Ǹ jẹ́ o mọ pàtàkì Ọjọ́ Àràfá fún àwọn mùsùlùmí?

Oríṣun àwòrán, HARAMAIN
Oni, tii se Ọjọ Kẹdogun osu Kẹfa ọdun 2024 ni ọjọ Arafa fun ọdun yii.
Ọjọ Arafa ni ọjọ kẹsan oṣu Zul-Hijjah, ni onka oṣù ojú ọrun.
Ní ayajọ oni ni awọn Alhaji ati Alhaja tuntun máa ń kórajọ pọ sí oke Arafat tó wà ní ìlú Makkah lọdọdún.
Lati igba ti irun aila ba ti to, titi di ìgba tí oorun ba ti wọ, ni wọn yoo maa gun oke Arafa, lati ṣe ọkan lara awọn koko iṣẹ hajj naa.
BBC ṣe ifọrọwerọ pẹlu agba Alfa ẹsìn Islam kan ní Naijiria, Ọmọwe Ibrahim Disina, lori awọn nnkan to se pataki to yẹ ki awọn eeyan ṣe ni ọjọ Arafa.
Awọn nnkan marun-un to se koko nipa lọjọ Arafa:
Ọlọrun sọ ofin ẹsin Islam kalẹ:
Ni iru ayajọ ọjọ yii lasiko hajj idagbere laye Anabi Muhmmad (S.A.W.), ni Ọlọrun pari sísọ awọn ofin ẹsin Islam kalẹ.
Lati ọjọ naa, ko si ìdajọ kan to sọkalẹ mọ, eleyii gan lo faa tí Sayyidina Umar fi sọ pe:
"Nitori ajulọ to wa fun ọjọ yii, to ba jẹ awọn Yahudí ni, ki sọ ọjọ yii di ọjọ tí wọn o maa ṣe ayẹyẹ lọdọdun",
Gẹgẹ bí Ọlọrun ṣe gba ẹmí Anabi Muhammad (S.A.W.) ní ọjọ kọọkanlelọgọrin lẹyìn ìgbà náà.
Adura lori oke Arafa lo lọla julọ:

Oríṣun àwòrán, HUJJAJ IN MASJID AL NAMIRAH, ARAFAT
Gbigba adura nígba tí eeyan ba wa l'Arafat ni adura to lọla ju lagbaye.
Gẹgẹ bí Annabi (S.A.W) se sọ pe "Àdura to lọla ju ni adura tí wọn ṣe lọjọ Arafat"
Ọlọrun maa n yọ awọn eeyan kuro ninu ọmọ ina:
Ní ọjọ Arafat ni Ọlọrun maa n yọ awọn eeyan kuro nínu ọmọ ina julọ.
Eleyii wa ninu ẹgbawa ọrọ Imam Muslim pe: Anabi (S.A.W) sọ pe:
"Ko sí ijọ tí Ọlọrun maa n yọ àwọn eeyan kuro ninu ọmọ ina bíi ọjọ Arafa"
Aawẹ ọjọ Arafa maa n pa ẹsẹ rẹ:
Gbígba aawẹ lọjọ Arafa maa n pa ẹṣẹ oṣu mejì rẹ, gẹgẹ bí Anabi (S.A.W) ti sọ:
"Àwẹ ọjọ rana Arafat maa n pa awọn ẹṣẹ ọdun to kọja ati ti ọdun to n bọ."
Muslim lo gba ọrọ yii wa bakan naa.
Ọlọrun maa n fi awọn Alhaji to wa ni Arafa yangan lọrun:

Oríṣun àwòrán, @YASIRQADHI
Ọlọrun maa fi awọn Alhaji to lọ sí Arafat yangan Arafat ní ọjọ yìí.
Imam Ahmad gba ẹgbawa ọrọ wa pe: Anabi ni: "Ọlọrun maa n fi awọn to lọ sí Arafa yangan loju awọn to wa lọrun. "
Hajj: Ǹjẹ́ o mọ pàtàkì Ọjọ́ Àràfá fún àwọn mùsùlùmí?
Ọjọ Arafa bọ si Ọjọ Kẹsan ti awọn musulumi n pe ni Dhul-Hajjah, to jẹ ọjọ keji Hajj.
Ọjọ nla ni Ọjọ yii jẹ ninu irinajo awọn musulumi lọ si ilu Mecca, ilẹ mimọ, to si jẹ ọkan ninu awọn ọjọ to se pataki si wọn.
Ti oorun ba ti jade ni ọjọ yii, ni awọn musulumi ti wọn lo bi ilẹ mimọ yoo bẹrẹ irinajo lọ si Oke Arafa to wa ni Mecca.
Ki ni idi ti Ọjọ Arafa fi se pataki si awọn musulumi?
Ọjọ Arafa ni ọjọ to kangun si ọjọ Eid-al-Adha, iyẹn Ọjọ Ileya, eleyii ti wọn ma n se ni aadọrin ọjọ lẹyin ọdun Ramadan.
Ọjọ yii jẹ ọjọ ti ẹsin Musulumi gba ibukun ati ire lẹnu Allah gẹgẹ bi ẹsẹ Iwe Mimọ Quran ti kọ silẹ.
Ọjo Arafa ni Ọjọ keji Hajj ti awọn musulumi jakejado agbaye to lọ si Mecca yoo gun oke aanu arafa to sun mọ Makkah.
Oke Arafah ni Ojisẹ Allah, Mohammed se ẹsiin ati iwaasu ikẹyin to fi ki wọn pe o digba kan naa.
Ni Ọjọ Arafa, awọn musulumi ti ko le e lọ si Mecca, ma n gba aawẹ ati adura, nigba ti awọn to lọ si oke Arafa yoo fi gbogbo ọjọ naa gba adura.
Ọjọ Arafa jẹ ọjọ ti awọn musulumi ya sọtọ patapata lati gba adura fun idariji ẹsẹ ti ọdun to kọja ati eleyii ti n bọ.















