Odunlade, Mr Latin, Kunle Afod àtàwọn òṣèré mii ń ṣèdárò Sunday Akinremi Chief Kanran tó jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Sunday Akinremi/Instagram
Ọjọ ti a ba ku la a dere, eeyan o ṣunwọn laaye, awọn alẹnulọrọ lagbo oṣere tiata Yoruba n ṣedaro akẹgbẹ wọn, agbaọjẹ oṣere, Alagba Sunday Akinremi ti ọpo mọ si Chief Kanran ẹni to jade laye lanaa ọjọ Ẹti ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ yii.
Ọgbẹni Bolaji Amusan, to jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere TAMPAN, Odunlade Adekola, Kunle Afod atawọn oṣere mii ti n fi ọrọ ibanikẹdun ransẹ si ẹbi oloogbe.
Adura ni Ọgbẹni Amusan tawọn eeyan mọ si Mr Latin gba fun gbajugbaja oṣere to doloogbe naa loju opo Instagram rẹ.
Mr Latin gbadura wi pe ki Eledua tẹ Oloye Kanran si afẹfẹ rere.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
Ninu ọrọ tiẹ, Kunle Afod sọ loju opo Instagram rẹ pe ''o si nira fun mi lati gbagbọ pe Chief Kanran ti di oloogbe titi di aarọ oni.
A si jọ sọrọ ni bii ọjọ mẹrin sẹyin lori iṣẹ ti a fẹ jọ ṣe papọ lọsẹ to n bọ.
Mo ṣakiyesi pe inu Chief Kanran dun lọjọ ti a jọ sọrọ yii.
A fi bi mo ṣe gbọ pe Chief Kanran ti dagbere faye!
Agbaọjẹ oṣere ni Chief Kanran i ṣe, ki Eleduwa tẹ wọn si afẹfẹ rere.''
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Adura naa ni Odunlade Adekola ba fun agbaọjẹ oṣere to doloogbe loju opo Instagram rẹ.
Adekola gbadura wi pe ki Ọlọrun tẹ Chief Kanran si afẹfẹ rere.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 3
Òṣèré tíátà, Sunday Akinremi Chief Kanran, ti jáde l'áyé

Oríṣun àwòrán, Other
Agba oṣere, Alagba Sunday Akinremi, ti ọpọ mọ si Chief Kanran, ti jade l'aye.
Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2025 ni iroyin jade pe, Chief Kanran dagbere fun aye pe o digba o ṣe.
Ọkan ninu awọn ọmọ rẹ obinrin lo fidi iroyin naa mulẹ fun BBC News Yoruba.
Nigba to n ba BBC sọrọ, ọmọ oloogbe naa sọ pe "ootọ ni, wọn tik u. Wọn ṣẹṣẹ fidi rẹ mulẹ fun wa ni pe wọn ti ku."
Chief Kanran jẹ ọkan gboogi lara awọn oṣere tiata Yoruba ti irawọ rẹ tan gidi.
Ọpọ eeyan lo fẹran lati maa ri ninu ere latari ipa to maa n ko ati bo ṣee maa sọrọ.
Lọpọ igba, baba olowo to n fi owo ṣaanu ni Kanran maa n ṣe ninu awọn fiimu to ti kopa.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ẹni ọdun mejilelaadọrin ni oloogbe naa ki ọlọjọ to de.
Amọ a ko tii le sọ pato nnkan to ṣekupa oloogbe naa lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.
Awọn nnkan to yẹ ki o mọ nipa Chief Kanran

Oríṣun àwòrán, Sunday Akinremi Chiefkanran
Sunday Akinremi ti kopa ninu ọpọlọpọ ere tiata ati sinima agbelewo lati nnkan bi ọdun 1980 to ti bẹrẹ.
Lara awọn ere tiata to ti kopa ni Kunrunmi lati ọwọ Ọjọgbọn Ola Rotimi, ko to o di pe o bẹrẹ si ni kopa ninu ere agbelewo.
Lara awọn fiimu to tun ti kopa ni Vigilante, Ose- Sango, Eri Okan, Itunnu, Eewo, Idunnu, Orire, Ofa Oro, Ajaka Oko, Great Bird of Eternity, Sharttered Bridge. Oba Oluaiye, Bibi Ire, Ilu le, ati I50 Million.
Ìrírí ayé sọ Chief Kanran dí ẹni tí kò rí ilé gbé mọ́, ti irinṣẹ́ jóná
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBC News Yoruba lọdun 2020, ni Alagba Sunday Akinremi 'Chief Kanran' ti sọ iriri rẹ bi oun ṣe di ẹni ti ko ri ile gbe mọ ati bi ohun gbogbo ṣe daru fun oun ni nkan bi ọdun melo ṣẹyin.
Ile ijọsin kan to n gbe lasiko naa ni ifọrọwanilẹnuwo ọhun ti waye.
Kanran ni: "Lẹyin nkan bu oṣu diẹ ti mọ de lati Canada, ile iṣe ipolowo ọja ati yiya ere amohunmaworan mi jona raurau, ti irinṣe to le ni miliọnu lọna ọgbọn Naira si jọna patapata.
"Ko pẹ diẹ si asiko yii ni awọn adigunjalẹ bẹrẹ si ni koju ija si mi, nitori wọn rọ wi pe emi ni mọ ni ile ti mo n gbe ati awọn ẹru ti wọn n ko wa lati oke okun to jẹ ti onile ti a n gbe naa.
''Eyi lo mu ki n sakuro ni awọn ile ti mo n gbe naa, ti mo si sa asala fun ẹmi mi nipa sisalọ si ile ijọsin ni ibi ti mọ n gbe lọwọlọwo.''
Chief Kanran lasiko to n bere iranwọ lọwọ awọn ọmọ Naijiria sọ wi pe gbogbo ohun ini oun ni awọn ti oun ya owo ni ọwọ wọn lati ṣe sinima gba pada, ti oun si da ẹni ti ko ni ọkọ ayọkẹlẹ mọ.
O fikun wi pe ninu ipọnju yii ni oun wa fun ọpọlọpọ igba, ti iyawo meji ti oun ni si saisan ti wọn si ku.
Idojukọ naa lo mu ko ke gbajarẹ si awọn ọmọ ile Yoruba nigba naa lati jọwọ ṣeranwọ fun un nipa pipese irinṣẹ to nilo lati bẹrẹ si ni ṣe fiimu pada.












