Ìdí tí ìjọba fi fagilé ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kan Kwam 1, mú àdínkù bá ìjìyà rẹ̀

Oríṣun àwòrán, K1 De Ultimate/Instagram
Bi awuyewuye sẹ n lọ lọwọ lori faakaja to waye laarin agbaọjẹ olorin Fuji, King Wasiu Ayinde Marshal (Kwam 1), minisita to n ri si eto irinna ọkọ ofurufu, Festus Keyamo (SAN) ti kede pe adinku ti ba ijiya agba orin naa lati oṣu mẹfa si oṣu kan gẹgẹ bii ijiya rẹ.
Ninu atẹjade kan ti minisita naa fi lede loju opo X rẹ lo ti sọ pe ajọ NCAA yoo mu adinku ba iye igba ti Kwam 1 eyi ti ko ni jẹ ko lanfaani lati wọ baalu ni Naijiria lati oṣu mẹfa si oṣu kan gẹgẹ bi ijiya fun faakaja to ṣẹlẹ laarin rẹ atawọn oṣiṣẹ Ibom Air.
Keyamo tun sọ ninu atẹjade naa pe ajọ FAAN yoo tun ṣiṣẹ pọ pẹlu agbaọjẹ olorin naa lati le sọ ọ di aṣoju awọn eṣọ eleto abo ni papakọ ofurufu ni Naijiria.
Lẹyin to ti huwa pẹlẹ bi Ọmọluabi, ajọ NCAA yoo fagile ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan Kwam 1 lọdọ awọn ọlọpaa.
Lori ọrọ awakọ baalu ValueJet, Cpt Oluranti Ogoyi, ati akẹgbẹ rẹ, Ivan Oloba, ajọ NCAA yoo da iwe ẹri wọn pada lẹyin oṣu kan bakan naa.
Keyamo sọ pe eyi yoo ṣẹlẹ lẹyin ti wọn ba ti ṣe awọn ayẹwo kan fun wọn tan.
Keyamo ni ajọ NCAA yoo kede ẹkunrẹrẹ gbogbo igbesẹ yii.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Naijiria pàṣẹ ìwádìí fáákákája tó ṣẹlẹ̀ láàrin Kwam 1 àtàwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ bàálù Valuejet
Ṣaaju ni ọga agba ọlọpaa ni Naijiria, Kayode Egbetokun, paṣẹ iwadii iṣẹlẹ faakaja to ṣẹlẹ laarin Kwam 1 atawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu ValueJet ni papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe Airport niluu Abuja.
Eyi waye lẹyin ti ajo NCAA to n ri si irinna ọkọ ofurufu ni Naijiria kọwe pe ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣe iwadii nnkan to ṣẹlẹ gan an.
Lara ẹsun ti wọn fi kan Kwam 1 ni pe o da ọti si awọn oṣiṣẹ ọkọ baalu lara ni papakọ niluu Abuja, lọjọ Iṣẹgun ọsẹ to kọja.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Olumuyiwa Adejobi, ṣalaye ninu atẹjade to fi sita pe ajọ NCAA tun fẹsun kan Kwam 1 pe o huwa aigbọran eyi to ṣakoba fun fawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu ValueJet lẹnu iṣẹ wọn lọjọ karun un oṣu Kẹjọ yii ni papakọ ofurufu ilu Abuja.
Ninu esi rẹ ni ọga ọlọpaa Egbetokun ti paṣẹ wi pe ki ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni papakọ ofurufu ilu Abuja bẹrẹ iwadii iṣẹlẹ naa lẹsẹ kẹsẹ ki wọn si ri pe idajọ ododo waye lori ọrọ naa.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria fi sita lọjọ Iṣẹgun ni ọga ọlọpaa ti paṣẹ ọhun.
Adejobi sọ ninu atẹjade naa pe ileeṣẹ ọlọpaa koni beṣu bẹgba lati pese abo to peye lẹka ileeṣẹ ọkọ ofurufu.
''ileeṣẹ ọlọpaa n fi dawọn eeyan to n ṣiṣẹ lẹka ileeṣẹ ọkọ ofurufu ni Naijiria loju pe eto abo yoo gbe pẹẹli si lẹka naa.
A o si ri pe awọn eeyan bọwọ fun ofin to de irinna ọkọ ofurufu lorilẹede Naijiria,'' Adejobi lo sọ bẹẹ.
Faakaja naa waye nigba ti Wasiu Ayinde fẹ wọ baalu ValueJet lati ilu Abuja lọ si Eko pẹlu igo kan lọwọ rẹ.
Igo to wa lọwọ rẹ yii tawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu ValueJet ro pe ọti lo wa ninu rẹ ni wọn sọ pe ko le gbe wọ baalu tori o lodi sofin irinajo ọkọ ofurufu ni Naijiria.
Lẹyin naa ni K1 ni fariga pe oun maa gbe igo naa wọ baalu ni ti o si fi ibinu duro siwaju baalu naa.
Lẹyin eyi ni ajọ NCAA fofin de awakọ baalu naa, Oluranti Ogoyi, ati akẹgbẹ rẹ, Ivan Iloba, wi pe wọn o gbọdọ wa baalu mọ fun igba kan, nigba ti ajọ naa tun kede pe akọrin Fuji naa ko gbọdọ wọ baalu ni Naijiria fun oṣu mẹfa nigba ti iwadii si n lọ lọwọ.
