Kókó nípa ìgbé ayé Aduke Gold lẹ́yìn ọdún kan tó jáde láyé

Aworan Aduke Gold

Oríṣun àwòrán, Aduke Gold/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọjọ a ba ku laa dere, eeyan o ṣunwọn laaye, o ti pe ọdun kan bayii ti gbajugbaja akọrin ẹmi, Aduke Ajayi ti ọpọ mọ si Aduke Gold jade laye.

Aduke Gold, naa ri awọn iriri aye nla, o gbiyanju iwọn to le ṣe ko too di ẹni ti aye mọ.

Ohun to n dun ọpọ awọn ololufẹ rẹ nipa iku ọdọmọbinrin to di oloogbe naa ni pe o koju awọn ipenija pupọ lati kekere.

Nigba to si ṣẹṣẹ fẹẹ maa jẹ ọrọ awọn ijiya naa ni iku mu u lọ.

Diẹ ree lara ohun to jẹ koko ninu ilakaka ati igbiyanju Aduke Gold, ẹni to jade laye ni rewerewe ree, gẹgẹ bo ṣe fi ẹnu ara rẹ sọ ọ lawọn asiko to n ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu awọn akọroyin.

Ọmọ ọdun mẹrin ni Aduke Gold wa ti iya ati baba rẹ fi ku, ori ẹja to n ko lọdọ awọn onisowo ẹja lo fi n jẹun

Ilu Ilesa, nipinlẹ Osun ni wọn ti bi Aduke Ajayi, ọmọ ọdun mẹrin lo wa to ti padanu awọn obi rẹ mejeeji.

O ti figba kan ri kiri awọn ọja bii bata awọyilẹ (slippers), ẹja gbigbẹ ati iṣu.

Bi Aduke ṣe jẹ alailẹnikan ni kekere to, bẹẹ lo tun ni aisan kan to maa n jẹ ko daku lọpọ igba, ko too di pe o ri iwosan si eyi.

Igba kan wa to jẹ ori ẹja ni ọmọbinrin yii maa n lọ ko lọdọ awọn to n ta ẹja tutu.

O ni awọn maa n purọ fun awọn ẹlẹja naa pe aja lawọn fẹẹ ko o fun, bẹẹ, ohun ti oun yoo jẹ niyẹn.

Aduke Penkẹlẹ lo kọkọ n jẹ nigba to bẹrẹ iṣẹ orin nitori eeyan lẹgẹlẹgẹ to fẹlẹ lori itage ni.

Idi ti Aduke ṣe pa orukọ da kuro ni Aduke Pẹnkẹlẹ si Aduke Gold

Oṣere tiata n ni, Gbenga Adewusi ti awọn eeyan mọ si Baba Itunu, lo maa n gbe Aduke Penkele wa si ori eto to n ṣe lorii tẹlifiṣan ipinlẹ Eko ni nnkan bii ogun ọdun sẹyin.

Ori eto naa ni Aduke ti di mimọ fun aye, to si tun n kọrin nibi awọn isọji ṣọọṣi pẹlu awọn eto to ba fi ara pẹ ẹ.

Orin to kọ nibi isinku Baba Ara, olorin ẹmi, tubọ jẹ ko di mimọ.

Nigba ti okiki Aduke Pẹnkẹlẹ bẹrẹ si i kan, lo yi orukọ naa pada si Gold.

O sọ nigba naa pe ohun ti eeyan ba pe mọ ara rẹ ni yoo ṣẹlẹ si i.

Ọmọbinrin naa ni oun ko fẹ pẹnkẹlẹ ti i ṣe ayederu mọ, Gold ti i ṣe wura loun fẹẹ ki aye maa pe mọ oun lọ.

Opeyemi Bamidele, agba oloselu, lo fun Aduke Gold ni anfaani ẹkọ ọfẹ to fi lọ si Fasiti

Aworan Aduke Gold

Oríṣun àwòrán, Aduke Gold/Instagram

Oloogbe Aduke Gold ri anfaani ẹkọ ọfẹ lati lọ si yunifasiti, nigba ti Ọnarebu Opeyemi Bamidele, kọmiṣọ́nna fun ọrọ awọn ọdọ ati ere idaraya nipinlẹ Eko nigba naa, fun ni ẹkọ ọfẹ.

Yunifasiti ipinlẹ Eko, (LASU) ni Aduke ti gboye ninu imọ nipa ibaṣepọ ilẹ okeere (International Relations).

Ọmọbinrin yii tun lọọ kẹkọọ nipa awọn ọmọde, o si gba ami ẹyẹ Diploma lati orilẹede United Kigdom.

Oloogbe Aduke Gold kẹkọọ nipa awọn akanda eeyan, nipa itọju ati ọsin ẹja, o kọ nipa iṣẹ olópò ati akara oyinbo ṣiṣẹ, yatọ si iṣẹ orin to sọ ọ di olokiki.

Aduke Gold lo kọ orin Abọru-Bọye to fa awuyewuye taye n se pẹlu Tope Alabi lori ayelujara

Orin 'Mo di ẹbọ', Abọru-abọye ti oun pẹlu Tope Alabi jọ kọ gbẹyin, di ohun ti awọn eeyan n tori ẹ sọrọ si Tọpẹ nigba naa.

Ṣugbọn Aduke Gold dahun nigba naa pe ki ẹnikẹni ma ṣe bu Tọpẹ Alabi.

O ni oun loun kọ orin naa, oun kan pe Tọpẹ Alabi lati ba oun ṣe ere naa papọ loju agbo ni.

Oloogbe yii sọ pe ki wọn maa darii gbogbo eebu wọn si ọdọ oun lo daa ju, nitori yoo jẹ ki ogo oun tun bu yọ si i ni.

Ọkan lara orin rẹ to ṣe lo pe ni Nitori ogo.

O yanna-na ogo ati ohun ti oju ologo yoo ri ko too depo ogo ọhun.

Ogo ti ko ni i wọ lokunkun.

Awọn orin rẹ mi-in ni: Ọlọrun de, Adura, Gbe mi ga, Ẹnikan Pere, Shina Ayọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ọjọ Aje, ọjọ kejila, oṣu kẹjọ, ọdun 2024 ni okiki kan, pe irawọ oṣere ti ko ti i dagba rara naa ti jẹ ipe Ọlọrun.