Trump kéde ìgbésẹ̀ tó kàn lẹ́yìn tí ìjíròrò pẹ̀lú Iran forí sánpọ́n

Obìnrin tó wọ aṣọ dúdú, tó mú àsíá Iran dání, àwon ọkọ̀ àti ọ̀kadàwà lẹ́yìn rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lẹ́yìn ìjíròrò láàárín Amẹ́ríkà àti Iran forí sánpọ́n ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, Ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump ti kéde ìgbésẹ̀ míì láti fi wá ojútùú sí àwọn ọ̀nà tí ogun fi máa parí.

Trump, nínú àtẹ̀jáde tó fi sórí ìkànnì Truth Social rẹ̀ sọ pé ìjọba máa fi àwọn ológun ojú omi máa di Iran pa.

Amẹ́ríkà ní àwọn kò ní gbà kí ọkọ̀ ojú omi Iran gbé epo jáde ní orílẹ̀ èdè náà, tí wọ́n kò bá ṣí Strait of Hormuz.

Ó kọ sójú òpó náà pé " kò sí ẹni tó máa ọ̀nà tí kò bá òfin mú tó máa gba orí omi láì farapa.

Ó ní Amẹ́ríkà máa bẹ̀rẹ̀ sí ní wà kùsà ní Strait of Hormuz láti ri dájú pé gbogbo àwọn ọkọ̀ ojú omi tó ní ìbáṣe pẹ̀lú Amẹ́ríkà rí ọ̀nà náà gbà kọjá.

Trump ní àwọn ọmọ ogun Amẹ́ríkà ti setán láti bẹ̀rẹ̀ ìkọlù padà sí Iran tí àsìkò bá tó

Trump ní àwọn ọmọ ogun Amẹ́ríkà ni wọ́n ti gbáradì, tí wọ́n sì ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ ìkọlù padà sí Iran tí àsìkò bá tó.

Ó fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìtẹ̀síwájú kan wà, ó ní Iran kọ̀ láti fẹnukò pẹ̀lú Amẹ́ríkà láti dáwọ́ ṣíṣe àdó olóró "nuclear weapon" dúró.

Àmọ́ ọ̀rọ̀ tí Trump sọ yìí tako ohun tí òṣìṣẹ́ Amẹ́ríkà kan tó wà níbi ìjíròrò tí igbákejì Ààrẹ Amẹ́ríkà, JD Vance ṣe pẹ̀lú àwọn asojú Iran ní Islamabad, Pakistan, ẹni tó sọ pé nǹkan ni wọ́n kò fẹnukò lé lórí, tó fi mọ́ àkóso Strait of Hormuz.

Ìdúnkokò Trump yìí ló ń jẹ́ ìpèníjà fun Amẹ́ríkà èyí tó le mú kí àwọn ọmọ ogun Iran ṣe ìkọlù sí wọn.

Onírúurú ìbéèrè tó ti ń jẹyọ ni pé báwo ni àwọn orílẹ̀ èdè bíi China, tí wọ́n ń gbáralé epo rọ̀bì Iran ṣe máa gba ìròyìn yìí? Ṣé ó máa dènà bí owó ṣe ń wọlé fún Iran àti pé ṣé ó máa tún mú kí owó epo rọ̀bì lọ sókè lọ́jà àgbáyé?

Ní alẹ́ ọjọ́ Àìkú ni iléeṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà tún kéde pé ìgbésẹ̀ Amẹ́ríkà náà máa dènà àwọn ọkọ̀ láti gbé epo wọ Iran tàbí gbé epo jáde níbẹ̀.

Aṣòfin Mike Turner ti Ohio sọ pé dídí ọ̀nà mọ́ Iran máa mú kí ìfẹnukò wáyé lórí Strait of Hormuz

Sẹ́nétọ̀ Mark Wagner ti Virginia sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn CNN pé òun kò mọ bí dídí ọ̀nà mọ́ Iran ṣe máa mú àwọn aláṣẹ Iran láti ṣí Strait of Hormuz.

Àmọ́ aṣòfin Mike Turner ti Ohio sọ pé dídí ọ̀nà náà máa jẹ́ ìgbésẹ̀ láti mú kí ìfẹnukò wáyé lórí Strait of Hormuz.

Ó ní ọ̀rọ̀ tí Trump sọ nípa pé àwọn kò ní jẹ́ kí Iran jẹ́ alákòso tó ń ṣàmójútó àwọn tó ń gba ọ̀nà náà kọjá túmọ̀ sí pé, ó ń pe àwọn alábàáṣepọ̀ Amẹ́ríkà láti dá sí ọ̀rọ̀ náà nítorí ó nílò àmójútó.

Ṣáájú kí Amẹ́ríkà àti Iran tó fẹnukò láti dáwọ́ ogun dúró fún ìgbà kan ná, Trump ni ó sọ pé òun máa ṣe ìkọlù sáwọn ohun amáyédẹ̀rùn Iran.

Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn, pàápàá àwọn ara Amẹ́ríkà, ló gbàgbọ́ pé ìdí tí Amẹ́ríkà fi ń gbógunti Iran, tó fi mọ́ ṣíṣí Strait of Hormuz, fífún àwọn èèyàn Iran ní àǹfààní láti gbé ìgbé ayé tó wù wọ́n àti fífi òpin sí ṣíṣe àdó olóró nuclear weapon ni kò wá sí ìmúṣẹ.