Àṣìṣe gbá à ni bí Bàbá Osun ṣe ru igbá Osun Osogbo lọ́dún yìí, òun kọ́ ni igbá rírù kàn - Ìyá Osun

Iya Osun Olojudo, Yeye Osunpidan Nathaniel
Àkọlé àwòrán, Iya Osun Olojudo, Yeye Osunpidan Nathaniel
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọsẹ to kọja yii ni ọdun Osun Osogbo ti ọdun 2025 pari niluu Osogbo, ipinlẹ Osun.

Ọkan lara awon ohun to si ṣẹlẹ nibẹ ni pe Baba Osun ṣe gba igba lori ọmọdé, ọmọ ọdún méje tó jẹ́ Arugbá ní odún yìí, to kọkọ n ru igba naa, tí bàbá Osun si ba a ru u.

Eyi lodi si bo ṣe maa n jẹ pe, wundia ti ko mọ ọkunrin rí lo maa n ru Igba Osun lọdọọdun, ọpọ eeyan lo si ṣe ni kayeefi gidi.

Igbá ti Baba Osun ru náà, ni Iya Osun ti ilu Ido-Osun, nipinlẹ Osun kan naa, Yeye Osunpidan Nathaniel, ti bu ẹnu atẹ lu bayii, to ni ko yẹ ko ri bẹẹ.

Iya Osun Osunpidan sọ fun BBC News Yoruba, pe aṣiṣe ni igba ti Baba Osun ru naa labẹẹ bo ti wu ko ri.

Nibi ayẹyẹ ọdun Osun Olojudo ti ilu ilu Ido-Osun, to waye lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kejọ ọdun 2025 yii ni Yeye Osunpidan ti ṣalaye naa.

Arugba Osun Olojudo ati awọn amugbalẹgbẹẹ rẹ
Àkọlé àwòrán, Arugba Osun Olojudo; Omidan Omitoki Adeshina ati awọn amugbalẹgbẹẹ rẹ

''Bí ẹni ti Ifa mú láti ru igbá bá kéré, síbẹ̀, kò tọ́ sí Baba Osun láti bá a rù ú''

Ninu alaye rẹ siwaju, Iya Osun Osunpidan sọ pe o ṣee ṣe ki ẹni ti Ifa mu lati ru igba kere lọjọ ori, o ni ṣugbọn iyẹn ko sọ pe ki Baba Osun ba a ru u.

Ki wa lo yẹ ki wọn ṣe bi Arugba ko ba le ru u?

Osunpidan ṣalaye pe, Aworo Awo ni ọrọ kan to ba ri bẹẹ.

O ni Aworo Awo ni yoo ru igba Osun.

Koda, Iya Osun Olojudo sọ pe ọba ko ni agbara lati yan ẹni ti yoo ru igba Ọsun, bi ko ṣe pe ki wọn difa lati mọ ẹni to tọ si lati ru u.

Bi ko ba si Aworo Awo nitosi lati ru igba, Yeye Osunpidan sọ pe wọn gbọdọ difa lati mọ ẹni ti yoo ru u ni.

Bakan naa ni Osunpidan sọ pe ọpọlọpọ igba ti Arugba n ru bayii ni ko ni iwure gidi mọ, latari bi wọn ṣe n fi ojuṣaaaju yan Arugba.

Iya Osun Ido-Osun fidi ẹ mulẹ, pe eyi lo fa a ti awọn ọba fi n ni aṣẹ lori awọn Atọkun ati Arugba Osun bayii.

O rọ awọn Oriade lati ṣe atunse si ọna ti wọn n gba yan ẹni ti yoo ru igba Osun.

‎Osunpidan sọ pe oun ni Arugba Karun-un to ru igba fun Osun Osogbo, ki oun too wa lọkọ ni ilu Ido-Osun.

Kabiyesi Olojudo Ido Osun; Oba Olayinka Oyetunde
Àkọlé àwòrán, Kabiyesi Olojudo Ido Osun; Oba Olayinka Oyetunde pẹlu Olori rẹ ati awọn eeyan nibi ayẹyẹ naa.

Kí ni ìyàtọ̀ láàárín ọdun Osun Osogbo ati Osun Olojudo?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ijọba ibilẹ Egbedore ni ilu Ido-Osun wa, nipinlẹ Osun, Kabiyesi Oba Olayinka Oyetunde si ni Olojudo ti ilu Ido Osun, nibi ti aṣekagba ọdun Osun Olojudo ti waye.

Ninu alaye rẹ nipa ọdun Osun Olojudo ti wọn ṣe naa, eyi ti awọn eeyan mi-in ko tilẹ gbọ nipa rẹ ri, Ọba Olayinka sọ pe bakan naa ni ọdun Osun Osogbo ati Osun Olojudo ṣe ri.

O ni eyi ri bẹẹ nitori wọn maa n ru igba ninu ọdun mejeeji.

Kabiyesi Oyetunde tẹsiwaju, pe bo ṣe jẹ wundia ti ko ti i mọ ọkunrin lo n ru igba Osun Osogbo, bẹẹ naa lo ri ni ti Osun Olojudo.

Bakan naa lo ni ọdun iwure ni ọdun Osun Olojudo, ọdun ti wọn fi n ru ibi danu bi wọn ṣe n ṣe l'Osun Osogbo.

Olojudo Ido Osun sọ pe nnkan mi-in to so ido Osun ati Osogbo pọ ni pe ẹya kan naa ni awọn mejeeji, lati ipasẹ Oduduwa to so ọmọ Yoruba pọ.

Ọba Olayinka Oyetunde, waa ke si ijọba apapọ ati ti ipinlẹ, lati mojuto ibudo asa ilẹ Yoruba.

Bakan naa lo tun rọ awọn Oriade gbogbo lati gbe aṣa ati ìṣe ilu koowa wọn lárugẹ, ki idagbasoke le de ba ilẹ Yoruba lapapọ.

Fun ti aṣekagba ọdun Osun Olojudo yii, Omidan Omitoki Adeshina lo ru igba, eyi si ni ìgbà karun-un ti yoo ru igba naa.