Inú abala àríwísí làwọn olólùfẹ́ mi ti tẹ orúkọ 'Arike Pre order' mọ́ mi – Arike Pre order

Àkọlé fídíò, Inú abala àríwísí làwọn olólùfẹ́ mi ti tẹ orúkọ ‘Arike Pre order’ mọ́ mi – Arike Pre order
Inú abala àríwísí làwọn olólùfẹ́ mi ti tẹ orúkọ 'Arike Pre order' mọ́ mi – Arike Pre order

Samuel Banks ti ọpọ eeyan mọ si Arikẹ Pre-Order loju opo ayelujara ti ba BBC News Yoruba sọrọ lori idi to fi maa n ṣe bi obinrin lawọn fidio apanilẹrin to n fi si oju opo ayelujara kaakiri.

O ni awọn eeyan lo fun oun ni orukọ Arikẹ. Nigba ti oun si ri pe orukọ naa dara fun iṣẹ apanilẹrin ti oun fẹ ṣe lori ayelujara loun naa fi yara tẹwọ gba a.

Arikẹ Pre order tun ṣalaye pe awọn nnkan to n ṣẹlẹ lawọn ibugbe awọn to ku diẹ kaato lawujọ loun maa n saba jẹ ko jẹyọ lawọn fidio apanilẹrin oun.

"Mo n ṣe eyi lati jẹ ki awọn eeyan mọ pe bi wọn bi eeyan ni atapatadide ko tumọ si pe ko lee laluyọ laye."

Wo fidio yii siwaju sii ki o le ri idi ati bi Arikẹ Pre Order ṣe gbinaya.