Ṣé ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí ni APC àti PDP gẹ́gẹ́ bíi ọ̀rọ̀ ilé ẹjọ́ Canada?

Aworan Atiku Abubakar ati Aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar/Bola Tinubu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ile ẹjọ kan lorilẹede Canada ti juwe ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP gẹgẹ bii ẹgbẹ agbesunmọni.

Nigba to n gbe idajọ kan kalẹ lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2025 lori ọrọ Douglas Egharevba to n gbiyanju lati ṣatipo nilẹ naa ni ọrọ ọhun jade.

Ṣaaju ni Egharevba ti kọkọ lọ sile ẹjọ lati pe ẹjọ tako bi ijọba ilẹ ọhun ko ṣe fẹ fun ni anfani lati ṣatipo nibẹ.

Adajọ Phuong Ngo da igbẹjọ naa nu latari pe Egharevba ti fi akoko igba kan wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ri, ti ẹgbẹ naa ko si ṣe nnkankan nigba ti awọn alatilẹyin rẹ n ṣeruba araalu.

Minisita to n ri si ọrọ abo araalu nibẹ sọ fun ile ẹjọ ọhun pe ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP kopa ninu oniruru iṣẹlẹ iṣerubalu, iṣekupani atawọn iwa laabi miran, eyii to fara jọ iwa igbesunmọmi.

Akọsilẹ ile ẹjọ ṣafihan pe ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni Egharevba laarin ọdun 1999 si ọdun 2007 ko to darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC to si wa ninu ẹgbẹ naa titi di ọdun 2017.

Igba to ṣipo pada si Canada lọdun 2017 ni ijọba orilẹede naa mọ ọfintoto ẹgbẹ oṣelu to darapọ mọ sẹyin.

Ijọba Canada sọ pe ẹgbẹ oṣelu PDP da ilu ru, bẹẹ ni wọn ji apoti ibo lasiko eto idibo ọdun 2003, bẹẹ ni wọn tun dunkoko mọ araalu lasiko eto idibo ijọba ibilẹ ọdun 2004.

Ijọba Canada gbọdọ ko ọrọ naa jẹ – PDP

Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP ti tako ọrọ ile ẹjọ naa pe ko ri bi wọn ṣe wi.

Nigba to n sọrọ lori ikede naa, ẹgbẹ oṣelu PDP sọ pe ọrọ naa jẹ aṣisọ lati ọdọ ijọba Canada, o si jẹ ọrọ to le ṣi eeyan lọna ati eyii ti wọn ko le fi ẹri kin nidii.

PDP sọ pe ijọba awarawa ni Naijiria ati Canada n lo, to n tumọ si pe ijọba orilẹede mejeji lanfani lati sọrọ bo ṣe wu u amọ eyii ko tumọ si pe ki ijọba kan maa sọ isọkusọ nipa orilẹede mii.

Igbakeji olori ọdọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Timothy Osadolor, sọ fun ileeṣẹ iroyin Vanguard pe ijọba Canada gbọdọ ko ọrọ naa jẹ niwọn igba ti ko si ẹri ti yoo fi kin nidi.

Agbẹnusọ ajọ NNPC tẹlẹ, Olufemi Soneye naa ni ọrọ naa ko dara to ati pe o jẹ eyii to buru jai.

Aimọkan lasan lo mu ki adajọ ọhun sọ bẹẹ - APC

Ni ti APC, wọn ni aimọkan lo n da adajọ naa laamu ti irufẹ ọrọ bẹẹ fi le jade lẹnu rẹ.

Eeekan ẹgbẹ oṣelu APC, Ajibola Basiru sọ pe ẹgbẹ APC ko si ninu awọn to jẹjọ nitori naa lo ṣe lodi fun adajọ ọhun lati jẹ ki ọrọ rẹ ta ba APC ninu idajọ rẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ẹgbẹ oṣelu APC jẹ ẹgbẹ to ṣe e mu yangan lawujọ, awọn ọmọluabi lo si wa ninu rẹ.

Lẹyin naa lo sọko ọrọ si awọn ọmọ Naijiria to n ṣatilẹyin fun ọrọ adajọ ilẹ Canada naa pe ko yẹ ki wọn maa tabuku ilẹ ibi wọn nipa atilẹyin wọn fun irufẹ ọrọ bẹẹ lati ẹnu ijọba ilẹ okere.