Frank Mba, Mohammed Gumel àti àwọn míì tó ṣéésé kí wọn fípò silẹ̀ nítorí Tunji Disu, adelé ọ̀gá Ọlọ́pàá tuntun ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Nigeria police force
Aarẹ Bola Tinubu, lọjọ Iṣẹgun yan Tunji Disu gẹgẹ bii adele ọga ọlọpaa Naijiria tuntun lẹyin ti Kayode Egbetokun kọwe fi ipo silẹ.
Oludamọran Aarẹ Bola Tinubu lori eto iroyin, Bayo Onanuga, lo fidi ọrọ naa mulẹ ninu atẹjade to fi sita.
Onanuga ṣalaye pe Tinubu yan Disu gẹgẹ bi adele ọga ọlọpaa Naijiria tuntun lẹyin ti Egbetokun kọwe fipo silẹ, igbesẹ to ni oun gbe nitori ẹbi oun.
Aarẹ Tinubu tẹwọ gba igbesẹ Egbetokun lati kọwe fipo silẹ, lẹyin to sọ pe nitori ẹbi oun loun fi ṣe bẹẹ.
Disu ti wa ni ipo igbakeji ọga ọlọpaa Naijiria fun bi igba kan ṣaaju tẹlẹ, ki o to de ipo ọga agba ọlọpaa.
Ni orilẹede Naijiria, ko ki n ṣe nnkan tuntun ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa, awọn ọga ma n fi iṣẹ silẹ tabi ki wọn fẹyinti kete ti wọn ba yan ẹni to kere si wọn gẹgẹ bii ọga fun ileeṣẹ ọlọpaa.
A ṣe akọsilẹ awọn ọga DIGs ti wọn yoo nilo lati kuro fun Tunji Disu lati di ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa.
- Frank Mba
Frank Mba bẹrẹ irinajo rẹ ninu iṣẹ ọlọpaa gẹgẹ bi insipẹtọ, to si n gun oke si. Ni ọdun 1999, wọn fikun ipo rẹ, to si bọ Assistant Superintendent, to si tun bọ si Deputy Superintendent ni ọdun 2003.
Ni ọdun 2014, o di igbakeji fun kọmisana ọlọpaa, to si di kọmisana fun ileeṣẹ ọlọpaa ni oṣu kejila ọdun 2020. Ni oṣu kẹta ọdun 2023, o tun bọ si ipo igba keji ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa
- Mohammed Gumel
Mohammed Gumel bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bii 4th igbakeji insipẹko ọga agba ọlọpaa ni olu ileeṣẹ niluu Abuja ni ọdun to kọja.

Oríṣun àwòrán, nigeria police force
- Adebola Hamzat
Adebola Hamzat wa lati ijọba ibilẹ Ifelodun nipinlẹ Kwara, fi igba kan jẹ kọmisana fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, to si w ani ipo DIG lọwọ bayii.
- Yakubu Abubakar
Ọga agba ni Yakuba Abubaker to di ẹka eto isuna mu ni ileeṣẹ ọlọpaa niluu Abuja.
Ti a ba n sọ nipa owo ati mimojuto awọn oṣiṣẹ, ẹka yii ni Abubakar di mu pupọ.
- Basil Idegwu
Basil Idegwu jẹ onimọ to kẹkọ gba oye PhD ni ẹka alaafia ati eto aabo, to si jẹ ọga fun ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n pe fun alaafia.
Awọn yooku ni Bzigu Kwazhi, Idris Abubakar ati Adebowale William
Wo awọn ọga ọlọpaa ti Naijiria ti ni lati ọdun 1999.

Oríṣun àwòrán, nigeria police force
IGP Musiliu Smith (1999–2002), lati ipinlẹ Eko
IGP Mustafa Adebayo Balogun (2002 – 2005), lati ipinlẹ Osun
IGP Sunday Ehindero (2005–2007), lati ipinlẹ Ondo
IGP Mike Mbama Okiro (2007–2009), lati ipinlẹ Imo
IGP Ogbonna Okechukwu Onovo (2009 - 2010), lati ipinlẹ Enugu.
IGP Hafiz Ringim (2010 - 2012), lati ipinlẹ Jigawa,
IGP Mohammed DIKKO Abubarkar (2012 - 2014), lati ipinlẹ Sokoto
IGP Suleiman Abba (2014 -2015), lati ipinlẹ Jigawa
IGP Solomon E. Arase (2015 - 2016), lati ipinlẹ Edo
IGP Ibrahim Kpotun Idris (2016-2019), lati Niger
IGP Mohammed Abubakar Adamu (2019-2021) lati ipinlẹ Nasarawa
IGP Usman Alkali Baba (2021-2023), lati ipinlẹ Yobe state
IGP Kayode Egbetokun, lati ipinlẹ Ogun state

























