Awuyewuye lórí bí wọ́n ṣe fi orúkọ Victor Osimhen sọ mọ́ṣálááṣí, àwọn mùsùlùmí ní àbùkù ńlá ni

Aworan Victor Osimhen

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awuyewuye ti bẹ silẹ lori bi wọn ṣe fi orukọ ẹlẹsẹ ayo ọmọ Naijiria to n gbabọọlu fun ikọ Galatasaray lorilẹede Turkey, Victor Osimhen, sọ mọṣalaaṣi kan lorilẹede naa.

Laipẹ yii ni Osimhen pada si Turkey lati darapọ mawọn akẹgbẹ rẹ fun igbaradi fun saa bọọlu tuntun ninu idije liigi Turkey ati kaakiri ilẹ Yuroopu.

Gẹgẹ bi iwe iroyin ere idaraya Fanatik to wa ni Turkey ṣe ṣalaye, mọṣalaaṣi Bulut to wa lẹkun Karatay ni Konya lawọn eeyan ṣadeedee ri pe o ti di ''Mọṣalaaṣi Victor Osumhen'' lori aapu itọnisọna ti wọn n pe ni Google Maps.

Ọdun 2008 ni a gbọ pe wọn ṣi mọṣalaaṣi ọhun lorilẹede Turkey.

Ọpọ awọn olujọsin ni wọn koro oju si bi orukọ mọṣalaaṣi ọhun ṣe yi pada si orukọ Osimhen.

Wọn si n pe fun ki wọn da orukọ mọṣalaaṣi naa pada si orukọ to n jẹ tẹlẹ.

''Mọṣalaaṣi Bulut ni a mọ mọṣalaaṣi yii si lati igba ti a ti n jọsin nibẹ.

Awa o faramọ ki wọn fi orukọ Victor Osimhen sọ mọṣalaaṣi wa, onigbagbọ ni Osimhen.

A fẹ ki awọn alaṣẹ bawa dasi ọrọ yii, ki wọn si da orukọ mọṣalaaṣi naa pada si mọṣalaaṣi Bulut to n jẹ tẹlẹ,'' olujọsin kan lo sọ bẹẹ.

Olujọsin mọṣalaaṣi miran sọ pe ''ohun to wa lori itakun ayelujara ni pe mọṣalaaṣi Bulut ti di mọṣalaaṣi Victor Osimhen.

Ṣugbọn mọṣalaaṣi Bulut ni awa mọ mọṣalaaṣi yii si fun bii ọdun mẹwaa bayii.

Osimhen kii ṣe agbabọọlu to wa lati Konyaspor, ko si ṣe nkankan fun mọṣalaaṣi yii.

Agbabọọlu Osimhen kii ṣe ẹnikan ti awọn eeyan Konya ko le gbagbe laelae.

Nitori naa, igbesẹ lati fi orukọ rẹ sọ mọṣalaaṣi Bulut ko ye wa.''

''Nnkan itiju ni ki wọn fi orukọ ẹni ti kii ṣe musulumi sọ mọṣalaaṣi''

Zeki Yaylacı toun naa jẹ ọkan lara awọn eeyan lawujọ ti mọṣalaaṣi naa wa sọ pe nnkan to le mu inu bi eeyan ni bi wọn ṣe fi orukọ Osimhen sọ mọṣalaaṣi Bulut.

Yaylacı ni nnkan itiju ni ki wọn fi orukọ ẹni ti kii ṣe musulumi sọ mọṣalaaṣi.

''A ri eleyii gẹgẹ bii ọna lati tabuku awọn musulumi, awọn eeyan awujọ ti mọṣalaaṣi yii wa ati mọṣalaaṣi yii gan an gan an.

A rọ awọn alaṣẹ lati ṣe ofin ti ko ni jẹ kọ rọrun lati maa paarọ orukọ mọṣalaaṣi gẹgẹ bi eyi to ṣẹlẹ yii.

Ko si ẹni to le fidi rẹ mulẹ bo ya Osimhen mọ nipa igbesẹ lati fi orukọ rẹ sọ mọṣalaaṣi ni Turkey.

Osimhen fakọyọ ni saa bọọlu to kọja, goolu mẹtadinlogoji lo gba sawọn fun ẹgbẹ agbabọọlu Galatasaray.

Lẹyin naa ni ẹgbẹ agbabọọlu naa ra a patapata lati ikọ agbabọọlu Napoli ti wọn ti ya a lo tẹlẹ.

Osimhen ni agbabọọlu ti wọn fowo to pọ julọ ra ninu itan ere bọọlu lorilẹede Turkey lẹyin ti Galatasaray ra a ni €75m.