Ìgbésẹ̀ láti yan Awujale tuntun bẹ̀rẹ̀, ìdílé ọmọ oyè ń fápa jánú pé wọ́n ti fẹ́ yí ìtàn padà

Aworan Oloogbe Ọba Sikiru Adetona Kayode, Awujale Ijebu. Oba naa jokoo lori itẹ pẹlu igo rẹ loju, ilekẹ oye lọrun, o si di awọn ika ọwọ rẹ pọ ninu aworan yii, o n wo orere.

Oríṣun àwòrán, Awujale Palace

Àkọlé àwòrán, Ọba Sikiru Adetona Kayode, Awujale Ijebu to waja laipẹ ree.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Yoruba ni bi ọba kan ko ba ku, omiran kii jẹ, bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu igbesẹ yiyan ọmọ oye tuntun si ipo Awujalẹ tilẹ Ijebu.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ Kẹtala osu Keje ọdun 2025 ni Awujalẹ ti Ijebu Ode, Ọba Sikiru Kayode Adetona waja, ti wọn si sin-in ni ọjọ naa ni ilana ẹsin Islam.

Ni bayii, ijagudu ti bẹrẹ lati yan ọmọ oye tuntun sipo rẹ laarin idile oye to n jọba ni Ijebu Ode.

Amọ idile kan laarin awọn idile to n joye ọba ilu Ijebu naa, ti n fapa janu lori iyansipo ọba to bẹrẹ naa.

"Bí wọn ṣe yọ ìdílé Adeyemi kúrò nínú ọmọ oyè láti ìdílé Anikilaya kò tọ̀nà, wọ́n ti fẹ́ yí ìtàn ìyànsípò ọba padà"

Mọlẹbi Adeyemi niluu Ijebu-Ode, eyi to jẹ ẹka idile Anikilaya, lo ti n fi aidunnu wọn han si bi wọn ṣe ni wọn yọ orukọ awọn kuro ninu ọmọ oye to le du ipo Awujalẹ ilẹ Ijebu.

Gẹgẹ bi molẹbi Adeyemi ṣe ṣalaye, wọn ni ọmọ oye ni awọn, agba si lawọn pẹlu.

Ati pe idile naa ni Ọba Sikiru Adetona, Awujalẹ to waja laipẹ ti wa.

Atẹjade kan ti Adedeji Ademola Adeyemi lati idile naa fi sita, sọ pe awọn eeyan kan ti yi itan pada bayii lati abala idile oye Anikilaya.

Wọn ni wọn ti yọ orukọ Adeyemi kuro ninu ẹka ọmọ oye n'Ijebu-Ode, eyi ti ko yẹ ko ri bẹẹ.

Àwọn wo ni ìdílé Adeyemi?

Ninu alaye Adedeji Ademola Adeyemi nipa idile to ni wọn yọ orukọ wọn kuro yii, o ni Adeyemi Anikilaya ni Arẹmọ ọba to dagba ju ninu awọn ọmọ ọba Anikilaya Saagun, to si kọkọ jẹ ọba.

Ogbagba ati Ademolu ni wọn jẹ aburo ọkunrin lẹyin rẹ bo ṣe sọ.

O fi kun un pe, "Ọmọọba Ademola Aiyegbajeje Adeyemi ni wọn yan sipo Awujalẹ lẹyin ti Ọba Daniel Adesanya (Gbelegbuwa II) waja ni 1959, ṣugbọn o ni oun ko fẹ.

"Aburo rẹ, Ọmọọba Mubashiru Adedipupo Adeyemi, to jẹ Baba fun Oloogbe Ọba Sikiru Adetona, si fa ọmọ rẹ ti i ṣe Sikiru kalẹ fun ipo ọba naa, lati idile Adeyemi Anikilaya kan naa. Awọn afọbajẹ tẹwọ gba a, o si di Awujalẹ ni ọdun 1960."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade ẹbi Adeyemi wi.

Ẹbi naa ni awọn ko gba bi awọn eeyan kan ko ṣe fẹẹ fi agba fun idile Adeyemi gẹgẹ bii igun to dagba ju lọ.

Wọn ni kaka ki awọn to wa nidii ọrọ naa ṣe ẹtọ, niṣe ni wọn gbe ipo olori fun ọmọkunrin keji.

