyan to le ni aadọta lọ si ọja lo yi sinu omi ni owurọ ọjọ Aiku, Ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹjọ ọdun 2025.

"A ti doola eeyan mẹwaa, ti a si n wa eeyan to le ni ogoji ni iye," NEMA ṣalaye.

Iṣẹlẹ yii waye ni agbegbe Gojiyau ni ijọba ibilẹ Goronyo nipinlẹ Sokoto ti ọpọ idile lo wa ninu ibanujẹ ọkan bayii

Usman Dangaliman ti abule Ruwan Goronyo ba BBC News Pidgin sọrọ to si fidi iroyin naa mulẹ pe iṣẹlẹ naa waye ni abule kan ti wọn n pe ni Kojiyo.

Yatọ si nnkan ti awọn ijọba sọ, Dangaliman ni eeyan mẹdogun pẹlu ọkada wọn lo n gbiyanju lati sọda odo lati le ni anfani lọ si ọja to wa ni ilu Goronyo.

"Eeyan mẹdogun lo ni ijamba ọkọ oju omi yii nigba ti wọn fẹ lọ si ọja kan ni Goronyo"

Awọn oṣiṣẹ adoola sin n gbiyanju lati ṣawari awọn eeyan to ba iṣẹlẹ naa lọ.

"A ti ti oku eeyan kan ninu omi pẹlu ọkada mẹfa to wa ninu ọkọ oju omi naa lasiko ti ijamba naa waye," Galadima sọ fun BBC.

O ni lọwọ lọwọ bayii, awọn ko le ṣalaye ohun pato to ṣokunfa ijamba naa.

"Eeyan kan ni a si ri, a si n wa awọn yooku ti wọn wa ninu baalu naa. A ko da awọn yooku ninu ọkọm oju naa mọ.."

Ninu igbiyanju wọn lati ṣawari awọn eeyan yii, Galadima ni awọn ti kede ti awọn ilu mii to ṣumọ pe ki wọn ran wọn lọwọ.

"Ni bayiii, a ti pe awọn pẹjapẹja pe ki wọn ran wa lọwọ lati ṣawari awọn eeyan yooku."