Mo sì wà nínú ìrora, mo nílò ìtọ́jú, Comfort tó fa wàhálà pẹ̀lú Ibom Air sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó jáde lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Kirikiri

Aworan Comfort Emmanson

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Comfort Emmanson, ero ọkọ baalu ti faakaja waye laarin rẹ atawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu Ibom Air ti sọ pe oun si wa ninu irora, bo tilẹ jẹ pe oun ti gba itusilẹ lọgba ẹwọn Kirikiri ti ileẹjọ ju oun si.

Lanaa Ọjọru ọjọ kẹtala oṣu Kẹjọ yii ni Comfort gba itusilẹ lọgba ẹwọn nibi ti ko ba wa titi di ọjọ kẹfa oṣu Kẹwaa ọdun yii ti igbẹjọ rẹ ko ba ti waye.

Comfort gba itusilẹ lọgba ẹwọn lẹyin ti ileeṣẹ ọkọ ofurufu Ibom Air gba lati jawọ kuro ninu ẹjọ ati ẹsun ti wọn fi kan an.

Lẹyin to jade lọgba ẹwọn ni Comfort sọrọ loju opo Instagram rẹ pe oun si wa ninu irora nitori bi wọn ti fọwọ lile mu oun.

''Mo nilo itọju bayii ki n to le ṣalaye gbogbo nnkan to ṣẹlẹ gan an.

Bakan naa ni mo tun nilo lati sinmi daadaa latari gbogbo nnkan to ti ṣẹlẹ si mi,'' Comfort lo sọ bẹẹ.

Bi awuyewuye ṣe n lọ lọwọ papaa julọ lori ayelujara nipa faakaja to ṣẹlẹ laarin Comfort atawọn oṣiṣẹ Ibom Air, ohun to jẹ ọdọbinrin naa logun bayii ni itọju ara rẹ.

Ninu ọrọ rẹ to fi lede loju opo Instagram rẹ, Comfort sọ pe ''ẹ ṣeun gbogbo eeyan fun adura, ifẹ ati atilẹyin ti ẹ ti ṣe fun mi.

Mo ti jade kuro lọgba ẹwọn ni toootọ, amọ, mo si wa ninu irora tori bi wọn ṣe fiya jẹ mi.

Mo nilo isinmi ati itọju lọwọ yii ki n to le ṣalaye nnkan to ṣẹlẹ gan an.

Ẹ ṣe gan an ni ẹyin ọrẹ ati gbogbo ẹyin ti ẹ ṣe atilẹyin fun mi, mo dupẹ lọwọ yin lati inu ọkan mi wa.

Ẹ ṣeun, bakan naa ni mo tun dupẹ lọwọ Ọlọrun to ga.''

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Ileeṣẹ ọkọ ofurufu Ibom Air ko tii fesi sọrọ ti Comfort Emmanson sọ loju opo Instragram rẹ.

Amọ, ileeṣẹ naa ti fidi rẹ mulẹ ṣaaju pe ede-ai-yede ṣẹlẹ laarin ero kan atawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu naa, eyi tawọn n yanju labẹnu.

Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu ọhun tun sọ pe awọn ko fi ọrọ awọn onibaara awọn ṣere rara.

Ọpọ eeyan lo ti n sọro lori nnkan ti Emmanson sọ loju opo Instagram rẹ.

Bawọn eeyan kan ṣe n kẹdun pẹlu rẹ lori nnkan to ti la kọja lawọn mii n sọ pe o yẹ ki ijọba ṣe iwadii nnkan to ṣẹlẹ si Comfort nigba ti wa latimọle.

Comfort Emmanson gba ìtúsílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

Ṣaaju l'Ọjọru ọjọ kẹtala oṣu Kẹjọ yii nile ẹjọ majistreeti kan lagbegbe Ikeja, niluu Eko tu Comfort Emmanson silẹ ni ahamọ ọgba ẹwọn lẹyin to da wahala silẹ to si gba oju ọkan lara oṣiṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu Ibom Air niluu Eko.

Adajọ Olanrewaju Salami tu ọdọbinrin naa silẹ lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn ko nifẹ si ati tẹsiwaju ninu ṣiṣẹ ẹjọ ẹsun marun un ọtọtọ ti wọn fi kan an mọ.

Ẹwẹ, ṣaaju igbesẹ yii ni minisita fun ọrọ irinkerinde ọkọ ofurufu ni Naijiria, Festus Keyamo, (SAN), ti kọkọ kede loju opo X rẹ pe ki wọn fi silẹ.

Keyamo sọ pe ọpọ araalu lo ba afurasi naa bẹbẹ, a ti pe o ti mọ ẹjọ rẹ lẹbi lawọn ṣe yọ okun ẹjọ lọrun rẹ.

O fi kun pe ileeṣẹ ọkọ ofurufu Ibom Air naa ti gba lati jawọ kuro ninu ẹjọ ati ẹsun ti wọn fi kan afurasi ọhun.

Ọjọ Aje ọsẹ yii ni Emmanson foju bale ẹjọ, bo tilẹ jẹ pe ile ẹjọ gba beeli rẹ amọ wọn fi si ahamọ ọgba ẹwọn latari pe ko ri ohun to nilo fun beeli ọhun.