Bo tilẹ jẹ pe Kwam 1 ti tọrọ aforijin, ọpọ ọmọ Naijiria lo ti n pe fun idajọ ododo lori ọrọ naa lẹyin ti ileẹjọ ju Comfort Emmanson si ọgba ẹwọn Kirikiri lori ẹsun pe o huwa ipa sawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu Ibom Air.
Ìdí tí Tinubu fi gbọdọ̀ foríjin Kwam 1 bíi ọmọ onínàákúnàá - MC Oluomo

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ ẹgbẹ awọn awakọ ni Naijiria NURTW, Musilu Akinsanya, ti ọpọ mọ si MC Oluomo ti rawọ ẹbẹ si Aarẹ Bola Tinubu wi pe ko forijin gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Ayinde Marshal, tawọn eeyan mọ si Kwam 1 lori ẹsun wi pe o tapa sofin to n dari eto irinna ọkọ ofurufu.
Ẹsun mii ti wọn fi kan Kwam 1 ni pe o da eto ileeṣẹ baalu ValueJet ru.
Ajọ FAAN to n ṣakoso irinna ọkọ ofurufu ni Naijiria fẹsun kan ilumọọka olorin naa pe o ṣe awọn nnkan yii nigba to fẹ wọ baalu ValueJet pẹlu nọmba (Flight VK 201) lati Abuja si ilu Eko.
Ninu atẹjade kan ti Obiageli Orah to jẹ agbẹnusọ FAAN buwọlu ni ajọ naa ti fẹsun kan Kwam 1 pe o fẹ wọ baalu pẹlu ọti lile lọwọ rẹ, eyi to lodi sofin to n dari irinajo ọkọ ofurufu ni Naijiria.
Ajọ FAAN ni eyi lo jẹ ki ede-ai-yede bẹ silẹ laarin Wasiu Ayinde ati oṣiṣẹ ileeṣẹ baalu ValueJet kan.
Lẹyin naa ni ajọ NCAA ati minisita to n ri si ọrọ irinajo ọko ofurufu ni Naijiria, Festus Keyamo, dasi ọrọ naa ti wọn si fofin de Wasiu fun oṣu mẹfa wi pe ko gbọdọ wọ baalu yala laarin orilẹede Naijiria tabi si ilẹ okeere bi iwadii ṣe n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa.
Kwam 1 ti mọ ẹjọ rẹ lẹbi - MC Oluomo
Amọ, MC Oluomo ti rawọ ẹbẹ si Tinubu wi pe ko fiye denu ki o si darijin Kwam 1 atawọn mii ti ọrọ ti iṣẹlẹ naa kan.
MC Oluomo fi ọrọ yii lede loju opo Instagram rẹ.
''Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, emi Alhaji Musiliu Ayinde Akinsanya, ti mo jẹ aarẹ ẹgbẹ onimọto ni Naijiria, NURTW fi tọwọtọwọ bẹbẹ fun idarijin Alhaji Wasiu Ayinde Marshal (K1).
K1 ti mọ ẹjọ rẹ lẹbi, o ti tọrọ aforijin, o si ti ṣetan lati ṣe atunṣe.
Mo fi irẹlẹ kepe ọga agba ajọ NCAA, Ọgagun Chris Najomo ati Minisita to n ri si irinajo ọkọ ofurufu, Festus Keyamo (SAN) lati gbẹsẹ kuro lori ofin ti wọn fi de Kwam 1 ati awakọ baalu tọrọ kan, Oluranti Ogoyi latari iṣẹlẹ to ṣẹlẹ ni papakọ ofurufu ilu Abuja.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
''Mo kábàámọ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n ọtí kọ́ ni mo rọ sí ife ìmumi mi''
Lẹyin ti iṣẹlẹ yii ti kari ayelujara, ti ajọ to n ri si irinna ofurufu ni Naijiria si ti fi ofin de olorin Fuji yii pe ko gbọdọ wọ baaluu fun oṣu mẹfa lo gbe igbesẹ aforiji.
Atẹjade ni Wasiu fi sita to fi tọrọ aforiji lọwọ gbogbo awọn ti ọrọ naa kan, bẹẹ lo ni oun kabaamọ rẹ.
Bakan naa lo ni omi lo wa ninu ife imumi toun gbe dani, ọti kọ.
" Ọpọ eeyan ni ko mọ pe ara mi maa n gbẹ gan-an, dokita mi si ti gba mi nimọran lati maa mu omi deede.
"Eyi lo fa a ti mo fi maa n gbe nnkan imumi dani nigba gbogbo.
"Fun awọn ti wọn n sọ ohun ti ko ṣẹlẹ, omi ni mo gbe dani lọjọ yẹn, ọti kọ bi wọn ṣe n gbe irọ kiri.
" Gẹgẹ bi ẹri, ayẹwo awọn ẹṣọ papakọ naa meji ni mo ti la kọja nigba ti ko si nnkan kan ninu ife imumi mi.
"Igba ti mo de abala ibi ti won ti maa n naju ni papakọ naa ni mo rọ omi si i.
"Wọn le fi ẹrọ to n ka aworan silẹ nibẹ wadi eyi. Mi o si ti i wọ baaluu naa, ka ma ti i ṣọ pe wọn wa ja mi bọ silẹ ninu ẹ.
"Ṣugbọn mo gba ẹbi mi ninu ọrọ naa, mo si kabaamọ ohun to ṣẹlẹ. Ko wu mi lati tapa si ofin irin ajo nibi kankan. "
Bẹẹ ni apa kan atẹjade ti Wasiu buwọlu naa wi.















