Agbéṣùmọ̀mí kọ lẹ́tà sáwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Katsina, bèèrè màlúù 700, àgùtàn 1,000

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Inu ibẹrubojo lawọn eeyan ijọba ibilẹ Kankia, nipinlẹ Katsina wa bayii lẹyin ti awọn agbesunmọmi fun wọn ni ọjọ mẹfa pere lati pese maluu 700 ati agutan ẹgbẹrunkan fun wọn ki wọn ma baa kọlu wọn.
Ibeere yii lo wa ninu lẹta kan ti awọn agbesunmọmi naa fi ṣọwọ si awọn ilu ti ọrọ naa kan lọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun 2026 ti a wa yii.
Awọn agbesunmọmi ọhun sọ pe awọn eeyan naa gbọdọ ṣe nnkan ti wọn bere fun ko to to di ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun 2026.
Lẹta naa da ipaya sọkan awọn eeyan lawọn ilu bii Sukuntuni, Unguwar Tsamiya, Magama, Walawa, ati Tudun Wulli, koda, a gbọ pe ni ṣe lawọn agbesunmọmi n yan fanda kaakiri awọn ilu ọhun lori alupupu.
Olugbe ọkan lara awọn ilu naa ti ko fẹ fi orukọ ara rẹ lede ṣalaye fun awọn akọroyin pe gbedeke ti wọn fun awọn lo n waye lẹyin ti wọn ti kọkọm dunkoko mọ awọn lọpo igba ti wọn tun ji ọpọ awọn eeyan wọn gbe lọ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọkan lara awọn olori ọdaran naa ti kọkọ ko ọpọ maluu lọ lẹyin ija to waye laarin rẹ ati akẹgbẹ rẹ kan, lẹyin naa ni wọn bẹrẹ si n bere owo ori lọwọ awọn eeyan naa.
O ni "Iṣẹlẹ naa ti mu ki ọpọ awọn eeyan wa salọ, awọn mii ti ko lọ si Rimaye.
"Awọn kan salọ si Kano, nigba ti awọn miii ko lọ siluu Katsina. Ilu bii mẹwaa lo ti dahoro bayii."
Ẹwẹ, ọpọ araalu lo ti n kọminu lori ipa ti ijiroro ati idunadura ti ijọba ni pẹlu awọn agbesunmọmi naa latẹyin latari bi ko ṣe so eso rere kankan.
Wayi o, agbẹnusọ ijọba ipinlẹ naa, Malam Maiwada Dan-Mallam ti ke si awọn eeyan ijọba ibilẹ ọhun ki wọn ṣe surru.
O ni o ṣeeṣe ko jẹ pe awọn kọlọrọsi ẹda kan lo mọọmọ kọ lẹta naa lati fi da wahala silẹ lawujọ.
Amọ ṣa, bo tilẹ jẹ pe ijọba ni ki awọn eeyan lọ fi ọkan balẹ, inu ibẹrubojo lawọn eeyan ijọba ibilẹ ọhun wa bayii, ojojumọ lawọn eeyan si n fi ilu silẹ.

























