Kí ni Ààrẹ Tinubu fẹ́ lọ sẹ ní Japan àti Brazil?

Oríṣun àwòrán, @nosasemota
Oni ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹjọ, ọdun 2025 ni Aarẹ Bola Tinubu yoo rinrinajo lọ silẹ okeere.
Agbẹnusọ Aarẹ, Bayo Onanuga sọ pe Aarẹ yoo lọ si Japan ati Barazil, amọ laarin irinajo naa ni Aarẹ yoo ya si Dubai ko to lọ Brazil.
Ninu ọrọ Onanuga, o ni "ni Japan, Aarẹ yoo kopa nibu eto Tokyo International Conference on African Development (TICAD9) niluu Yokohama laarin ogunjọ si ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹjọ."
Yatọ si eyii, o ni Aarẹ yoo yọju si awọn ipade kan ti yoo waye ṣaaju eto naa nibi ti yoo ti ba awọn ileeṣẹ kan sọrọ nipa bi wọn yoo ṣe dokoowo ni Naijiria.
Nigba ti Aarẹ ba ti kuro ni Japan, o ni yoo morile ilu Brasilia lorilẹede Brazil.
Ni Brazil, Aarẹ yoo wa nibẹ laarin ọjọ kẹrinlelogun si ọjọ karundinlọgbọn oṣu Kẹjọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, Aarẹ yoo tun ṣe awọn ipade to ṣe koko ni Brazil pẹlu awọn ti wọn nifẹ si ati wa ṣowo ni Naijiria.
Ṣe Tinubu fẹ lọ tọju ara rẹ loke okun ni?
Lẹnu ọjọ mẹta yii ni iroyin gbode pe ojojo n ṣogun Tinubu, ati pe ara rẹ ko le.
Amọ lẹyin iroyin naa ni ileeṣẹ Aarẹ tete kede pe ko si ohun to jọ pe Aarẹ n ṣaisan ati pe kokoko ni ara rẹ le.
Wayi o, awọn eeyan kan ti n sọ pe anfani irinajo yii ni Aarẹ fẹ lo lati lọ fi tọju ara rẹ amọ ṣe bẹe lo ri?
Ninu atẹjade ileeṣẹ Aarẹ nipa irinajo Tinubu yii, ko mẹnuba pe Aarẹ n ṣaisan tabi pe niṣe lo fẹ lọ tọju ara rẹ loke okun.
Iya n jẹ araalu, Aarẹ n rinrinjo kiri agbaye – Peter Obi
Ẹwẹ, awọn ọmọ Naijiria kan ti bu ẹnu atẹ lu irinajo Aarẹ ọhun latari bi nnkan ṣe ri lọwọ yii ni Naijiria.
Oniruru orilẹede ni Tinubu ti lọ lati igba to ti gba ọpa aṣẹ ijọba lọdun 2023.
Obi sọ pe ko tọ bi Tinubu ṣe n rinrinajo kaakiri agbaye lasiko to yẹ ko joko sile lati maa gbọ ti araalu.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, laipẹ yii ni Tinubu lọ silẹ Saint Lucia ko to lọ sibi ipade BRICS ti ko si ṣe nnkankan pato nibẹ.
Gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ naa ni "bo tilẹ jẹ pe ọpọ nnkan lo ti dẹnukọlẹ ni Naijiria, Aarẹ wa n tẹsiwaju ninu iwa aikọbiara rẹ si wa.
"Bawo ni a ṣe fẹ ṣalaye pe a ni Aarẹ to ṣẹṣẹ de lati Brazil laipẹ yii tun n pada sibẹ bo tilẹ jẹ oniruru iṣoro la n koju nile lai si ọna abayọ?"
Obi sọ pe lootọ ni Aarẹ ni oun n lọ Brazil ati Japan amọ ko sọ ọjọ pato ti yoo pada wa.
Lẹyin naa lo ni ki Aarẹ Tinubu dẹkun ati maa ṣe bi arinrinajo afẹ.
Wayi o, Aarẹ Tinubu ti rinrinajo lọ ilẹ okeere nigba bii mẹẹdogun o kere tan lati igba to ti gba ọpa aṣẹ Naijiiria.















