Tunji Disu di adelé Ọ̀gá Ọlọ́pàá Naijiria tuntun lẹ́yìn tí Kayode Egbetokun kọ̀wé fipò sílẹ̀

Ọga agba ọlọpaa tuntun, Olatunji Disu wọ aṣọ ọlọpaa dudu pelu fila dudu, Kayode Egbetokun ọga agba ọlọpaa to fẹyinti wọ aṣọ buluu pẹlu fila dudu

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Tunji Disu ti di adele ọga ọlọpaa Naijiria tuntun lẹyin ti Kayode Egbetokun kọwe fi ipo silẹ.

Ni irọlẹ ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹrinlelogun oṣu Keji yii ni oludamọran Aarẹ Bola Tinubu lori eto iroyin, Bayo Onanuga, fidi ọrọ naa mulẹ ninu atẹjade to fi sita.

Onanuga ṣalaye pe Tinubu yan Disu gẹgẹ bi adele ọga ọlọpaa Naijiria tuntun lẹyin ti Egbetokun kọwe fipo silẹ, igbesẹ to ni oun gbe nitori ẹbi oun.

Aarẹ Tinubu tẹwọ gba igbesẹ Egbetokun lati kọwe fipo silẹ, lẹyin to sọ pe nitori ẹbi oun loun fi ṣe bẹẹ.

Disu ti wa ni ipo igbakeji ọga ọlọpaa Naijiria fun bi igba kan ṣaaju tẹlẹ, ki o to de ipo ọga agba ọlọpaa.

Onanuga sọ ninu atẹjade to fi sita pe Tinubu dupẹ lọwọ Egbetokun fun iṣẹ ribi ribi to ṣe ati ifọkansi rẹ lasiko to fi wa lẹnu iṣẹ ọba ati lasiko to jẹ ọga ọlọpaa Naijiria.

Loṣu Kẹfa ọdun 2023 ni Tinubu yan Egbetokun sipo, o si yẹ ko kuro nipo naa loṣu Kẹfa ọdun 2027, gẹgẹ bi atunṣe ofin ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria.

Amọ, pẹlu bi eto aabo ṣe ri lọwọ yii lorilẹede Naijiria, Aarẹ Tinubu ni lati buwọlu iyansipo Tunji Disu gẹgẹ bi adele ọga ọlọpaa tuntun lẹsẹ kẹsẹ.

Tinubu gbagbọ wi pe Disu jẹ akọṣẹmọṣẹ, o si ni iriri lati dari ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria papaa julọ lasiko yii ti eto aabo mẹhẹ ni Naijiria.

Gẹgẹ bii alakalẹ ofin ileeṣẹ ọlọpaa ọdun 2020, Aarẹ Tinubu yoo ṣepade pọ bayii pẹlu ajọ NPC to n ri si ọrọ ọlọpaa lori iyansipo Tunji Disu.

Lẹyin naa ni aarẹ yoo forukọ rẹ ranṣẹ sile aṣofin agba l'Abuja fun ibuwọlu.

Ohun to yẹ ki mọ nipa ọga ọlọpaa Naijiria tuntun Tunji Disu

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

A bi Tunji Disu lọjọ kẹtala oṣu Kẹrin ọdun 1966 ni Lagos Island nipinlẹ Eko.

Disu bẹrẹ ẹkọ rẹ ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ Holy Cross Cathedral.

O tẹsiwaju eto ẹkọ rẹ ni ile ẹkọ Mayflower Junior School niluu Ikenne nipinlẹ Ogun lọdun 1979.

Disu tun kẹkọọ nile ẹkọ girama Pobuna niluu Epe ati ile ẹkọ St. Gregory 's College niluu Eko nibi to ti kẹkọọ jade lọdun 1985.

O tẹsiwaju eto ẹkọ rẹ nile ẹkọ giga fasiti ipinlẹ Eko LASU nibi to kẹkoo njpa kikọ ede Gẹẹsi, o si kẹkọọ gboye nibẹ lọdun 1990.

Disu tun kẹkọọ gboye PGD ninu imọ ibaraẹniṣepọ lagbaaye ni ile ẹko giga giga LASU bakan naa.

Ko tan sibẹ o, Disu tun gba iwe ẹri nipa dida aabo bo ara ẹni nilẹ Gẹẹsi.

Disu gboye meji ọtọọtọ ni fasiti ninu imọ iṣeto ilu ati imọ nipa iwa ọdaran lọdun 2010.

O tun gboye ninu imọ nipa eto aabo ati ihuwasi ẹda ni fasiti Adekunle Ajasin niluu Akungba l'ọdun 2022.

Disu tun ti gba oriṣiiriṣii oye lẹnu iṣẹ ni Naijiria ati kaakiri agbaye to fi de Ilẹ Gẹẹsi, orilẹede Botswana atawọn orilẹede mii.

O tun kẹkọọ gboye ninu imọ nipa iwa ọdaran ni fasiti ilu Eko UNILAG ati ni ile ẹkọ awọn ọlọpaa to wa niluu Jos nipinlẹ Plateau.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Bi Disu ṣe darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa

Ọjọ kejidinlogun oṣu Karun un ọdun 1992 ni Disu darapọ mọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria.

Disu ṣe ọga ọlọpaa DPO ni Ago Iwoye nipinlẹ Ogun ati ni ilu Ikare lOndo.

O tun ṣe DPO niluu Owo ati ni Elimbu to fi mọ Elelenwo nipinlẹ Rivers.

Oun ni ọga ikọ ọlọpaa kogberegbe tawọn eeyan mọ si SARS nipinlẹ Rivers.

O tun ṣe ọga ọlọpaa SARS l'Ondo ati ni ipinlẹ Oyo.

Lọdun 2005, Disu lo lewaju ikọ ọlọpaa Naijiria ti wọn lọ pẹju sija labẹ asia ajọ AU lorilẹede Sudan.

Disu tun figba kan jẹ ọga ikọ ọlọpaa kogberegbe RRS nipinlẹ Eko laarin ọdun 2015 si ọdun 2021.

Ọpọ olugbe ipinlẹ Eko lo maa n sọ nipa iṣẹ ti Disu atawọn ọlọpaa to wa labẹ rẹ ṣe lasiko to jẹ ọga RRS.

Ikọ RRS gbajumọ fun gbigbogun ti iwa ibajẹ nipinlẹ Eko labẹ idari Disu.

Lọdun 2021 ni Disu di igbakeji ọga ọlọpaa DCP niluu Abuja, Ọga agba ọlọpaa tẹlẹ, Usman Alkali Baba lo yan Disu sipo adari ikọ ọtẹlẹmuyẹ IRT.

Disu ni igbega lẹnu iṣẹ si ipo ọga ọlọpaa CP lọdun 2023.

Ipo ọga ọlọpaa ipinlẹ Rivers ni Disu wa, ki ọga agba ọlọpaa Egbetokun to gbe e lọ si Abuja lati di ipo ọga ọlọpaa olu ilu Naijiria mu.