Igbákejì akọ́nimọ̀ọ́gbá 3SC, Akin Olowokere jáde láyé

Oríṣun àwòrán, x/@TelegraphNG
Akin Olowookere, to jẹ igbakeji akọnimogba ẹgbẹ agbabọọlu 3SC, ti ọpọ eeyan mọ si Shooting Stars ti ilu Ibadan ti jade laye.
Akin Olowookere ni ẹgbẹ agbabọọlu 3SC ṣẹṣẹ fivlede gẹgẹ bii igbakeji akọnimọọgba ikọ ọhun lọjọ mẹta sẹyin.
BBC Yoruba fidi rẹ mulẹ pe o ṣubu lakoko ti awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu 3SC n ṣe igbaradi ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ kan ti yoo waye lọla ọjọ Iṣẹgun nilou Ijebu-Ode, nibi ti wọn ti n gba ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹẹ ti Value Jet lọwọ.
Awọn ti iroyin naa ṣoju wọn ni, kete ti Olowookere ṣubu, nisẹ ni wọn gbe lọ si ile iwosan to si padanu ẹmi rẹ ṣaaju ki wọn to gbe de ile iwosan naa.
Ṣaaju ko to darapọ mọ 3SC, Olukọni Olowookere ṣiṣẹ gẹgẹ bii oluranlọwọ olukọni ti ikọ agbabọọlu Sunshine Stars FC, ti ilu Akure, nipinlẹ Ondo.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
O tukọ ikọ agbabọólu Sunshine Stars nigba ti Austin Eguavoen fi iṣẹ naa silẹ lọdun 2017.
Olowookere lo ti gba bọọlu pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Sunshine Stars ti ilu Akure ko to fẹyinti to si ṣiṣẹ gẹgẹ bii igbakeji akọnimọọgba Edith Agoye.
A ṣẹṣẹ n ko iroyin yii jọ ni, a o maa fi iryoku rẹ to yin leti laipẹ.















