'Nàìjíríà lorílẹ̀èdè tó léwu jùlọ fún kristẹ́nì láti gbé lágbáyé' – ilé àṣòfin Amẹ́ríkà gbé èsì ìwádìí nípa ìṣekúpa àwọn Kristẹni ní Naijiria jáde

Aworan Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump, ti tẹwọ gba ẹkunrẹrẹ alaye nipa iwadii bi ọpọ awọn ẹlẹsin Kristi ṣe n padanu ẹmi wọn lẹyin ọpọ oṣu iwadii lati ọwọ aṣofin ile igbimọ aṣofin Amẹrika.

Esi iwadii yii ni awọn ọmọ igbimọ tẹẹkoto lori ọrọ iṣuna ati ọrọ ilẹ okeere nile aṣofin orilẹede Amẹrika , fi ransẹ si ile ààrẹ Amẹrika, pẹlu alaye ati imọran ti wọn ni fun iṣoro to n koju awọn Kristẹni ni orilẹede naa.

Igbesẹ yii waye lẹyin ti Trump ṣapejuwe orilẹede Naijiria gẹgẹ bii orilẹede to ni ohun woye pe o nilo amojuto gboogi, to si pa a laṣẹ fun awọn ọmọ ile igbimo aṣofin, Riley Moore ati Tom Cole lati gbe fimu finlẹ lori ohun to n ṣẹlẹ nipa eto aabo orilẹede Naijiria.

Ki ni abọ iwadii US?

Moore fidi rẹ loju opo X rẹ lọjọ Aje, pe ipade waye lori iwadii naa, ti wọn si ti gbe esi iwadii lọ ile ijọba, White House.

Gẹgẹ bii o ṣe ti ṣe sọ, Moore ni iwadii naa lo lori ero awọn onimọ ati awọn oṣojumikoro pẹlu iranlọwọ lati ọdọ awọn ijọba Amẹrika.

Ṣaaju ni Moore lewaju awọn igbimọ wa si orilẹede Naijiria ti wọn si ṣe abẹwo si awọn agbegbe kan ni Naijiria, awọn eeyan ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si sọrọ, ni ipade pẹlu awọn olori ijọba, to fi mọ oludamọran si aarẹ lori aabo, Nuhu Ribadu.

O ni awọn awọn igbimọ naa ti ni oye nipa ohun to n fa kudiẹkudiẹ eto aabo ni awọn apa ibi kan ni orilẹede Naijiria.

"Orilẹede Naijiria jẹ ibi to buru fun Kristẹni lati gbe. Awọn Kristẹni n koju iṣekupani lati ọwọ agbebọn Fulani ati awọn ikọ agbebọn mii, ti wọn si n pa ọpọ awọn Kristẹni, to fi mọ awọn pasitọ ati alufa.

"Didana sun ile ijọsin, ile ẹkọ ati jiji ọpọ gbe wa lara awọn nnkan ti awọn Kristẹni n koju."

Ki awọn imọran ti wọn fun ijọba?

Moore ninu alaye iwadii pe ajọsepọ laarin ijọba Naijiria ati orilẹede Naijiria lati pese aabo to peye fun awọn agbegbe ti Kristẹni wa, ti wọn si gbe ogun t tako awọn agbebọn yii.

Lara awọn imọran ti Moore fi sini esi iwadii naa ni pe ijọba orilẹede Naijiria yoo nilo lati ri pe wọn fopin si ikọlu awọn agbebọn nipasẹ lilo iranlọwọ igbalode ati igbigba awọn agbẹ laaye lati ni idanilẹkọọ lati da abo bo ara wọn.

"Ijọba ni lati ṣe iranlọwọ fun awọn agbẹ to n sin nnkan isin, ki wọn si faye gba awọn agbẹ lati ma da aabo bo ara wọn lọwọ agbebọn.

"Ijọba ni lati gba awọn oṣiṣẹ kun awọn ileeṣẹ ologun, ti wọn yoo ji pepe lasiko ikọlu awọn agbebọn.

"Ijọba lati pese ofin ti yoo fi ijiya fun ẹgbẹ tabi ijọ to n kopa ninu iwa ti ko faye gba ominira ẹsin ṣiṣe."

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Kí ló ti wáyé sẹ́yìn nípa eto aabo Nàìjíríà laarin ààrẹ Amẹ́ríkà àti Nàìjíríà?

Lọdun to kọja ni ijọba ilẹ Amẹrika kede pe oun yoo gbẹsan lara ijoba Naijiria tori bo se kuna lati daabo bo awọn Kristẹni.

Aarẹ Amẹrika tun fi orukọ Naijiria si ara awọn akọsilẹ orukọ awọn orilẹede to tapa si ofin ominira lati ṣe ẹṣin to ba wu onikaluku.

Bakan naa, ninu oṣu Kejila ọdun 2025, ijọba Amẹrika tun kede ilẹ Naìjiria bii ara awọn orilẹede ti yoo nira fun lati wọ orilẹede naa, to si fi ofin ati gbedeke ti irinajo awọn ọmọ Naijiria si Amẹrika nidi.

Bakan naa ni ikọ ologun Amẹrika kọlu awọn agbegbe kan ni orilẹede Naijiria lọdun to kọja.