Ati pe wọn tun fi awọn meji mi-in ti wọn ki i ṣe ọmọ oye kun un.

Àwọn wo ni kò yẹ kí wọ́n wà nínú ìdíje?

Gẹgẹ bi Adeyemi ṣe wi, "Ko yẹ ki idile ọmọ ọba Mabadeje, Adekoya Ofirigidi ati Adeire Adeewu wa lara awọn ti wọn yoo fi kun un idije sipo Awujale.

Awọn wọnyi ni wọn ni ọmọ Ọba Anikilaya Saagun Figbajoye ni wọn, ti baba wọn jọba ni 1821, ṣugbọn awọn ko mọ wọn.

"Awa idile ọmọ oye Adeyemi, fidi ẹ mulẹ, pe arọmọdọmọ Adeyemi Anikilaya, ni wa. Oun si ni Arẹmọ to dagba ju ninu awọn ọmọ Ọba Anikilaya Saagun Figbajoye, to jẹ Awujale Ijebu Ode titi di 1821."

Ṣaa, awọn ẹbi Adeyemi ni awọn rọ awọn eeyan lati ma ṣe gba ohun ti awọn eeyan kan n gbe kiri ninu ẹbi gbọ.

"Bí wọn kò bá ṣe ètùtù ikú Awujalẹ Adetona, yóò dààmú Ìjẹ̀bú-Òde"

Awujalẹ Adetona àti Abọrẹ Akilẹ Ìjẹ̀bú

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àkọlé àwòrán, Ọba Sikiru Adetona tó ti di olóògbé wọ aṣọ aláwọ̀ ofeefe pẹlu ìlẹ̀kẹ̀ ati Razak Adeneye Oshimodi, Ọlọ́wá Ibẹru tíì ṣe Abọrẹ Akilẹ Ìjẹ̀bú to wọ Ankara aláwọ̀ Pupa pẹlu adé Lori ati ìlẹ̀kẹ̀ lọrun.

Àgbà oyè kan ni ilu ijebu Ode, Razak Adeneye Oshimodi, tii se Ọlọ́wá Ìbẹ̀rù ti Ìjẹ̀bú-Òde àti Abọrẹ̀ Akile Ìjẹ̀bú tí sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀ṣe.

Ọlọ́wá, tii ṣe àgbà òye kẹta sí Awujalẹ lẹ́yìn Olisa, ṣàlàyé pé bí wọ́n ko bá ṣe orò lẹ́yìn ikú Awujalẹ to papoda laipẹ yìí, Ọba Sikiru Kayode Adetona, ìgbésẹ̀ náà le e lẹ́yìn, tí yóò sì dààmú ìlú Ijebu Ode.

Agba Oye Oshimodi, woye ọ̀rọ̀ náà nínú ifọrọwerọ to bá ileeṣẹ ìròyìn Punch se, èyí tí fídíò rẹ ń jà lórí ayélujára.

Àmọ́ ó wá gbáà ní àdúrà pé Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí ìdààmú bá ìlú Ìjẹ̀bú Òde lórí ọ̀rọ̀ to ń jà nílẹ̀ náà.

Ọlọ́wá Ibẹru àti àwọn èèyàn miran wà nìdí òrìṣà

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àkọlé àwòrán, Ọlọ́wá Ibẹru fi ọwọ́ mú igi ìrókò ńlá kan tí wọn rọ̀ aṣọ funfun mọ lára, èyí tí wọn pe ni ìdí òrìṣà, àwọn èèyàn kan sì dúró tì Abọrẹ náà.

"Òrìṣà ló ni adé orí àti ìlẹ̀kẹ̀ tó wà lọrun ọba, a sì máa ń lé ìtẹ́ fún ọba"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọlọ́wá Ibẹru ni Ọba to bá sọ pé ọba lé ma ṣe ìṣẹ̀ṣe, torí kò ṣe ìṣẹ̀ṣe kò tó dé orí ìtẹ́, kò mọ òun tó ń sọ ní.

"Adé tó wà lórí rẹ̀, ta ló ni í? Ìlẹ̀kẹ̀ ṣẹ́ṣẹ́ ẹfun tó wà lọrun rẹ̀, ta ló ni í? Ó ní Òrìsà to ni adé yẹn, òrìṣà ló ni í.

