Ìjọba sàlàyé ìdí abájọ ipò 'àmbásádọ̀' nípa ọ̀rọ̀ ìrìnnà òfúrufú tó fún KWAM 1, ọ̀pọ̀ èèyàn fọnmú

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọba apapọ ti ṣalaye idi abajọ ipo aṣoju awọn ẹṣọ eleto abo papakọ ofurufu ti wọn fun gbajugbaja olorin Fuji, King Wasiu Ayinde Marshal, ti ọpọ mọ si KWAM 1 latari faakaja to waye laarin ilumọọka akọrin naa atawọn oṣiṣẹ ileesẹ ọkọ ofurufu ValueJet niluu Abuja.
Lanaa Ọjọru ọjọ kẹtala oṣu Kẹjọ yii ni minisita to n ri si eto irinna ọkọ ofurufu ni Naijiria, Festus Keyamo (SAN), sọ loju opo X rẹ pe ijọba yoo fun KWAM 1 ni ipo aṣoju awọn ẹṣo eleto abo papakọ ofurufu.
Keyamo sọrọ yii lẹyin to kede wi pe ajọ NCAA to n ṣakoso ẹka eto irinna ọkọ ofurufu ni Naijiria ti fagile ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan KWAM 1 lọdọ awọn ọlọpaa tori o huwa pẹlẹ bi Ọmọluabi lati ti igba iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Bakan naa ni minisita tun kede pe adinku ti ba ijiya gbajugbaja akọrin naa eyi ti ajọ NCAA fofin de e tẹlẹ wi pe ko gbọdọ wọ baalu ni Naijiria fun oṣu mẹfa.
Keyamo ṣalaye pe ijiya naa ti di oṣu kan pere bayii nitrori bi KWAM 1 ṣe huwa pẹlẹ ti o si tọrọ aforijin.
Minisita sọ pe ọpọ awọn alẹnulọrọ lawujọ lo ba Wasiu Ayinde bẹbẹ lori bi o ṣe duro siwaju baalu ValueJet pe ko ni gbera ayafi ti wọn ba jẹ koun wọle.
Amọ, ọpọ ọmọ Naijiria lo bu ẹnu atẹ lu igbesẹ yii papaa julọ lori itakun ayelujara.
Pupọ ninu awọn eeyan yii sọ pe ijọba n ṣegbe lẹyin KWAM 1, lẹyin ti ilẹ ẹjọ ju Comfort Emmanson ti faakaja waye laarin oun naa atawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu Ibom Air si ẹwọn ni Kirikiri.
Ṣugbọn Keyamo kede pe ijọba ti fagile ẹsun ti wọn fi kan Comfort naa, o si ti gba itusilẹ lọgba ẹwọn lati ana Ọjọru.
''Kaakiri agbaye ni wọn ti maa n fun arufin to ti ronu piwada nipo aṣoju''
Ninu ọrọ rẹ, Keyamo ṣalaye wi pe ''kaakiri agbaye ni wọn ti maa n yan ẹni to ba ru ofin sipo ti yoo fi maa ṣe ilanilọye fawọn araalu lori nnkan to ṣe ti o si ti ronu piwada lori rẹ.
Eyi dabi ki eeyan maa ṣisẹ sin awujọ naa ni ti ileẹjọ maa n sọ pe kawọn eeyan kan ṣe.
Iru ipo aṣoju bayii ko lowo ninu, iṣẹ ọfẹ ni, amọ, o ṣeni laanu wi pe ọpọ ọmọ Naijiria lo ro pe ipo aṣoju nii ṣe pẹlu ọfiisi nla ati oriṣiiriṣii ajẹmọnu.
Eyi ko rii bẹẹ rara, ọfẹ ni, kii ṣe igba akọkọ ti iru nnkan bayii yoo ṣẹlẹ ni Naijiria niyii; ko si ni jẹ igba tii yoo ṣẹlẹ kẹyin niyii.
Ijọba ti fun ọpọlọpọ eeyan ni iru ipo yii lorilẹede Naijiria ṣaaju.''
Eto n lọ lọwọ lati fun Comfort naa nipo
Eto n lọ lọwọ lati fun Comfort naa nipo aṣoju ero ọkọ baalu - Keyamo

Oríṣun àwòrán, Others
Minisita to n ri si eto irinna ọkọ ofurufu ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu n gbero lati yan Comfort Emmanson naa sipo aṣoju ero ọkọ baalu nitori bii o ti huwa daadaa ti o si mọ ẹjọ rẹ lẹbi.
''Bi ajọ to n ri si eto irinna ọkọ ofurufu ṣe fẹ yan KWAM 1 sipo aṣoju awọn ẹṣọ papakọ ofurufu lawọn alaṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu naa fẹ yan Comfort sipo aṣoju ero ọkọ baalu fun bi o ti gba ẹjọ rẹ lẹbi.
Ẹgbẹ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu yii yoo kede ohun ti wọn fẹ ṣan gan an fun Comfort,'' Keyamo lo sọ bẹẹ.
Minisita ni ijọba ko ṣegbe lẹyin ẹnikankan ninu gbogbo iṣẹlẹ to ṣẹlẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ìdí tí ìjọba fi fagilé ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kan Kwam 1, mú àdínkù bá ìjìyà rẹ̀
Bi awuyewuye sẹ n lọ lọwọ lori faakaja to waye laarin agbaọjẹ olorin Fuji, King Wasiu Ayinde Marshal (Kwam 1), minisita to n ri si eto irinna ọkọ ofurufu, Festus Keyamo (SAN) ti kede pe adinku ti ba ijiya agba orin naa lati oṣu mẹfa si oṣu kan gẹgẹ bii ijiya rẹ.
Ninu atẹjade kan ti minisita naa fi lede loju opo X rẹ lo ti sọ pe ajọ NCAA yoo mu adinku ba iye igba ti Kwam 1 eyi ti ko ni jẹ ko lanfaani lati wọ baalu ni Naijiria lati oṣu mẹfa si oṣu kan gẹgẹ bi ijiya fun faakaja to ṣẹlẹ laarin rẹ atawọn oṣiṣẹ Ibom Air.
Keyamo tun sọ ninu atẹjade naa pe ajọ FAAN yoo tun ṣiṣẹ pọ pẹlu agbaọjẹ olorin naa lati le sọ ọ di aṣoju awọn eṣọ eleto abo ni papakọ ofurufu ni Naijiria.
Lẹyin to ti huwa pẹlẹ bi Ọmọluabi, ajọ NCAA yoo fagile ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan Kwam 1 lọdọ awọn ọlọpaa.
Lori ọrọ awakọ baalu ValueJet, Cpt Oluranti Ogoyi, ati akẹgbẹ rẹ, Ivan Oloba, ajọ NCAA yoo da iwe ẹri wọn pada lẹyin oṣu kan bakan naa.
Keyamo sọ pe eyi yoo ṣẹlẹ lẹyin ti wọn ba ti ṣe awọn ayẹwo kan fun wọn tan.
Keyamo ni ajọ NCAA yoo kede ẹkunrẹrẹ gbogbo igbesẹ yii.