Wọ́n máa lé ìtẹ́ fún ọba, kó tó le jókòó sórí ìtẹ́ náà. Ọba tí wọn bá sì lé ìtẹ́ fún, kìí ṣe Mùsùlùmí ni yóò wá ka Tírà níbẹ̀.

Mo ti sọ pé tí wọn kò bá ṣe ètùtù fún ikú ọba Sikiru Adetona, ó máa dààmú Ìjẹ̀bú-Òde torí ọba kan kò gbọ́dọ̀ da ní àṣà pé òun kò bá oníṣẹ̀ṣe jẹ.

Gbogbo ohun tó bá bá ní ààfin pátápátá, nǹkan ìṣẹ̀ṣe ni torí kò sí ààfin tí ẹ máa dé, tí ẹ kò ní bá nǹkan ìṣẹ̀ṣe níbẹ̀.

Ọba tí ó bá sọ bẹẹ, igbẹyin wọn kì í dára, pàápàá ni ọdọ wa nibi, ní Ìjẹ̀bú Òde.

Àwa oníṣẹ̀ṣe ni a máa ṣètò bí gbogbo nnkan ṣe máa tuba tusẹ fun Ọba, torí kí ìlú má bàa dàrú, ní àwa oníṣẹ̀ṣe ṣe yẹba.

Olisa lo bẹ oníṣẹ̀ṣe pé kí wọ́n má jẹ ki ìlú dàrú lórí tòun, bí wọn ṣe ń pariwo pé kí oníṣẹ̀ṣe máa lọ lọ́jọ́ ìsìnkú yẹn, bí wọ́n bá yán ìgbálẹ̀ sí wọn, onítọ̀hún yóò ti mọ ibi tí ara òun kù sí.

Ní ọdún 1960, odindi ìlú kan tí irufẹ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tí wáyé, ṣe ló tú, n kò ní dárúkọ ìlú náà.

Àgbà oyè Razak Adeneye Oshimodi, Ọlọ́wá Ibẹru tíì Ijebu Ode àti Abọrẹ Akilẹ Ìjẹ̀bú, to jẹ àgbà òye kẹta sí Awujalẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àkọlé àwòrán, Àgbà oyè Oshimodi wọ aṣọ Ankara pupọ, ó mú ọ̀pá funfun lọ́wọ́ àlàáfíà, ó fi ọwọ́ otun sọ aya, tó sì là ẹnu bíi ẹni pé ó ń sọrọ.

"Wòlíì àti Aafa ń lọ síbi ìṣẹ̀ṣe ní alẹ, àwa ní à ń ṣe òògùn fún wọn, èmi ni mo ṣe èṣù sínú ṣọ́ọ̀sì àti Mọsalasi"

Ọlọ́wá Ibẹru tẹsiwaju pé "Ayanlaja sọ fún wa pé ọba Adetona ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn Mùsùlùmí ni kó sin òun àmọ́ ohun tó bá jẹ́ ti àwọn oníṣẹ̀ṣe, kí wọn fún wọn.

Ohun tí wọn fi ń tan àwọn ọmọ wa jẹ nìyẹn, ẹni tó bá sọ pé wọn ń gé orí ọba, wọn ń gé apá àti ẹsẹ ọba, irọ ló pa.

Irú rẹ kò ṣẹlẹ̀ mọ, ọlaju ti wà, ibi tí wọ́n máa sin orí, apá àti ẹsẹ ọba sí, ẹran ní wọ́n ń sin síbẹ̀.

Ohun náà la ṣe lásìkò yìí, o dẹ tuba tusẹ.

Anabi gan kò jẹ́ sọ pé kò sí awo, ìgbà tí Ọba Adetona sọ irú rẹ, adé tó wà lórí rẹ̀, ni kò jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ òdì si.

Àmọ́ ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn kú díẹ̀ kaato. Oníṣẹ̀ṣe wá káàkiri àgbáyé, ẹ kò lé dé ìlú kan, kí ẹ má bá ẹṣin ìbílẹ̀ nibẹ.

Ẹ máṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín jẹ pé ìṣẹ̀ṣe jẹ ẹṣin àṣáwọ̀, rárá, kìí ṣe ẹṣin àṣáwọ̀.

Ìṣẹ̀ṣe ni àgbà, òun ni a kọ́kọ́ dá, wòlíì àti Alfa, tó bá ní kí ẹ má lọ síbi ìṣẹ̀ṣe, ẹ má gbà ó.

Àwọn náà ń lọ síbi ìṣẹ̀ṣe ní alẹ, àwa ní à ń ṣe òògùn fún wọn, Pasitọ̀ kan wa, èmi ni mo ṣe èṣù sínú ṣọ́ọ̀sì rẹ, èmi náà ni mo ṣe èṣù sínú mọsalasi.

Èṣù náà ni wọn ń pè ní ọba alaje, ó máa lọ máa tí èrò wá rẹpẹtẹ, ẹ máṣe tán ara yín jẹ."

Àgbà oyè Oshimodi

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àkọlé àwòrán, Àgbà oyè Oshimodi nínú aṣọ Ankara Pupa, pa kaja aṣọ funfun, ó sì dúró sídìí òrìṣà rẹ tí wọn gbé sábẹ́ igi ìrókò ńlá kan, àwọn èèyàn kan dúró tì í.

"Àlàyé rèé lórí bí èmi Abọrẹ Akilẹ Ìjẹ̀bú ṣe ń ṣe ètùtù fún ọba tó fẹ́ jẹ ní ìlànà ìṣẹ̀ṣe"

Àgbà oyè Oshimodi, lásìkò tó ń ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ń jẹ Awujalẹ ní ìdílé ọba tí òye kàn, ní yóò panupọ láti fa ọmọ òye kalẹ.

"To bá di pe wọn fẹ́ yàn ọba, àwọn Ọlọ́wá lo máa ṣe kokari iyansipo àti fífi ọba jẹ.

Tí wọn bá ti mú ọmọ òye wá láti ìdílé tí ipò ọba kan, wọn yóò fa ọmọ òye náà kalẹ fún Ìlámùrẹ́, wọn yóò ṣàyẹ̀wò ọmọ òye náà, kí wọn tó kú lé àwọn Odi lọ́wọ́.

To bá ń bọ̀ láti Òdo, ó máa wà sì ojúbọ Èṣù Ọba, nibẹ sì ni wọn yóò ti yọ ọwọ́ Sikiru Adetona kúrò ní ojúbọ Èṣù náà torí tí Ọba miran bá jẹ, kí ohunkóhun má bàa ṣe é.

Nígbà tí a yọ ọwọ́ Sikiru Adetona kúrò lórí Èṣù Ọba, ètùtù yẹn gbà torí àpẹrẹ mẹta la rí.

Òjò rọ̀, Èṣù tún mú àwọn ẹran àti adìẹ tí a mú lọ.

Tí a bá bọ èṣù ọba fún ọmọ òye tuntun tán, ó máa wá sí ìdí igi Ìrókò, ó sì ní ètùtù tí a tún máa tú ṣe fún nibẹ.

Èyí kan èmi Ọlọ́wá, tii ṣe abọrẹ̀ Akilẹ Ìjẹ̀bú, ni mo sọ yẹn."

Ọba Sikiru Adetona

Oríṣun àwòrán, Awujale Sikiru Adetona

Àkọlé àwòrán, Olóògbé Ọba Sikiru Adetona wọ aṣọ aláwọ̀ ofeefe, ó fi ìlẹ̀kẹ̀ sọrun, ó dé fìlà aṣọ to wọ, ó sì fi dígí sójú

Kí ló ti wáyé ṣáájú

Ọjọ́ kẹtàlá oṣu Keje ọdun 2025 ni Awujalẹ ti Ijebu Ode, ọba Sikiru Kayode Adetona wàjà.

Àwọn ẹbí rẹ kò sì gbà kí àwọn oníṣẹ̀ṣe wá ṣe ètùtù tàbí sí òkú rẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà ìṣẹ̀ǹbáyé.

Àwọn Aafa sì lọ sí ọba Adetona ní ìlànà ẹ̀sìn Mùsùlùmí èyí tó fa awuyewuye pupọ.

Ìdí sì rèé tí àgbà òye Razak Adeneye Oshimodi, tii se Ọlọ́wá Ibẹru àti Abọrẹ Akilẹ Ìjẹ̀bú, ṣe ṣàlàyé pé ìgbésẹ̀ náà kò bá ìlànà ìṣẹ̀ṣe mú.